Kano rape cases: Muhammad, ẹni ọdún mẹjìlélọgbọn jẹwọ bí òun ṣe ń fipábá àwọn obìnrin ogójì lò pọ

Oríṣun àwòrán, Kano Police
Ọpọ awọn eeyan lo ti ṣe iwọde loriṣiriṣi lori ọrọ ifipabanilopọ to n fojoojumọ pọ sii ni Naijiria lasiko yii.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe nitori konile-o-gbele lati dena itankalẹ Coronavirus lo faaa.
Bẹẹ naa ni awọn miran n ni iwa ika inu awọn ọkunrin oniṣẹ ibi kan ni o faa.
Ọwọ ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Muhammad Zulfara'u Alfa ni agbegbe Kwanar Dangora ni ipinlẹ Kano.
Ninu awọn to n hu iwa buruku ifipabanilopọ lọwọ rẹe gẹgẹ bo ti se jẹwọ fawọn ọlọpaa.
Wọn ni o ti fipa ba ọpọlọpọ obinrin lo pọ, koda, a gbọ pe iya arugbo ẹni ọgọrin ọdun kan wa ninu awọn obinrin naa to ti fipa ba lopọ.
- Lẹ́yìn tó ṣá Monisola aya rẹ̀ ládá, Oniya ní iṣẹ́ èṣù ni
- Wèrè tí mò ń ṣe ní Facebook ló pawó fún mi-Esabod
- Èèyàn 104 kó covid-19 ní iléeṣẹ́ kan ṣoṣo ní Sagamu- Ìjọba Ogun
- Bí Gómìnà Makinde bá ṣẹ̀ mí, lẹ́tà lásán ló jẹ mí- Aláàfin Ọ̀yọ́
- Kónílé-ó-gbélé Covid 19 ló tú àṣírí àwọn àfipábánilòpọ̀ láwùjọ- Mínísítà ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin
Alukoro ọlọpaa nilu Kano sọ fun BBC pe ọwọ awọn ti pada tẹ Muhammad Zulfara'u Alfa to jẹwọ pe oun fipa ba awọn obinrin yi lopọ ni ilu Kwanar Dangora ni Kano.
Lọjọ Isẹgun ni ọwọ tẹ Muhammad lẹyin to wọ inu ile kan lati lọ fipa ba awọn ọmọde kan lo pọ nibẹ ki ọkan ninu awọn ọmọde naa to kigbe sita.
Gẹgẹ bi ohun tawọn ọlọpaa wi, Iya awọn ọmọ naa lo tu asiri rẹ nigba to saa deede ri pe eeyan kan sa n pa ina ọba ninu iyara awọn ọmọ naa lera lera ti ọkan si n pariwo.
Iya yi wọ inu iyara awọn ọmọ rẹ lọ nibi to ti ri Muhammad lori ọkan ninu awọn ọmọ rẹ́ to ti ràgà bòó mọlẹ sibẹ
O figbe ta ti ọdaran naa si gbiyanju lati sa lọ sugbọn ọkọ arabinrin yi ati awọn araadugbo lee mu.

Oríṣun àwòrán, Kano State Government
Awọn agbofinro ni itaniji ati ariwo ti awọn eeyan n pa kaakiri Naijiria lori ifipabanilopọ yii ti n ṣi oju awọn ọmọde ati obinrin si pipariwo sita lasiko.
Ọga agba ọlọpaa ni ẹkun naa, Abdullahi Haruna ṣalaye pe Muhammad ti jẹwọ nipa awọn obinrin to to ogoji to ti fipa ba lo pọ ati pe agbara ofin yoo ṣe ohun to yẹ lẹyin iwadii
Awọn eeyan ilu naa ni: ''O ti pẹ ti Arakunrin yi i ti maa n dẹruba awọn eniyan agbegbe Kwanar Dangora lori ọrọ ifipabanilopọ ṣugbọn ti onikaluku dakẹ ti wọn n fi mọra nitori eru to n ba wón.
O le ni obinrin ogoji ti Muhammad Alfa ti fipa ba lopọ pẹlu wọn laarin ọdun kan; Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ ni awọn obinrin naa si ti n bọ sita wa sọ ohun to ṣe fun wọn.
Lati igba tọwọ ti tẹẹ ni awọn obinrin adugbo yii ti n yọ ayọ ominira ti wọn si n wa yọju lati wa wo ẹni to n dunkooko mọ wọn yi ti wọ́n si ti wa fi ẹsun kan lọdọ awọn ọlọpaa tẹlẹ'
Muhammad jẹwọ fun akọroyin BBC to fọrọ wa a lẹnu wo pẹ nitootọ ni awọn iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
O tun ni pe: lootọ ni pe oun hu iwa buruku yi.
O ni yatọ si iya arugbo ẹni ọgọrin ọdun ti oun fipabalopọ, oun tun ba ọmọde ti ko to ọdun mẹwaa lajọsepọ nipa.
Halima Sani to jẹ ọkan lara awọn obinrin ilu naa to ba BBC sọrọ wi pe awọn obinrin ilu naa yoo fẹdọ lori oronro sun bayi ti ọwọ ti tẹ ọdaran yi.
O ni orukọ tawọn obinrin ilu naa sọ Muhammad tẹlẹ ki ọwọ too tẹ ni '''Mai Sikẹti''
Muhammad Jamil tó jẹ Kansẹlọ wọọdu Yalwa ni ilu Dangora sọ fun akọroyin BBC pe idunnu ti ṣubu lu ayọ gbogbo awọn olugbe ẹkun yii nitori pe arakunrin Mai Sikẹẹti yii ti da ọpọlọpọ igbeyawo awọn eniyan ru.
O ni titi di isinyi ni ọrun ṣi n dun ọmọdebinrin kan ti ọkunrin yii fipabalopọ nitosi ile Oun yatọ si ti iya arugbọ to n gbe ni ẹgbẹ Mọṣalaṣi to tun fipa kọlu.
Baalẹ ilu Dangora, Mallam Ahmadu Ya'u naa ba akọroyin BBC sọrọ pe o ti pẹ ti tonile talejo ti n gbadura pe ki ọwọ tẹ oniṣẹ ibi yii ni eyi ti o dẹ ti jasi ọpẹ nla fun gbogbo olugbe Dangora lasiko yii.
Ilu Dangora ti iṣẹlẹ yii ti waye jina si Kano niwọn kilomita marunlelọgọrin.
Agbẹ lọ pọ ju ninu awọn ara ilu naa ti wọn a si maa gbin ohun jijẹ bi ọka baba, agbado ati alubọsa ti wọn si maa n kore fun tita
Lẹnu ọjọ mẹta yi, ọrọ ifipabanilopọ jẹ eleyi to gbode kan kaakiri Naijiria ti awọn obinrin kan si ti padanu ẹmi wọn lọwọ awọn ika eniyan to fipa bawọn lo pọ yi.














