Ogun state lockdown update: 'Èèyàn 104 tó kó covid-19 ní ílééṣẹ́ kan ní Sagamu fihàn pé ààrùn náà ti wà láwùjọ'

Oríṣun àwòrán, Twitter/Prince Dapo Abiodun
Bi awọn eeyan mẹrinlelọgọrun un ṣe lugbadi aarun coronavirus ni ileeṣẹ kan niluu Sagamu nipinlẹ Ogun fihan pe aarun naa ti wa lawujọ.
Nigba ti Kọmiṣọnna eto ilera ipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker ba BBBC Yoruba sọrọ lo fidi ọrọ naa mulẹ.
Kọmiṣọnna eto ilera ṣalaye pe ko si ẹni ti o ni apẹẹrẹ pe o ni aarun covid-19 ninu awọn oṣiṣẹ naa ti wọn lugbadi coronavirus.
- Èèyàn 409 míì ti lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Ìyàwò kejì tó fi owú ré ọkọ bọ́ láti òkè pẹ̀tẹ́sì gba ìdájọ́ ikú
- Ẹ̀wọ̀n gbére ni fún ẹnikẹ́ni tó bá fipá bánilòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
- Lẹ́yìn tó ṣá Monisola aya rẹ̀ ládá, Oniya ní iṣẹ́ èṣù ni
- Wèrè tí mò ń ṣe ní Facebook ló pawó fún mi-Esabod
Kọmiṣọnna ni gbogbo awọn to laarun yii atawọn eeyan ti wọn ni ajọṣepọ lo n gbe ninu ọgbọn ileeṣẹ naa.
O ni ọpọ eeyan lo n rin kiri pẹlu aarun coronavirus lai mọ.
Dokita Tomi fikun ọrọ rẹ pe ewu to wa bayii ni wi pe awọn eeyan ko tẹle ilana wiwọ ibomu lati dena itankalẹ coronavirus.
Kọmiṣọnna ni aarun yii ko le ṣalai maa maa tan kalẹ si nitori awọn eeyan ko tẹ le ilana itakete si ara ẹni.
O ni otitọ ni pe awọn ọlọpaa n gbiyanju lati maa mawọn eeyan ti wọn ko tẹ le ilana ti ijọba la kalẹ lori at i dena itankalẹ aarun covid-19.
Ṣugbọn kọmiṣọnna sọ pe o yẹ kawọn eeyan mu ọrọ ilera ara wọn lọkunkun lai jẹ wi pe wọn n fipa mu wọn.
Lori erongba ijọba ipinlẹ Ogun lati ṣi ile ijọsin ati mọṣalaaṣi, kọmisọnna ni ijọba ti ṣepade pẹlu awọn olori ẹsin lori awọn ilana eto aabo lati dena covid-19 ti ile ijọsin ba di ṣiṣi pada.












