Wahab Adegbenro: Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ondo jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Akintomi Akin
Kọmisọnna fun eto ilẹra ni ipinlẹ Ondo, Wahab Adegbenro ti wọlẹ sun ni Ọjọ Ẹti.
Adegbenrọ ni wọn sin si ile rẹ to wa ni Ilara Mokin ni ijọba ibilẹ Ifẹdore ni deede aago mẹwaa owurọ gẹgẹ bi ẹsin Musulumi ṣe laa kalẹ.

Oríṣun àwòrán, Adetomi Akin
Ile iwosan ijọba to wa ni Owo lo ku si lẹyin to lugbadi arun Coronavirus.
Amọ awọn aworan ti a ri fihan gbangba pe ọpọ awọn eniyan to wa si ibi isinku naa ni wọn ko lo ibomu, ti wọn ko si tẹle ofin yiyagofunraẹni.

Oríṣun àwòrán, Adetomi Akin
Ẹbi, ara ati ọrẹ pẹlu ojulumọ lo peju pese si ibi isinku naa.

Oríṣun àwòrán, Akintomi Akin
Àlàyé rèé lórí ikú tó pa Adegbenro, Kọmísánà l'Ondo
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe Kọmiṣọnna feto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Wahab Adegbenro ti jade laye.
Gẹgẹ baa se gbọ ibudo ti wọn ti n tọju awọn alarun Coronavirus nilu Akure ni Kọmiṣọnna naa dakẹ si.

Oríṣun àwòrán, Ondo TV Twitter
Adegbenro, tii se ọmọ bibi ilu Ilaramọkin nipinlẹ Ondo, ni wọn kede iku rẹ lẹyin ọjọ meji ti gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu kede pe oun naa ti lugbadi arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Ondo TV Twitter
Mọlẹbi oloogbe naa, Rasheed salaye pe Kọmisana naa se isẹ abẹ fun alaisan kan lọjọ Aje nile iwosan adani rẹ to wa ni Odo Ikoyi.
Amọ sadede lo subu lulẹ, to si daku lọ rangbọndan, ki wọn to gbe digba-digba re ile iwosan.
Rasheed fikun pe "Lati ọjọ Aje naa la ti ri pe ilera wọn ko ji pepe rara titi di ọsan oni to sadede de lati ọọfisi lairoti , ti wọn si gbe lọ sile iwosan FMT, nibi to dakẹ si."
Ọpọ eeyan lo ti duro go go go sile oloogbe naa lati kẹdun, ti wọn si n sọkun lori iku aitọjọ to mu Kọmisana naa lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀nà tí àwọn ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’ gbà dé ààfin Ọyọ
- Bí òṣìṣẹ́ tó ń ta epo nílé epo ṣe di onímọ̀ ìṣẹ́gun òyìnbó, kàyéèfì ńlá!
- Ṣé ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà ní ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun ti Falana, Ezekwesili àtàwọn 28 mìí dá sílẹ̀ yìí?
- Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ Ọba Ìkirè nìdí lẹ́yìn ọdún 27 lórí ìtẹ́
- Ayédèrú Lọ́yà tó ń díbọ̀n gbowó lọ́wọ́ aráàlú bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá













