Àwọn obìnrin ìlú Owo ṣe ìwọ́de, wọ́n bẹ Ògún lọ̀wẹ̀ sí àwọn tó kọlu Ṣọ́ọ̀ṣì nìlùú nàá

Awọn obinrin naa ti kọkọ ṣe iwọde yika ilu ki wọn o to ṣe etutu
Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin naa ti kọkọ ṣe iwọde yika ilu ki wọn o to ṣe etutu

Ogunlọgọ awọn obinrin, lọmọde, agba ati adelebọ ati arugbo, lo tu jade lonii nilu Owo, lati ṣe iwọde lẹyin ipaniyan to waye ninu ijọ Aguda St. Francis lọjọ aiku.

Awọn obinrin ọhun to wọde yika gbogbo ilu n sọ awọn ọrọ aṣẹ ati èpè pe ki ẹsan wa sori awọn to ṣe ikọlu ọhun.

Yatọ si pe wọn rin kaakiri, gbogbo awọn obinrin naa lo ja ewe dani, eyi to jẹ apẹrẹ aidunnu si iṣẹlẹ kan.

Lẹyin ti wọn yipo ilu tan, ni wọn korajọ si oju kan, nibi ti wọn ti da àdá ati awọn ọ̀bẹ jọ si ilẹ.

Bi wọn ṣe da awọn ada naa jọ, ni wọn yiI ka, ti wọn si bẹ oriṣa Ogun lọwẹ lati gbẹsan.

Bẹẹ ni ẹnikọọkan wọn n gba adura ati epe bo sẹ wu wọn.

Awọn obinrin to ṣe iwọde

Lẹyin eyi ni iya arugbo kan, to jọ pe oun ni adari wọn, paṣẹ pe ki gbogbo wọn o bọ bata silẹ.

Lẹyin naa lo mu àdín atì ọ̀bọ̀, to si da a si ori awọn ada ati ọbẹ ti wọn dajọ.

Ẹnikan lara wọn to ba akọroyin BBC, Gift Andrew sọrọ, pẹlu omije loju, sọ pe iru nkan bẹẹ ko ṣẹlẹ ri nilu Owo.

“Adura wa ni pe Ọlọrun wa yoo fi idajọ bẹ awọn oniṣẹ ibi naa wo, titi de irandiran wọn.”

Lẹyin etutu ti wọn ṣe laarin ọja, ni wọn gbe iwọde wọn lọ si aafin Olowo ti Owo

Aafin naa wa ni ẹyin ile ijọsin ti ikọlu ọhun ti waye.

Awọn to n ṣe iwọde
Olowo ti Owo re e to n ba awọn obinrin naa sọrọ, lasiko ti wọn ṣe iwọde de aafin rẹ
Àkọlé àwòrán, Olowo ti Owo ree to n ba awọn obinrin naa sọrọ, lasiko ti wọn ṣe iwọde de aafin rẹ.

Òkú 22 àti èèyàn 57 mìí tó farapa níbi ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì Owo ni wọ́n gbé wá sílé ìwòsàn - NEMA

Diẹ lara awọn to farapa nibi ikọlu awọn agbebọn niluu Owo
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn to farapa nibi ikọlu awọn agbebọn niluu Owo

Olori ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria (NEMA) ẹka ti ipinlẹ Ondo, Osun ati Ekiti, Kadiri Olanrewaju, sọ fun BBC iye eeyan to kagbako ninu ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ile ijọsin St. Francis Catholic Church, nilu Owo, ipinlẹ Ondo.

Ọgbẹni Olanrewaju sọ pe ni ileewosan FMC Owo, wọn gbe apapọ eeyan mọkandinlogoji wa sibẹ, agbalagba mẹrindinlọgbọn, ọmọde mẹtala. Ninu wọn ni oku agbalagba mẹfa wa, ati ti ọmọde meji.

Ni ileewosan St. Louis Catholic, oku eeyam mẹtala ni wọn gbe de ibẹ, ti eeyan mejidinlgoun si n gba itọju lọwọ.

ile iwosan

Ni ileewosan aladani kan, eeyan kan pere lo n gba itọju lọwọ, wọn ti tọju eeyan meje ti ko farapa pupọ, wọn si ti lọ sile wọn pada.

Nileewosan aladani yii kan naa, wọn gbe oku eeyan kan lọ sibẹ.

Apapọ awọn tp faragba ninu ikọlu naa jẹ mọkandinlọgọrin.

Eeyan mejilelogun ti ku, awọn meje ti pada sile lẹyin itọju, aadọta ṣi wa nileewosan.

Fídíò yìí ló ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣe wáyé

Àkọlé fídíò, Owo Church Attack: Agbébọn yabo ṣọ́ọ̀ṣì àgùdà ní Owo, òkú sùn, ọ̀pọ̀ farapa

Ọjọ buruku ni ọjọ Aiku, ọjọ Karun osu Kẹfa ọdun 2022 jakejado ilẹ Naijiria ati lawujọ agbaye nigba ti awọn agbebọn kan yabo ile ijọsin ijọ aguda kan nilu Owo.

Orukọ ijọ naa ni St Francis Catholic Church to wa nilu naa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si ile ijọsin ọhun ti isẹlẹ ipaniyan ti waye, se ni a ri ti ẹjẹ kun ile ile ijọsin naa ati ita rẹ.

Bakan naa ni a ri oku awọn eeyan kan ninu ile ijọsin naa amọ a ko le sọ apapọ iye ẹmi to ba isẹlẹ naa lọ.

Awọn eeyan to fori sọta ikọlu ni sọọsi nilo ẹjẹ:

Bakan naa ni BBC Yoruba tun kan sawọn ile iwosan meji, St Louis at Federal Medical Centre ti wọn wa nilu Owo nibi ti wọn gbe awọn eeyan to farapa lọ.

Nibẹ si ni awọn osisẹ ilera naa wa n rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati wa fi ẹjẹ silẹ fun awọn eeyan ti ẹjẹ pupọ danu lara wọn lasiko ikọlu naa.

Bakan naa la ri pe awọn osisẹ agbofinro bii ọlọpaa ati Sọja ti de sile ijọsin naa lati maa ko oku awọn eeyan to fori sọta ikọlu ọhun.

Akeredolu seleri lati mu awọn eeyan to sisẹ ibi ọhun:

Nigba to se abẹwo sibi isẹlẹ, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu rọ awọn araalu lati fi ọwọ wọnu lori isẹlẹ naa, ki wọn ma si se gba ẹsan.