Igbákejì gómìnà àti APC l‘Oyo kò le jí ipò tí kò tọ́ sí wọn, tètè kọ̀wé fipò sílẹ̀ bíbẹ́ẹ̀kọ́... PDP

Seyi Makinde ati Rauf Olaniyan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ẹ̀ka ìpínlẹ̀ ti ṣèkìlọ̀ fún igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Rauf Olaniyan láti tètè kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ náà.

Èyí kò ṣẹ̀yìn ìkéde Olaniyan ní ọjọ́ Àìkú wí pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ àti pé òun ti ko ẹ̀kọ́ òun tọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nítorí ó dàbí wí pé ọ̀dọ̀ wọn ni ọbẹ̀ wà.

Lẹ́yìn tí Olaniyan kéde wí pé òun ti fi ẹgbẹ́ PDP sílẹ̀, ó ní òun ṣì ni igbákejì gómìnà Seyi Makinde nítorí kò sí ibi kankan tó wà níní ìwé òfin Nàìjíríà wí pé gómìnà àti igbákejì rẹ̀ gbọdọ̀ wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà.

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Akeem Olatunji nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lórí ọ̀rọ̀ tí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo sọ.

Olatunji ní ó pọn dandan fún Rauf Olaniyan kó kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ nítorí òun ló finú fẹ́dọ̀ fi ẹgbẹ́ àwọn sílẹ̀.

Olatunji ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò ní fàyè gba Olaniyan àti ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ láti jí ohun tí kìí ṣe ti wọn nítorí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ́ ni àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo dìbò fún lọ́dún 2019.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu ńlá gbáà wí pé lẹ́yìn tí Olaniyan ti kéde wí pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, òun ṣì ni igbákejì gómìnà.

Agbẹnusọ PDP ní irú ìkéde yìí ṣàfihàn ìwà ìmọtaraẹni nìkan àti fífẹ́ fi ọwọ́ ọlá gbá àwọn ará ìlú tó dìbò lójú.

Bákan náà ló fi kun pé gbogbo ìgbìyànjú àwọn adárí ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà àti látòkè láti parí gbogbo ááwọ̀ tó ń wáyé èyí tó ṣokùnfà kíkúrò nínú ẹgbẹ́ ló já sí pàbó.

Amin idamọ ẹgbẹ oselu PDP

Oríṣun àwòrán, PDP Oyo state

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

PDP ní kò yẹ kí Olaniyan máa ṣe bí ẹni w;i pé òun kò mọ ohun tó kàn láti nígbà tó ti fi ẹgbẹ́ tó gbé òun àti gómìnà Seyi Makinde wọlé lábẹ́ tíkẹ́ẹ̀tì kan náà tó bá jẹ́ wí pé lóòótọ́ ni orúkọ ọmọlúàbí tó ga tó máa ń pe ara rẹ̀ jẹ́ òótọ́.

Ó fi kun pé lóòótọ́ ni ìwé òfin Nàìjíríà fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti ṣe ẹgbẹ́ tó wù ú àmọ́ ó yẹ kí Olaniyan mọ̀ wí pé tó bá jẹ́ pé ó díje ní òun nìkan ló ní irú àǹfàní bẹ́ẹ̀.

“Kìí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP/APC ni àwọn ènìyàn dìbò yàn lọ́dún 2019, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni wọ́n dìbò fún.”

“Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ẹgbẹ́ ni àwọn ènìyàn máa ń dìbò fún kìí ṣe ènìyàn, tó bá jẹ́ wí pé ènìyàn ni, Olaniyan ṣì lè ní àǹfàní láti kúrò nínú ẹgbẹ́ kan bọ́ sí òmíràn kò sí máa bá ipò rẹ̀ lọ.”

“Ohun ta fẹ́ lọ́wọ́ Olaniyan kò ju pé ko fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ lọ àmọ́ tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ a ṣetán láti gbàá lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìlànà òfin.”

Olatunji ni ìgbésẹ̀ Olaniyan kò tu irun kan lára ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí àwọn gbàgbọ́ wí pé ti Seyi Makinde ni àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ń ṣe nítorí gbogbo ètò tó ń ṣe fún àwọn ará ìlú.

Mo ti kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP lọ sí APC àmọ́ èmi sì ní igbákejì Seyi Makinde - Olaniyan

Seyi Makinde àti Rauf Olaniyan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Saaju ;a ti mu iroyin wa fun yin pe Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo Rauf Olaniyan tí kéde pé òun ti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tí òun sì ti kó ẹ̀kọ òun tọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lọ.

Olaniyan kéde ìpinu rẹ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Ibadan ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfà ọdún 2022 ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, òun ṣì ni ìgbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo.

Ó ni ìwé òfin Nàìjíríà kò fi ibi kankan làá kalẹ̀ wí pé gómìnà àti igbákejì rẹ wá kò lè sí nínú ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìdí èyí òun ṣì ń tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo.

Ó fi kun pé ìpìnu òun láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kìí ṣe ohun tí òun nìkan kàn dáṣe, ó ní gbogbo àwọn alátìlẹyìn òun káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Oyo ni wọ́n pinu pé kí àwọn máa lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

“Mo fẹ́ sọ fún un yín wí pé mo ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti àsìkò yìí lọ nítorí gbogbo ìgbà ni ẹ ń bèrè lọ́wọ́ mi pé kí ni mo fẹ́ ṣe.”

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú ló ń pè mí pé kki n wá darapọ̀ mọ́ àwọn kòdá àwọn kan tílẹ̀ ní àwọn yóò gbà mí láyè láti díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ wọn.”

Olaniyan fi kun pé kìí ṣe wí pé òun ń wá ipò ní dandan nítorí náà ni òun kò ṣe gbà láti lọ sínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú bẹ́ẹ̀.

Rauf Olaniyan

Oríṣun àwòrán, Rauf Olaniyan Instagram

Ìkéde Olaniyan yìí ti fi òpin sí gbogbo àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ tó yi ń lọ fún ọjọ́ pípẹ́ wí pé kò sí àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán láàárín gómìnà Seyi Makinde àti igbákejì rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjéèjì kò fi ìgbà kankan sọ síta pé ìfanfà ń wáyé láàárín àwọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìlú ni igbákejì gómìnà kìí báwọn péjú sí.