Òní lòní ń jẹ́, bí ìpalẹ̀mọ́ fún ìbò abẹ́nú APC láti yan olùdíje Ààrẹ ṣe ń lọ rèé

Ibi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Òní lòní ń jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Conngress, APC.

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC yóò ṣe ètò ìdìbò abẹ́nú rẹ̀ lónìí láti yan ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú náà níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023.

Ní ìrọ̀lẹ́ òní, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Keje, oṣù Kẹfà ọdún 2022 ní àwọn olùdíje mẹ́tàlélógún yóò máa wàkóò pẹ̀lú ara wọn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ìdìbò abẹ́nú náà ti ń fa awuyewuye nítorí ìkéde tí alága ẹgbẹ́ APC, Abdullahi Adamu sọ wí pé Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Ahmed Lawan ni ẹgbẹ́ fọwọ́ sí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó fi mọ́ àwọn gómìnà méjìlá láti ẹkùn àríwá Nàìjíríà ti sọ wí pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkéde tí alága APC náà gbé jáde nítorí gbogbo àwọn ti fẹnukò pé ẹkùn gúúsù ni kí ipò Ààrẹ Nàìjíríà lọ lọ́dún 2023.

Awọn asoju nibi ibo abẹnu APC

Ṣaájú ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó sì tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà.

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ Muhammadu Buhari ti jáde wí pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìròyìn tí Abdullahi Adamu fi léde àti wí pé òun kò ní ààyò nínú àwọn gbogbo àwọn tó ń wá ipò náà.

Ààrẹ rọ àwọn olùdíje láti ẹkùn gúúsù Nàìjíríà láti foríkorí kí wọ́n mu ẹnìkan jáde nínú wọn tí yóò gbá àsíá ẹgbẹ́ náà ṣaájú ètò ìdìbò abẹ́nú.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, Abubakar Atiku Bagudu ní ìṣọ̀kan gbogbo ọmọ ló ṣe pàtàkì jùlọ nítorí ẹnìkan ni yóò jáwé olúborí nínú gbogbo àwọn olùdíje.

Awọn asoju nibi ibo abẹnu APC

Ẹnìkan kò le sọ pé ipá òun ló gbé Ààrẹ Buhari wọlé lọ̀dún 2015 - Garba Shehu

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti sọ pe ẹnikẹ́ni ko gbọdọ sọ pe oun nikan ṣoṣo lo ṣe atọna bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe di aarẹ ninu eto idibo ọdun 2015. Oludamọran fun aarẹ lori eto iroyin, Garba Shehu, sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje pe nkan to ṣẹlẹ sẹyin, ko gbọdọ sọ bi esi idibo gbogbogboo to n bọ yoo ṣe ri. Ọgbẹni Shehu sọ eyi gẹgẹ bi esi si ọrọ ti oludije, Bola Tinubu, sọ pe ọpẹlọpẹ oun ni Muhammadu Buhari fi di aarẹ Naijiria ni 2015. O ni nkan to ṣe koko lasiko yii ni lati yan oludije ti "yoo mu kí orile-ede wa dara ju ti atẹhinwa lọ." Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni Bola Tinubu da awuyewuye silẹ nigba to sọ pe Buhari ko ba ma ti wọlé sipo aarẹ, lai si oun. N'ilu Abeokuta ni oludije si ipo aarẹ, Tinubu, ti sọ ọrọ naa lasiko to n ba àwọn aṣoju ẹgbẹ́ oselu sọ̀rọ̀ saaju idibo abẹle ẹgbẹ́ APC.

Garba Shehu ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, others

Ṣùgbọ́n ninu atẹjade ti Garba Shehu fi sita, eyi to pe àkọlé rẹ ni: Esi si ọrọ ti ọkan pataki lara awọn oludije ni APC sọ.

O ni "ko jẹ iyalẹnu pe bi idibo abẹle ẹgbẹ All Progressives Congress ṣe ku ọ̀la, awọn kan lara àwọn to fẹ dije, n so ara wọn pọ mọ aṣeyọri bi aarẹ ṣe de ipo ni ọdun meje sẹyin."

Shehu sọ pe ọpọ eeyan lo kopa ninu eto idibo ọdun 2015, lati rii pe oludije ninu ẹgbẹ́ alatako gba ijọba lọwọ aarẹ to wa nipo, fun igba akọkọ, lai mu wahala kankan dani.

"Àwọn kan lara wọn gba aarẹ ni imọran lati dije, awọn kan pinnu lati kọ́ ẹgbẹ́ oselu APC, to pada di atọna iṣẹgun ti awọn apapọ ẹgbẹ́ alatako ko ri ṣe tẹ́lẹ̀.

" O le jẹ pe awọn eeyan perete lo gbe awọn igbesẹ naa, ṣùgbọ́n obitibiti miliọnu eeyan lo dibo fun igbesẹ wọn.

" Nitori naa ni ẹnikẹ́ni ko ṣe gbọdọ sọ pe agbara oun lo gbe aarẹ wọle."

Shehu sọ pe ẹni to bá ni ipinnu ati eto lati mọ le ipilẹ ti Buhari fi lélẹ̀, ni yoo ṣoju APC ninu eto idibo.