'Atiku tí a yàn ti mú kí ẹ̀rù PDP má a ba APC'

Atiku Abubakar nibi ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, other

Agba ọjẹ kan ninu ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party (PDP), Alhaji Adamu Maina Waziri, ti sọ pe ipaya ti wa fun ẹgbẹ All Progresives Congress (APC) nitori oludije ti PDP fa kalẹ fun ipo aarẹ lọdun 2023.

O ni idi re e ti APC ko ṣe yara ṣe eto idibo abẹle wọn.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Alhaji Waziri sọ pe APC ti kọkọ fi ọgbọn ẹwẹ, mu ki ajọ eleto idibo sun gbedeke idibo abẹle siwaju pẹlu ọsẹ kan, ki wọn o le sun idibo abẹnu wọn siwaju.

Ọsẹ to kọja ni PDP dibo yan oludije wọn, Atiku Abubakar.

Awọn onwoye eto oṣelu ni Naijiria sọ pe jijawe olubori Atiku, lo mu ki APC o ma tete yan oludije ti wọn.

Eyi si ti mu ki ọpọlọpọ oju wa lara ẹgbẹ naa lati wo oludije ti wọn yoo fa kalẹ.

Opin ọsẹ to kọja lo yẹ ki ẹgbẹ APC ṣe eto idibo abẹle rẹ si ipo aarẹ, amọ wọn sun titi di ọjọ kẹfa oṣu Kẹfa, si ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹfa.

Alhaji Maina Waziri sọ pe “ipinnu awọn eeyan Ariwa Naijiria ni lati wa ni ipo, eyi to mu ki gomina ipinlẹ sokoto, Aminu Tambuwal, yọnda erongba rẹ lati dije, to si sẹ atilẹyin fun Atiku” fun anfaani ẹkun wọn.

O ni awọn ti ṣakiyesi pe ẹnikan lati Gusu Naijiria n gbiyanju lati fi owo jawe olubori ninu eto idibo, ti yoo si ni ipa ti ko dara fun Ariwa Naijiria.

“Gbogbo eeyan lo mọ pe APC ko fẹ yan oludije ti ko ni gba ipo aarẹ fun wọn, amọ ẹru wọn ko ba wa rara.”

Ọjọ Ẹti ni ẹgbẹ APC pari ayẹwo fun awọn to fẹ dupo aarẹ, to si yọ ọwọ awọn mẹwaa kuro “nitori pe wọn o koju osunwọn”.

Ni bayii, oludije mẹtala ni yoo kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ lọdun 2023.