Tinubu: Àwọn adárí ẹgbẹ́ APC bá Tinubu wí lórí ọ̀rọ̀ 'ẹ̀gbin' tó sọ nípa Buhari
Tinubu àti Ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti fun gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Bola Tinubu, nitori ọrọ to sọ nipa Aarẹ Muhammadu Buhari.

Alaga ẹgbẹ APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, sọ pe inu awọn ko dun si awọn ọrọ abuku ti Tinubu, ti ọpọ n wo gẹgẹ bi asiwaju ẹgbẹ, sọ nipa aarẹ.

“Ko ba ma ti sọ ohunkohun nipa Buhari to jẹ ẹni apọnle ninu ẹgbẹ wa, tabi darukọ rẹ rara.”

O ni aṣiṣe nla gba a ni bi Tinubu ṣe sọrọ buhari laiṣe pe o wa nibẹ.

Ọjọbọ ni Tinubu sọ nilu Abeokuta pe oun ni igi lẹyin ọgba to mu ki Buhari de ipo aarẹ Naijiria lọdun 2015.

Ọrọ naa ṣi n fa ariynajiyan laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaa lori ayelujara.

Bo tilẹ jẹ pe Tinubu pada sọ pe awọn eniyan ṣi oun gbọ ni. O ni oun ni apọnle ati ọ̀wọ̀ pupọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, ti oun ko si le tabuku rẹ.

Ṣugbọn alaga ẹgbẹ APC, Abdullahi Adamu ṣapejuwe ọrọ ti Tinubu sọ pe “ẹ̀pa kò bóró mọ́”.

O ni o yẹ ko tọrọ aforiji lọwọ Buhari ni.

Bakan naa ni alaga naa sọ pe gbogbo awọn oludije fun ipo aarẹ ni yoo kopa ninu idibo abẹle, tako iroyin to n lọ pe wọn ti yọ awọn kan danu.

Mi ò jẹ́ fẹnu tẹ́mbẹ́lú Ààrẹ Muhammadu Buhari, ènìyàn pàtakì ni lọ́wọ́ mi – Tinubu

Bí awuyewuye ṣe gba gbogbo ìlú kan lórí ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ ni ọjọ́bọ̀, Tinubu ṣàlàyé ara rẹ̀.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ní òun kò jẹ́ fi ẹnu tẹ́mbẹ́lú Ààrẹ Muhammadu Buhari àti pé àṣìgbọ́ ni bí àwọn ènìyàn ṣe ń tú ohun tí òun sọ ní ìlú Abeokuta.

Tinubu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹfà ọdún 2022 ní nínú èròńgbà òun láti di Ààrẹ Nàìjíríà àwọn nǹkankan wà tí òun kò gbọdọ̀ ṣe láéláé àti pé àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí òun kò gbọdọ̀ gbé.

“Mi ò gbọdọ̀ tàbùkù ara mi nípa sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ààrẹ Muhammadu Buhari tàbí ipò rẹ̀.”

“Báwo ni máa ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu ọ́fíìsì tí mò ń wá?”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tinubu ń fèsì sí bí àwọn ènìyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ òdì sí lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nígbà tó ṣe ìpolongo lọ sí ìlú Abeokuta.

Ó ní bí kò bá sí ipa ùn nínú ètò òṣèlú ọdún 2015, Ààrẹ Muhammadu Buhari kò bá ti má di Ààrẹ àti pé ipa òun nínú òṣèlú Nàìjíríà kò kéré rárá.

Ọ̀rọ̀ yìí sì tí ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wí pé Tinubu fi ẹnu tẹ́mbẹ́lú Ààrẹ Buhari ní.

Tinubu wá ní òun ní ọ̀wọ̀ púpọ̀ fún Ààrẹ Buhari àti pé àwọ

n tí ohun tí òun sọ yẹn jẹ́ láti fèsì sí àwọn kan tó ń ṣe ìkọlù sí òun nípa ìpolongo ìdìbò wọn.

Ó fi kún pé bí ìpolongo láti gbá àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ti ń le si àwọn ènìyàn ti sọ onírúurú ọ̀rọ̀ nípa òun tó sì jẹ́ wí pé irọ́ ni gbogbo rẹ̀ dálé lórí.

Ó sọ síwájú pé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí òun sọ ní láti fìdí òtítọ́ múlẹ̀ nípa òun àti pé ó yẹ kí àwọn ènìyàn mọ èyí tó ń jẹ́ òtítọ́ àti ibi tí òun fì sí.

“Àwọn ta jọ ń dupò ló ń gbé ìròyìn náà bí ẹni pé mo sọ̀rọ̀ òdì sí Ààrẹ Muhammadu Buhari kí Ààrẹ le rò wí pé mó kọ iyán òun kéré kó sì lòdì ìjẹyọ mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ APC.”

“Àmọ́ mo ní ìgbàgbọ́ wí pé olóye ènìyan ni Ààrẹ Buhari kò ní léti nínú gbogbo àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ bẹ́ẹ̀.”

Bákan náà ló ní gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC ni òun yóò faramọ́ àti pé òun yóò kún ẹnikẹ́ni tó bá gbégbá orókè níbi ìdíje náà lọ́wọ́ kòdá bí kò ṣe òun.