Queen Elizabeth 70th: Ọbabìnrin kò ní lè kópa nínú ìjọsìn St Paul's Cathedral lónìí

Aworan Obabinrin Elizabeth

Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi, Queen Elizabeth ko ni kopa ninu ayẹyẹ ijọsin ọdun aadọrin to gun ori oye ti o n waye ni St Paul's Cathedral lonii.

Ọbabinrin ni awọn eleto ilera Aafin kẹfin ilera kudiekudie nigba ti o darapo mo awọn ara ilu fun ojo akoko ayẹyẹ ni Buckingham Palace lojobo ana.

Wakati diẹ lẹyin ayẹyẹ akoko lana, Ikede jade lati Aafin pẹ Obabinrin Elizabeth ko ni kopa ninu ayẹyẹ ijọsin naa lonii.

“ Obabinrin dupẹ lowo awọn to darapo mọ ọ loni fun ayẹyẹ manigbagbe naa”.

Ayẹyẹ naa ti o tẹsiwaju lọjọ abameta nibi ti Obabinrin yio ti maa wo fifi ẹshin saree "Epson race" niluu Derbry, ṣugbọn a ko lẹ sọ boya Obabinrin naa yio darapo mo ayẹyẹ ọhun lola.

Àwòrán ‘Portrait’ Queen Elizabeth ti jáde láti ṣayẹyẹ ọdún 70 gẹ́gẹ́ bí Ọba Ilẹ̀ UK

Aworan Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi, Queen Elizabeth ti jade ṣaaju ayajọ ayẹyẹ ọdun aadọrin to gun ori oye.

Ayaworan Ranald Mackechnie lo ya fọto naa ni ibẹrẹ ọdun yii ni Victoria Vestibule to wa ni Windsor Castle.

Awọn to ṣeto ayẹyẹ naa ni ohun meremere lorisirisi ni yoo waye lasiko ayẹyẹ naa.

Ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni yoo bọsi igboro lati ṣe ayẹyẹ aadọrin ọdun ti ọbabinrin naa gori oye. Ọjọ mẹrin ni wọn yoo fi ṣe ayẹyẹ naa, eleyii ti yoo bẹrẹ ni Ọjọbọ, ti yoo si pari ni Ọjọ Isinmi.

Bí àwòrán Ọbabìnrin náà ṣe rí...

Aworan Obabinrin Elizabeth

Ọbabinrin Elizabeth naa ti wọn ya aworan rẹ joko ni ori aga ni ẹgbẹ ferese

Ọbabinrin naa ri bi ẹni ti ọkan rẹ balẹ.

Afin ti Ọbabinrin naa ti wa fun ọpọ ọdun diẹ bayii ni wọn ti ya aworan naa

Bi eto ayẹyẹ naa yoo ṣe lọ niyii

aworan bi eto ayeye odub aadorin obabinrin

Ninu ọrọ Obabinrin naa si awọn eniyan rẹ ni o ti dupẹ lọwọ gbogbo eniyan fun aduroti oun pẹlu ipinnu pe oun yoo lo asiko yii lati fi woye bi oun ṣe lo aadọrin ọdun lori oye.

• Ọjọbọ ni eto naa yoo bẹrẹ pẹlu ayẹyẹ ni igboro pẹlu awọ orisirisi ti awọn eniyan yoo wọ kaakiri igboro pẹlu awọn soja lori ẹṣin lorisirisi.

Ni irọlẹ Ọjọbọ ni wọn yoo tan ina to le ni ẹgbẹrun mẹta kaakiri Ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi ayẹyẹ fun Ọbabinrin naa.

Aworan aadorin Obabinrin Elizabeth

• Ọjọ Ẹti ni wọn yoo lọ si St Paul’s Cathedral lati lo ṣe isin idupẹ, ti wẹjẹ-wẹmu yoo si waye ni irọlẹ ọjọ naa.

• Wẹjẹ wẹmu tẹsiwaju kaakiri ilu ati igboro Ilẹ Gẹẹsi pẹlu ounjẹ lorisirisi fun awọn eniyan.