Èròngbá Ààrẹ Buhari láti yan Ààrẹ túntún kó bá òfin mú - Dino Melaye

Agba ọje ninu ẹgbẹ oselu People Democratic Party PDP, Dino Melaye ti bu enu atelu bi Aarẹ Muhammadu Buhari se beere fun anfani ati igbaruku ti lati ọdọ awọn Gomina ẹgbẹ oselu All Progressive Congress APC lati fa ẹni ti yoo dipo rẹ gẹgẹ aarẹ lọdun 2023 kalẹ.
Melaye ninu fido kan to fi si ori ayelujara Twitter rẹ ni erongba Aarẹ yii lodi si ofin orile-ede Naijiria ati pe aba naa ni o jẹ aba gẹgẹ bii ologun.
O ni se ni Aarẹ fe fi tipatipa gbe Aarẹ tuntun le awọn ọmọ orilede yii lori, ti o si tako ofin ati pe iwa alaibikita ẹto ọmọniyan ati aralu ni Aarẹ fẹ hu.
“Nnkan ti Aarẹ sọ fun awọn Gomina APC ko ba ofin nitori Aarẹ fe lo ogbon ijapa fun awọn ọmọ orilede Naijiria ni".
“Bawo ni Aare o se ma bere fun anfani lati yan ẹni ti o ropo rẹ. Kini idi ti Aarẹ o fi ni oun ni ọmọ ti yoo rọpo rẹ lati gba asia ẹgbẹ oselu APC.”
“ Sugbọn awa ko ni gba fun Aarẹ o, tio o ba di ọdun 2023, A setan lati gba ijọba lọwọ Aare Muhammadu Buhari “

Àbá ààrẹ lè fa ìfàsẹ́yìn wá sínú ẹgbẹ òṣèlù APC

Bakan naa, Minisita nigba kan ri ati Agba ọje ninu ẹgbẹ oselu APC, Adebayo Shittu naa pẹlu Dino Melaye lati tako erongba Aare Muhammadu Buhari.
Shittu se ikilọ pe igbinyanju Aarẹ le fa ọpọlọpọ ifasẹyin fun ẹgbẹ oselu APC.
Shittu, nigba ti o soro lori amohunmaworan Channels l'Ọjọru ọsẹ yii ni Aarẹ Muhammdu Buhari ko ni agbara lati yan Aarẹ tuntun, ti o si rọ Aarẹ lati jẹ ki ẹgbẹ oselu APC yan ẹni tio gbe asia ẹgbẹ naa lọdun 2023.
“Mo fẹ rọ Aarẹ ati awọn Gomina lati jẹ ki awọn ọmọ orilede Naijiria yan Aarẹ tuntun to ba wu wọn, mo dẹ fẹ rọ Aarẹ lati ma gbe ọmọ oye kankan le ẹgbẹ oselu APC lori.”
O ni erongba Aarẹ ni a ko gbọdọ gbinyanju lati tẹle nitori ẹgbẹ oselu APC je ẹgbẹ ti o fẹran ijọba awarawa.”
Aarẹ Buhari ninu ipade pẹlu awọn Gomina ni ọjọ kokanlelogbon oṣu karun-un ọdun 2023, ni ojuṣe oun ni lati gbaruku ti ẹgbẹ oselu APC nibi eto idibo abẹle ati lati rii pe ẹgbẹ oṣelu naa jawe olubori ni eto idibo ọdun 2023.













