APC 2023:Àgbẹ́yẹ̀wó àwọn olùdíje sípò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ̀síwájú

Oríṣun àwòrán, professoryemiosinbajo
Igbimọ to n ṣagbeyẹwo awọn oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ti tẹsiwaju ayẹwo awọn oludije mii lọ̣jọ Iṣẹgun.
Igbimọ naa ti Alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹri , John Oyegun n dari rẹ ni wọn bẹrẹ iṣẹ wọn ni Ọjọ Aje.
Wọn n ṣe agbeyẹwo awọn oludije yi ṣaaju idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu naa ti yoo waye ni Ọjọ Kẹfa ati Ọjọ Kẹjọ, ọdun 2022.
Ile itura Transcorp Hilton ni agbeyẹwo naa ti n waye ni Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Bola Tinubu, gomina ipinlẹ Jigawa, Abubakar Badaru, minisita eto irinna tẹlẹri, Chibuike Amaechi ati gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Ibikunle Amosun wa lara awọn ti wọn ti ṣayẹwo wọn.
Minisita fun eto Eko, Chukwuemeka Nwajiuba, gomina ipinlẹ Ebonyi, Dave Umahi, Aare ilẹ igbimọ aṣofin agba tẹlẹri, Ken Nnamani ati gomina ipinlẹ Zamfara, Sani Yarima ko gbẹyin nibẹ.
Lara awọn to tun wa nibẹ ni Felix Nicholas, Sẹnatọ Borroffice, Abilekọ Uju Ken-Ohaneye ati Pasitọ Tunde Bakare.
Awọn oludije miran ti o yẹ ki wọn ṣayẹwo wọn ni Ọjọ Iṣẹgun ni yii
Yemi Osinbajo to jẹ igbakeji aarẹ Naijiria pẹlu awọn to kọkọ fi ero rẹ han lati dije dupo aarẹ ni idibo gbogboogbo, ọdun 2023.
Lọjọ Iṣẹgun yi la si ri aworan rẹ loju opo Facebook nibi ti awọn igbimọ ti n ṣe ayẹwo fun.
Bakan naa Kayode Fayemi to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti toun naa n dije dupo aarẹ, to si ti jẹ minisita ohun alumọni ni ọdun 2015 si 2018 yọju fayẹwo niwaju igbimọ.
A ko ri aworan Ahmed Lawan to jẹ Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin lọwọlọwọ botilẹ jẹ wi pe oun naa n dije dupo aarẹ labẹ asia APC.
Yahaya Bello to jẹ gomina ipinlẹ Kogi naa wa lara awọn oludije, to si jẹ ẹni to kere ju lọjọ ori laarin awọn oludije ni ẹni ọdun mẹrindinlaadọta.
Awọn miran to ku ni Godswill Akpabio, Dimeji Bankole ati awọn miran.

Oríṣun àwòrán, JKayodeFayemi

Oríṣun àwòrán, JKayodeFayemi












