Olùdásílẹ̀ ilé ìtura Hilton Rahmon Adedoyin ló ní kí n sọ fawọn ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sùn ilé ìtura wà

Igbẹjọ tẹsiwaju lọjọ Aje lori ẹjọ iṣekupani oloogbe Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ti wọn ba oku rẹ ni ile itura Hilton Hotel ni Ife.
Nibi igbẹjọ naa, afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola tu kẹkẹ ọrọ lori bi oludasilẹ ile itura naa ṣe ni koun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.
Adesola sọ fun adajọ pe Dokita Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem pe oun wa si ile igbe wọn ti wọn si sọ pe koun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.
"Emi pẹlu Roheem Adedoyin ni a jọ wọle lati lọ ba Dokita Rahmon Adedoyin ninu ile wọn. Nibẹ ni Dokita ti sọ pe ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke ko sun Ile itura Hilton Hotel Honour ni ọjọ taa n wi yi.''
"Wọn bere boya mo gba owo sinu akanti banki UBA mi, mọ dẹ ni bẹẹni. Wọn ni ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke kò sun ilé ìtura naa ati pe mi o gbọdọ darukọ awọn alakoso ile ìtura Hilton Hotel Honour fun awọn ọlọ́pàá."
O tẹsiwaju pe "Dokita Rahmon Adedoyin ni awọn o ba fi owo sinu banki mi sugbọn awọn ọlọ́pàá yoo mọ. Wọn ni ki emi àti agbẹjọ́rò wọn lọ ba awọn ọlọpaa nile itura wọn iyẹn Hilton Hotel Honour."

Ọmọ Adedoyin fún mi ní Receipt mìí tó ní nọ́ḿbà ìdánimọ̀ ti mọ̀ kò fún Timothy Adegoke láti kọ orúko ẹlòmíràn sii -Adedeji Adesola
Osisẹ ile ìtura Hilton Hotel Honour Adedeji Adesola ni ọmọ dokita Rahman Adedoyin ti oruko rẹ n jẹ Roheem Adedoyin fun oun ni iwe ọja miiran lati lo orúkọ ẹlomiran sì, ki oun si fun awọn olopaa ti wọn ba ti beere iwe ọja naa.
Adesola Adedeji ni awọn alasẹ ile ìtura naa ti ṣaaju fẹsun kan oun pe oun sọ iwe ọja ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 7316 nu ati pe awọn ọlọpaa si ti n beere iwe ọja yi.
Adesola si sọ fun ile ẹjọ pe ọrọ ko ri bẹẹ nitori oun ti fi iwe yi ranṣẹ pẹlu isiro owo tawọn pa sọwọ si olusiro owo ile itura naa.
Adesola sọ fun ilẹ ejo pe ilu Ilesha ni oun wa nígba ti akẹgbẹ rẹ Esther Asigo pe oun lati ma bo níbi ipade naa ti oun si ni oun ko le f’oju han si ipade naa nitori ona òun jin.
"Roheem Adedoyin pe mi si inu ile kan, o sọ fun mi wipe awọn ọlọpaa ni wọn beere ìwé ọja receipt ti nọmba rẹ jẹ 7316.''
" Mọ ni pẹ ko si aṣiṣe kankan ninu iwe akanti mi tori pe mo ṣe ìwe akànti naa dáadáa.
"O ni oun fẹ ran mi lọwọ pe oun ma fun mi ni iwe ọjà miiran. O wa sọ pe kin kọ Adewale Lekan si ori receipt yii, kín si buwọlu.Dokita Rahman Adedoyin ati ọmọ wọn ní ki n fun awọn ọlọpaa ni receipt yi ti wọn ba ti beere rẹ lọwọ mi"
Adesola fi kun ọrọ rẹ pe ''nigba ti awọn ọlọpaa mu mi de ọfisi wọn ni Osogbo, insipẹkitọ kan fi iwe akanti kan han mi ti mo si ni kii ṣe akanti ti mo gbẹ fun 'auditor' Kunle Adebayo ree.''
O ni oun beere aaye lati mu ẹrọ ibanisọrọ oun nibi ti aworan iwe akanti toun ya wa.
"Mọ beere fun anfani lati mu ẹrọ ibanisọrọ mi ti insipẹkitọ si lọ ba mi mu wa. Mo wa fi aworan akanti tí mọ gbe fun auditor Kunle Adebayo han inspector olopaa lori foonu mi''

"Mọ sọ fun ọlọpaa naa pe 'hand writing' yẹn yatọ si temi ati pe awọn oṣiṣẹ miiran bi checker ni ile itura wa gbọdọ buwọlu ṣugbọn ko si nkan to jọ bẹ ninu iwe ti wọn gbe fun mi''
"Owo ti mọ san si akanti ilé ìtura Hilton Hotel lati banki IBTC jẹ ẹgbẹrun lọna metalelogorun naira sugbọn owo ti inspector fi han mi kere si iye naa.
Adesola Adedeji ni lẹyin alaye oun ni awọn ọlọpaa lọ mu awọn afurasi yoku.
Adajọ sun igbẹjọ lori ẹjọ yi si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2022.












