Osun Hotel Murder: Ohun táa mọ̀ rèé nípa ikú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì OAU tó kú sí hòtẹ́ẹ̀lì Osun àti bí ọwọ́ ṣe tẹ olùdarí hòtẹ́ẹ̀lì

Oríṣun àwòrán, Facebook/Timothy Adegoke/Oduduwa University
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kede pe awọn ti mu alaga ati oludasilẹ ile itura Hilton Hotel and Resort, Ile-Ife, Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin.
Eyi ko si ṣẹyin iwadii ti wọn lawọn n ṣe lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, OAU, Timothy Adegoke ti wọn ni o de si ile itura Hilton ko to ṣaadede poora.
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Opalola Yemisi fi ṣọwọ si BBC, o ni ṣaaju ki awọn to mu Adedoyin, awọn ti mu eeyan mẹfa kan ti awọn fura si pe wọn mọ si iku akẹkọọ yii.
Ẹwẹ, BBC Yoruba ti kan si idile Timothy, a si ba iyawo, baba ati iya rẹ ni gbolohun nibi ti wọn ti ke gbajare pe: Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta
- Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l'Abeokuta, bó ṣe lọ rèé
- Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ - Akintoye
- Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, Ijọba Eko sọrọ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ igbẹjọ́ lórí #EndSARS
- 'Ó ṣeéṣe kí ẹ̀dà ìwé àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ EndSARS tó lu sórí ayúlujára yàtọ̀ sí èyí t'íjọba yóò gbé jáde'
- Ìdí nìyí tí mo fi kọ́ ilé ẹ́kọ́ fáwọn Daran-daran Fulani - Sheikh Gumi
Timothy Adegoke la gbọ pe o de si ile itura Hilton lati Abuja lọjọ Kaarun oṣu Kọkanla ti o si fẹ sun sibẹ ki o baa le ribi kopa ninu idanwo ẹka ileẹkọ OAU ti yoo waye lọjọ keji.
Lọjọ Keje Oṣu Kọkanla ni wọn kede pe Adegoke ti di awati lẹyin ti iyawo ati awọn mọlẹbi rẹ ko gburo rẹ mọ.
Lẹyin tawọn mọlẹbi fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Edun Abon Police, wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran iyẹn State Criminal Investigation Department lọjọ Kẹsan oṣu Kọkanla.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oduduwa University
Abalọ ababọ, ọlọpaa lawọn ri oku Adegoke ninu saare kan ti wọn sin in si ti wọn si ti gbe oku naa lọ fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣeku pa.
Bakan naa wọn lawọn ti mu eeyan mẹfa kan tawọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju ati pe awọn n fi ọrọ wa Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin lẹnu lati mọ ohun to ṣẹlẹ gaan.
- Èèmọ̀ rèé o! Òkú ọmọ tuntun pòórá nílé ìgbókúpamọ́sí nílùú Akurẹ
- Àlàyé rèé láti ẹnu ilééṣé ọlọ́pàá lórí ikú akọ̀ròyìn Vanguard, Tordue Salem
- Èèyàn mẹ́rin kú sábẹ́ ilé alájà kan tó dàwó ní Badagry
- Nítorí òbítíbitì ìdọ̀tí la ṣe ti ọjà Oyingbo pa - Folashade Tinubu-Ojo
- 'Irọ́ ńlá lẹ pa, Lai Mohammed ò kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate'
Ki lo le mu ki wọn ṣeku pa Adegoke ni ile itura to de si?
Ibeere yi lo gba ẹnu awọn eeyan to n fọkan ba ọrọ yi bọ lati igba to ti lu sita.
Onimọ iwe iṣiro ni Adegoke to si fi ilu Abuja ṣe ibujoko.Ẹekọọkan lo n de si ile itura Hilton nitori eto ẹkọ to n ṣe ni ẹka fasiti OAU to wa ni Moro.
Ninu nkan ti ẹgbọn rẹ kan sọ fun gbajugbaja akọroyin nilu Ibadan, Olayomi Hamzat ninu fọnran fidio, awọn oṣiṣẹ ile itura lo gbimọran pọ lati pa Adegoke.
Ọrọ yi ko ti ribi fidi mulẹ lati ọdọ awọn ọlọpaa.
Ni kete ti wọn ba gbe esi iwadii wọn jade, a o maa fi to yin leti
















