Badagry building collapse: Èèyàn mẹ́rin kú sábẹ́ ilé alájà kan tó dàwó ní Badagry

Awọn oṣiṣẹ panapana nibi iṣẹlẹ ile to dawo naa

Oríṣun àwòrán, lagos fire and rescue service

Lẹyin ọsẹ meji ti ile alaja mọkanlelogun kan wo lagbegbe Ikoyi ni ipinlẹ Eko ti ẹmi ọpọlọpọ si baa lọ, ile miran tun ti da wo lagbegbe Badagry ni ipinlẹ kan naa.

Amọṣa o, ile alaja kan leyi, eeyan mẹrin ni wọn ti yọ labẹ rẹ.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Atẹjade kan ti oludari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Margaret Adeṣẹyẹ fi sita, ileeṣẹ naa gba ipe pe ile alaja kan naa da wo lagbegbe Sunny filled flour mills Estate ni Magbọn, Badagry.

Atẹjade naa ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana to wa ni Badagry ti doola ẹmi eeyan marun ni abẹ awoku ile naa ti wọn n kọ lọwọ. Bẹẹni akitiyan n lọ lọwọ lati yọ awọn to ṣi ha si abẹ ile naa.

"Awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ni ile naa ni iṣẹlẹ naa ba ti wọn si ti doola wọn pẹlu oniruuru ifarapa, pupọ wọn lo si ti n gbadun ni ileewosan."

A ṣi n mojuto iroyin yii lati mọ bo ṣe n lọ si.