Police vs Olokada: Kí ló fa rúgúdù láárín ọlọ́pàá àtàwọn ọlọ́kadà ní Obalende, l'Eko?

Gbẹgẹdẹ gbina lọsan Ọjọru nigba ti awọn ọlọpaa atawọn ọlọkada lagbegbe Ọbalende nilu Eko gbena woju ara wọn.
Gẹgẹbi ohun ti awọn o ṣoju mi kan sọ fun BBC News Yoruba, ni nnkan bii agogo mọkanla owurọ ọjọru lawọn ọlọpaa ikọ Taskforce nipinlẹ Eko ya wo agbegbe abẹbẹ afara to wa ni Ọbalaende tawọn ti ihamọra ogun eyi to ba ọpọ awọn eeyan to wa lagbegbe naa, yala ọlọja tabi awọn to n gba ibẹ lọ si ibikan lojiji ti kaluku si bẹrẹ si ni sa asala kaakiri lati yẹra fun iro ibọn ti wọn n gbọ lakọlakọ.
- Wo Femi Otedola, Mr Eazi, E-money, Eniola Badmus, Ikorodu bois àtàwọn èèkàn tó ti fowó ránṣẹ́ sí Davido
- Nítorí òbítíbitì ìdọ̀tí la ṣe ti ọjà Oyingbo pa - Folashade Tinubu-Ojo
- 'Irọ́ ńlá lẹ pa, Lai Mohammed ò kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate'
- 'Gómìnà Sanwo-Olu kò tíì ka ìwé àbájáde ìwádìí EndSARS'
- Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
Lẹyin iṣẹju diẹ ni wọn ni o ṣẹṣẹ han si awọn eeyan pe awọn ọlọkada lawọn ọlọpaa naa wa ba.
Awọn kan lara awọn ọlọkada naa la gbọ pe wọn kọkọ doju ija kọ awọn ọlọpaa naa ki awọn ọlọpaa to le wọn wọ agbegbe ati sọkalẹ afara Ọbalende lọ si ọna Ikoyi ati Falọmọ.
Bi gbogbo eyi ṣe n lọ lawọn ọlọpaa naa n yinbọn kikankikan soke pẹlu tajutaju.

Nigba ti gbogbo girgiri naa yoo fi pari, ọpọlọpọ alupupu ọkada ni wọn ti ko ti akọroyin BBC News Yoruba si tun ri ọkada kan ti wọn ti dana sun.
Nigba ti skan lara awọn agbero kan tọrs naa ṣoju rẹ ṣalaye ọrọ fun BBC News Yoruba, O ni arakunrin to ni ọkada naa lo funra rẹ dana sii nigba ti awọn ọlọpaa naa fẹ fi tipatikuuku gbe.
"Arakunrin naa dana sii nitori pe o mọ pe bi wọn ba le gbe ọkada naa lọ, ko si bi oun ṣe fẹ rii gba mọ laelae lo fi kuku funrarẹ dana si"
Akitiyan akọroyin BBC News Yoruba lati ba ẹni to lewaju ikọ naa sọrọ lo ja si pabo pẹlu bi awọn ọlọpaa naa ṣe pakuru mọọ ti wọn si ni awọn yoo luu ni alubami bi ko ba tete wabigba.












