Lai Mohammed on Lekki Toll Gate: Irọ́ ńlá lẹ pa, Lai Mohammed ò kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate - Iléeṣẹ́ ìròyìn àti àṣà

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Ministry of Information and culture

Ileeṣẹ to n ri eto iroyin ati aṣa eyi ti Minisita Lai Mohammed n ṣe adari fun ti fesi si iroyin kan to sọ pe Ọgbẹni Lai ti yi ẹnu pada pe oun sọ pe eeyan kankan o ku ni Lekki tollgate eyi tii ṣe ibi ti iṣẹlẹ ifẹhonuhan EndSARS ti waye.

Ileeṣẹ naa fi eyi sita loju opo lati bu ẹnu atẹ lu iroyin naa ti ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan to n jẹ Igbere TV gbe sita.

Minista Lai Mohammed jẹ eeyan kan ti ẹnu kii ṣi lori rẹ pẹlu bo ṣe maa n fi gbogbo igba duro lori ọrọ rẹ to maa n sọ pe ko si eeyan kankan to ku latọwọ ibọn yinyin to ṣẹlẹ ni Ogunjọ oṣu Kẹwa ọdun 2020.

Ọrọ yii tun wu sita pada toripe iroyin abajade igbimọ iwadii EndSARS ti jade ti awọn ọmọ igbimọ si ti gbe e le gomina ipinlẹ Eko lọwọ bo tilẹ jẹ ijọba ni awọn ko tii boju wo abajade naa.

Bakan naa ni ileeṣẹ ologun Naijria naa ni awọn ko tii wo abajade ọhun amọ pẹlu ohun tawọn n gbọ latara iroyin to n fo kiri, awọn ri kọnu n kọhọ ninu abajade naa amọ o da ileeṣẹ ologun loju pe awọn mọ iṣẹ awọn daju.

,Ẹwẹ̀ lẹyin eyi ni ileeṣẹ iroyin kan gbe e jade pe Lai Mohammed ti ko ọrọ rẹ jẹ pada amọ lọgan ni ileeṣẹ to n ri si eto iroyin ati aṣa sọ pe irọ funfun balau ni.

Igbimọ aṣewadii naa gbe abajade iwadii wọn jade ni ọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla ninu eyi ti wọn ti sọ pe awọn eeyan kan ku lọjọ iwọde EndSARS ijọba si ni kii sii kii ṣe ọlọpaa tabi ologun Naijiria lo wa nidi rẹ eyi ti ijọba tun ti kọkọ sọ pe ko sẹni to ku.

Lati igba naa ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti n reti ọrọ latẹnu Minisita Lai Mohammed ko da si abajade iwadii igbimọ naa.

Àkọlé fídíò, Ọdún 1999 ni mo tí ń gbìyànjú láti gba SAN kí wọ́n tó fún mí ẹ̀ní ọdún 90 -Toriola Oyewo