November 16 Public Holiday: Gómìnà Obiano fòntẹ̀ lù àyájọ́ Ọ̀jọ ìbí Zik, ó ní kí ìjọba àpapọ̀ náà ṣé bẹ́ẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Gomina ipinlẹ Anambra ti kede ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla gẹgẹ bi isinmi lẹnu iṣẹ lati fi ṣe ayẹsi Nnamdi Azikiwe.
Gomina Willie Obiano sọ pe awọn ṣe bẹẹ ni iranti ọjọ ibi agbaọjẹ oloṣelu ati olori nigba kan ri ni Naijiria yi.
Nnamdi Benjamin Azikiwe ti ọpọ a maa pe ni "Zik" lo jẹ aarẹ akọkọ ni Naijiria laarin ọdun 1963 si 1966.
Nilu Zungeru ni wọn ti bi Zik lọdun 1904 nibi to jẹ ipinlẹ Niger lode oni.
Ọdun ẹlẹẹkẹẹta ree ti ipinlẹ Anambra to jẹ ilu abinibi Zik yoo maa ṣe ayajọ yi ti wọn si yaa sọtọ gẹgẹ bi ọjọ isinmi.
Gomina Obiano ko fi mọ ni ipinlẹ rẹ nikan, o loun fẹ ki ijọba apapọ ya ọjọ yi sọtọ ko si di ọjọ isinmi kaakiri Naijiria.
O ni iru apọnle bayi naa ni wọn ṣe fun Kwame Nkruma lorileede Ghana ati Julius Nyerere ti Tanzania.

Oríṣun àwòrán, johan10
Amọ ṣa ijọba Naijiria ṣi ti ṣe ayẹsi Zik nipa fifi aworan rẹ sara ẹẹdẹgbẹta Naira owo Naijiria.
Lati oṣu Kẹrin ọdun 2001 ni ile ifowopamọ agba CBN ti ṣapọnle Zik pẹlu owo yi to jẹ owo to tẹle eleyi to ga julọ ni Naijiria

Azikiwe lo ṣe idasilẹ banki ifowopamọ tiwantiwa akọkọ,African Continental Bank, ṣugbọn banki yi ti kogba wọle
Fasiti Naijiria to wa ni Nsukka taa mọ si UNN, Zik naa lo da silẹ.
Lara awọn babanla orileede yi to ṣapa lati ri pe Naijiria gba ominira lọwọ awọn oyinbo amunisin ni Zik wa.
Eyi lo mu ki ọpọ maa ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ''Baba idasilẹ ijẹ orileede ni Naijiria''

Oríṣun àwòrán, UNN
Nnamdi Benjamin Azikiwe dagbere faye ni ilẹ iwosan eto ẹkọ ilera fasiti Enugu to wa ni Ituku.
O ku lọjọ Kọkanla oṣu kaarun ọdun 1996.
















