Love Making at Old Age: Eré ìfẹ́ wa kò wà láti bímọ, a kàn ń tẹ̀ẹ́ sójú rẹ̀ ni

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti di ọjọ́ ogbó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ

Awọn tọkọ-taya meji yii ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ohun ti wọn n ṣe to ran wọn lọwọ lati ri ọjọ alẹ papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya.

Bẹẹ ni wọn tun sọ nipa irufẹ ounjẹ ti wọn n jẹ, eyii to maa n fun wọn ni okun.

Gẹgẹ bi ọkọ ṣe sọ, o ni “Nigba ti mo wa ni kekere, mo maa n jẹ ororo pupọ, ṣugbọn ni bayii, mo maa n jẹ epo pupa...”

Bakan naa lo ni oun ti fi oyin dipo ṣuga.

Aya rẹ naa sọ pe awọn ounjẹ ti wọn maa n jẹ lasiko yii ni ẹwa, ẹfọ, igbin, ẹja, ati bẹebẹe lọ dipo ẹran ẹlẹjẹ.

Onimọ nipa oun to yẹ ki eeyan maa jẹ kole di ogbo to da si ọrọ naa ni “o yẹ ka maa jẹ ounjẹ to maa fun wa ni okun, ki a maa ṣere idaraya, ki a ma si maa wo aago alaago sare.”

Nipa ohun ti eeyan le ṣe lati gbadun ọjọ rẹ titi dalẹ, mama agba naa ni ohun kinni ni ki eeyan ma ṣe atojubọ, ko si gba ọlọrun gbọ.

Bakan naa ni ọkọ rẹ ni ko yẹ ki eeyan maa ṣe ju ara rẹ lọ nitori ko sin ẹni to le ni ohun gbgogbo tan nile aye.