Covid-19 Vs Homosexual: Alfa Abbas Tabrizian ń wáàsù kí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ má gba abẹ́rẹ́ Covid-19

Abẹrẹ Covid

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adari ẹsin Islam kan Alfa Ayatollah Abbas Tabrizian ti fi ọrọ sita pe abẹrẹ ajẹsara Covid-19 tawọn eeyan n gba lee sọ wọn di ẹni to fẹran ibalopọ akọsakọ tabi abosabo.

Ninu iwe iroyin Jerusalem Post, Alfa Tabrizian sọ loju opo Telegram rẹ to si ti ni awọn to n tẹle e to le ni igba miliọnu pe aburu ti abẹrẹ ajẹsara yii le ṣe ree.

Amọ ko fi ẹri pataki kankan han to fi gbe ọrọ rẹ lẹyin.

" Ẹ ma sun mọ awọn to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Wọn ti yipada si onibalopọ akọsakọ ati abosabo".

Iroyin sọ pe aafaa yii ni akọsilẹ itan ki o saba maa sọ ọrọ itako nipa awọn oogun oyinbo.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Bẹẹ naa ni awọn ọrọ to sọ laipẹ yii ti fa iriwisi ọtọọtọ ti awọn eeyan si n gbiyanju ati dẹru ba awọn eeyan ki wọn ma ṣe gba abẹrẹ ajẹsara.

Awọn ijọba orilẹede kaakiri si n fi aridaju han fun gbogbo agbaye pe ko si ewu kankan ninu gbigba abẹrẹ ajẹsara yii.

Ayatollah Abbas Tabrizian to jẹ araa Iran maa n gbe ara rẹ gẹgẹ bii "Baba awọn onimọ iṣegun ẹsin Islam" to si n fihan pe awọn oogun ti ẹsin ti pa oju awọn oogun ti oyinbo da si eyi ti ko wulo.

Ni ọdun to kọja ni fidio kan tan ka lori ayelujara to ṣafihan bi Tabrizian n sọ ina si iwe imọ iṣegun oyinbo kan to n jẹ Harrison's Manual of Medicine ọkan lara iwee Harrison's Principles of Internal Medicine to jẹ iwe pataki kan tawọn oniṣegun oyinbo maa n lo.

Ara ilẹ Iran kan to lodi si awọn nkan yii, Sheina Vojoudi sọ fun iwe iroyin Jerusalem Post pe erongba Tabrizian ni lati maa tan ọrọ ase ka lati maa dẹru sọkan awọn eeyan ki wọn ma gba abẹrẹ ajẹsara naa.

Bii ti awọn mii, gbogbo kudiẹ kudiẹ to ba yọju lara ọrọ abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Tabrizian n yi mọ ọrọ ibalopọ.

Oun kọ ni yoo kọkọ jẹ adari ẹsin to n sọ pe abẹrẹ ajẹsara Covid-19 m fa ibalopọ akọsakọ ati abosabo.

Oniwaasu kan naa nibẹrẹ ọdun yii sọ fun awọn ọmọlẹyin rẹ pe wọn ma gba abẹrẹ ajẹsara naa tori o lee sọ wọn di akọsakọ

Lọdun to kọja, pasitọ to jẹ eeyan ti aarẹ tẹlẹ ni Amẹrika, Trump fẹran, Rick Wiles fesi si ọrọ iku agbẹjọro onibalopọ akọsakọ kan to ko arun Covid pe idajọ Ọlọrunlo wa sori rẹ ati pe ajalu mla kan n bọ.

Ẹwẹ, ninu oṣu kọkanla oniwaasu ori tẹlẹfisan to lodii si ibalopọ akọsakọ ati abosabo to si ni aisan Covid-19 nii ṣe pẹlu aṣẹwo ati gbigbe igbe aye ẹṣẹ ni oun funrarẹ ku latari kiko arun Covid-19 yii kan naa.