Itan Manigbagbe: Oba Asanike Yefusu Oloyede, Olubadan tó gbóyà, aláwàdà, tó tún kún fún ọgbọ́n

Ọba Asanikẹ

Oríṣun àwòrán, The Cable

Ọba Yesufu Oloyede Asanikẹ ni Olubadan kẹtadinlogoji to jẹ niluu Ibadan.

Idile Asanikẹ ni adugbo Idi-Aro lo ti wa.

Gbajumọ oniṣowoo koko ni Ọba Asanikẹ.

Lati ọdun 1947 si lo ti n dari ilu lẹyin ti wọn fi jẹ Mọgaji agboole Asanikẹ.

Lọdun 1957, Oloyede asanikẹ di oloye laafin Olubadan, nigba ti Ọba I.B Akinyẹle fi joye.

Diẹdiẹ si lo gun akasọ oye, titi to fi di Olubadan ni ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 1983.

Ọdun mẹwaa ni Asanikẹ lo lori oye Olubadan. Ọpọlọpọ si ni ko gbagbọ pe yoo lo to iye ọdun naa, nitori pe o ti di arugbo kujọ-kujọ ko to o jẹ ọba.

Sugbọn lai fi ti ọjọ ori ati ipo ilera rẹ ṣe, itan sọ pe ọba to kun fun ọgbọn, imọ, igboya, iwoye, ati alawada ni.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Bakan naa lo jẹ pe kii rẹrin, ti kii si bẹru lati sọrọ.

Lara awọn 'ọrọ akin' ti itan sọ pe Asanikẹ sọ ni asiko ti aarẹ ologun, oloogbe Sani Abacha ṣe abẹwo si aafin rẹ.

Ọba Asanikẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hrh Oba Yesufu Oloyede-Asanike I

Eeyan nla, to ga, to sigbọnlẹ, ti oju rẹ n yọ ina, ni kabiesi n reti, amọ iyalẹnu lo jẹ fun lati ri pe Abacha ko ri bẹẹ.

Asanikẹ ko le pa iyalẹnu rẹ mọra, lo ba dahun pe "Abacha, a so o ju bayi lọ!''

Abacha paapaa bu si ẹrin.

Ẹru ẹnikẹni kii ba a, to fi mọ awọn ọmọ ologun.

Koda, gomina ologun kan fi ẹsun kan-an pe saara lo n fi òyè ṣe nilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Inu bi Asanikẹ debi pe pẹlu ibinu lo fi sọ pe ki gomina naa ko gbe ẹnu rẹ dakẹ. O ni "ọba ni gomina laaye rẹ, ọba ni emi naa laaye mi.

Ọrọ naa waye lẹyin ti Ọba Asanikẹ fi M.K.O Abiola, to jẹ ọmọ bibi ilẹ Ẹgba, jẹ oye Bashorun ilẹ Ibadan.

Ọba Asanikẹ ati MKO Abiola

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hrh Oba Yesufu Oloyede-Asanike I

Àkọlé àwòrán, Ọba Asanikẹ ati MKO Abiola

Ọpọlọpọ ọmọ bibi ilẹ Ibadan lo binu si ifinijoye naa, nitori wọn gbagbọ pe ọmọ ilu nikan ni oye naa tọ si.

Itan sọ pe Ọba Asanikẹ ni Olubadan to fi eeyan joye ju lọ, lai fi ẹya ti ẹni naa ti wa ṣe ni Naijiria.

Awọn kan ti ẹ gbagbọ pe o ma n ta oye fun ẹnikẹni to ba ti le san owo fun.

Asanike ati Oba Adeniji Adele ti ilu Eko, ati Alake ti Ẹ̀gba,ati Ọ̀ba Ademolalọ̀dun 1950

Oríṣun àwòrán, Twitter/ @yoruba history

Àkọlé àwòrán, Asanike ati Oba Adeniji Adele ti ilu Eko, ati Alake ti Ẹ̀gba,ati Ọ̀ba Ademolalọ̀dun 1950

Lara awọn ọmọ ilẹ okeere ti Asanikẹ fi joye ni ọmọ orilẹ-ede Lebanon, I-MUDAH to jẹ oniṣowo ni ọja Gbagi.

Oye Baba Laje ilu Ibadan ni Ọba Yesufu Asanikẹ fi jẹ.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Lori ọrọ ifinijoye yii naa, itan sọ pe awọn oloye rẹ kan ti inu n bi ko ara wọn jọ lẹyin ija kabiesi ati gomina ologun naa.

Wọn lọ si aafin Asanikẹ, wọn si sọ fun pe ko si oye kankan mọ ninu akọsilẹ lati fun ẹnikẹni.

Niṣe ni Asanikẹ tun sare fun wọn ni esi pe "oye tan, oye naa ni".

Lọdun 1983, laipẹ si igba to jẹ ọba ni eto idibo waye. Ija oṣelu si waye laarin gomina to wa ni ipo, Oloogbe Bola Ige ti ẹgbẹ oṣelu UPN, ati oludije ẹgbk oṣelu NPN, Dokita Ọmọlolu Olunlọyọ.

Olunlọyọ lo wọle, botilẹ jẹ pe awọn eeyan fi ẹsun kan pe magomago waye ninu idibo naa.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

Ọrọ naa di ti ile ẹjọ. Asanikẹ paapa lọ si iwaju igbimọ to n gbọ ẹsun idibo naa lati ṣe atilẹyin fun Olunlọyọ to jẹ ọmọ ilu Ibadan.

Gbangba lo ti sọ pe "ọmọ wa ni, ẹ jẹ o se", lai fi ṣe pe ilu Ibadan ni Bọla Ige gbe dagba, to ti n ṣe iṣẹ amofin, to tun fẹ ọmọ ilu Ibadan ni iyawo.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ọkan lara awọn iṣẹlẹ to tun jẹ manigbagbe lasiko ti Ọba Oloyede Asanikẹ wa nipo ni asiko ti awọn adigunjale kan wọ aafin rẹ, ti wọn si yọ awọn taya ati ẹya ara ọkọ lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ Olubadan.

Ọba Asanikẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Hrh Oba Yesufu Oloyede-Asanike I

Kiakia ni ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo l'aafin tẹ digunjale yii.

Pẹlu idinnu ati iwuri si ni awọn oṣiṣẹ alaabo naa fi ko awọn ole lọ siwaju kabiesi lati fi han pe awọn ṣe iṣẹ takun-takun.

Amọ, iyalẹnu lo jẹ nigba ti Kabiesi tu awọn ole naa silẹ, to si fun awọn alaabo ni esi pe "mi o ran yin pe kẹ ẹ sọ mọto, iyawo mi ni mo ni ẹ sọ".

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Itan sọ pe Ọba Asanikẹ ko fi inu tan ọkan lara awọn olori rẹ to fẹra, eyi si lo mu ko gba awọn ẹsọ alaabo lati ma a tẹle kiri. Boya o n yan ale.

Gẹẹgẹ lo ma n gbe awọn obinrin.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Iṣẹlẹ manigbagbe miiwo lo tun ṣẹlẹ?

Iṣẹlẹ manigbagbe mii tun ni lasiko ti awọn ọmọ ilẹ Afrika kan to tun jẹ ọmọ ilẹ America ṣe abẹwo si aafin rẹ.

Gẹgẹ bi iṣe rẹ, Olubadan tun ta omi oge si arẹwa obinrin kan nipa si sọ pe "Oo le lọ".

Itan sọ pe ẹru ba ọmọbinrin naa to ro pe Kabiesi ti fi ofin mu oun ni.

Ọba Asanikẹ ati ọ̀kan lara awọn olori rẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hrh Oba Yesufu Oloyede-Asanike I

Àkọlé àwòrán, Ọba Asanikẹ ati ọ̀kan lara awọn olori rẹ

Kia lo fi igbe ta, ki Kabiesi fun'ra rẹ to o mọ pe awada ti oun ṣe ti l'agbara ju.

O tọrọ aforiji, o si sọ fun un pe "mo fi n ba ọ sie ni".

Yatọ si awọn nkan wọn yii, Ọba Asanikẹ ni Olubadan akọkọ to gbe ninu aafin igbalode ni Ọja Ọba, nilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Oba Asanke lo ipo rẹ lati wa ilọsiwaju ilẹ Ibadan ati awọn ọmọ ilu.

O pese iranwọ fun awọn to fẹ ẹ wọ ileewe giga, ati awọn to n wa iṣẹ lara wọn.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 1993 lo waja.