SERAP sues Buhari: Àjọ SERAP gbé Ààrẹ Buhari lọ sílé ẹjọ́ nítorì kò wádìí N3B tó pòórá níléèṣẹ̀ ètò ẹ̀náwó

Oríṣun àwòrán, others
Ajọ to n polongo fun iṣejọba akoyawọ ati eto ọrọ aje ni Naijiria, SERAP, ti gbe aarẹ Muhammadu Buhari lọ sile ẹjọ nitori boṣe kuna lati wadii bilinu mẹta Naira owo ilu ni apo asunwọ ileeọ̀ẹ to n risi eto ẹnawo.
Kii ṣe Aarẹ Buhari nikan ni SERAP gbe lọ sile ẹjọ. O tun gbe minisita fun eto idajọ, to tun jẹ agbẹjọro agba Naijiria, Abubakar Malami, ati minisita eto ẹnawo, Arabinrin Zainab Ahmed.
Igbesẹ ajọ yii ko ṣẹyin awọn ẹsun kan ti ọfiisi oluyẹwe owo wo agba ni Naijiria fikan lọdun 2018 ati 2019 pe biliọnu mẹta Naira di awati tabi ko jẹ pe wọn na ni inakuna.
Ninu iwe ipẹjọ naa ti wọn mu lọ sile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Eko lọjọ Ẹti to kọja, ajọ SERAP sọ pe o ṣe koko fun Aarẹ Buhari lati ṣe iwadii bi owo naa ṣe poora, ko si sẹ igbẹjọ ẹnikẹni to ba jẹbi .
- Ìdí rèé tí Yahaya Bello fi gbọdọ̀ dá Amotekun sílẹ̀ ní Kogi- Gani Adams
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
Lara nkan ti SERAP tun kọ sinu iwe ipẹjọ naa ni pe awọn araalu lo n jiya iwa jẹgudu-jẹra naa, to si tun n ṣe akoba fun eto ọrọ aje.
Wọn ni ẹjọ ti awọn pe wa ni ibamu pẹlu ofin ọdun 1999 to sọ pe dandan ni fun awọn adari ilu lati pa iwa ibajẹ ati aṣilo ipo run.
Kinni ipinlẹ ẹsun owo to poora?
Ileeṣẹ eto ẹnawo sọ pe oun na owo to le ni miliọnu mẹrinlelogun Naira lati fi ṣe idanilẹkọ fun awọn to fẹ fẹhinti lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ko si iwe akọsilẹ kankan nipa eto naa.
Bakan naa ni akọṣẹmọṣẹ ti wọn lo sẹto idanilẹkọ na ko kọ iye owo to na fun idanilẹkọ, ṣugbọn ileeṣẹ ijọba san owo to le miliọnu marun-un Naira fun gẹgẹ bi owo iṣẹ.
Oluyẹwe owo wo tun ri pe ileeṣẹ eto ẹnawo ko le sọ bo sẹ na owo to le ni biliọnu meji Naira to gba lati apo ijọ̀ba gẹgẹ bi owo ajẹmọnu fun ṣiṣoju ijọba apapọ ni awọn ipade kan, ati fun kikopa ninu ajọ OPEC.
Wọn yii ni diẹ lara awọn owo ti ajọ SERAP sọ pe ileeṣẹ naa ṣe balabala, to si n fẹ ki Aarẹ Buhari wadii rẹ.
Igba akọkọ kọ niyi ti ajọ naa gbe ijọba Naijiria lọ sile ẹjọ lori awọn nkan to nii ṣe pẹlu iwa ibajẹ.













