MKO Abiola death: Abdulsalami ní ìjọba kọ́ ló pa Abiola bí ọ̀pọ̀ ṣe gbàgbọ́

Oríṣun àwòrán, Omololu Omotosho
Yoruba bọ wọn ni bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan bayii ni otitọ yóò le ba.
Lẹyin bi ọdun mẹrinlelogun ti gbajugbaja oniṣowo ati oloṣelu ni, Oloye MKO Abiola jade laye, olori ologun to jẹ adari ijọba ologun Naijiria nigba naa, ajagunfehinti, Abdulsalami Abubakar ti sọ pe eeyan kọ lo pa Abiola gẹgẹ bi ọpọ ṣe gbagbọ.
Abdulsalami ṣalaye pe aisan lo ṣe Abiola ki ẹlẹmii to gba a.
Abdulsalami lo sọrọ yii ninu ifọrọwerẹ to ṣe pẹlu ile iṣẹ iroyin Daily Trust.
- Dókítà àti Nọ́ọ̀sì di atọrọjẹ torí àjẹsílẹ̀ owọ oṣù mẹ́jọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ pásítọ̀ tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìyá àti ọmọ méjì
- Ọmọ Nàíjíríà, ẹ yé yan àwọn ‘Grandpa’ ní ààrẹ, ẹ wá ọlọ́gbọ́n ọ̀dọ́ tó tún sán-an-gun - Seyi Makinde
- Òjòwú-bìnrin fi ẹ̀rọ ìlọṣọ gbígbónà jó ọkọ ní abẹ́ àti ojú láti ojú oorun, ó sì gba ibẹ̀ kú
- Omijé lójú, ọ̀rọ̀ ìdárò àti orin èpè ní ọ̀dọ́ Eruwa fi dárò ikú bí Timothy Adegoke ti yóò wọ ilẹ̀ sùn lónìí
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
Abdulsalami Abubakar ṣalaye bi MKO ṣe jade laye
Abdulsalami ni "Mo rẹrin nitori orisiiriṣii nkan l'awọn eeyan maa n sọ pe o pa Abiola."
"Awọn kan tiẹ fẹsun kan wa pe awa ni a pa Abiola."
"Mo maa n dupẹ lọwọ Ọlọrun ni gbogbo igba ti mo ba sọ nipa iku Abiola fun bi Eleduwa ṣe fun mi ọgbọn ti o si dari igbesẹ mi lasiko ti Abiola ku."
"Ni ọjọ ti Abiola ku, ki Ọlọrun fi ọrun kẹ ẹ, nkan meji si mẹta ni mo maa n dupẹ lọwọ Ọlọrun fún."
"Akọkọ, mo gbalejo ikọ to wa lati orile-ede Amẹrika eyi ti Ọgbẹni Pickering ati Susan Rice wa níbẹ."
"Lẹyin ti a ki ara wa tan ni Pickering sọ pe awọn fẹ ri Abiola ṣugbọn wọn ko fawọn lanfaani lati le ri i."
"Lẹsẹ k'ẹsẹ naa ni mo pàṣẹ pe k'awọn iṣọmọgbe mi mu wọn lọ yọju si Abiola lahamọ to wa."
O ni "Ekeji ni pe, ni gbogbo igba ti Abiola fi wa lẹwọn, ko si ẹbi rẹ kankan to lanfaani lati yọju si i yatọ si dokita rẹ."
"Amọ, nigba ti mo di olori orilẹ-ede Naijiria ni mo ni ki wọn fun ẹbi Abiola ni ọjọ kan lati wa ri Abiola lẹyin ti mo ba oludije igbakeji rẹ ninu ibo aarẹ ọdun 1993, Babagana Kingibe."
Bi MKO Abiola se ku ree:
Abdulsalam ni o ku ọla ti Abiola maa ku ni awọn ẹbi rẹ wa si Abuja lati yọju si i.
O ni "a sọ pe awọn ẹbi Abiola ri i lana, ikọ ijọba orile-ede Amerika wa ri mi lonii, mo si paṣẹ pe ki wọn lọ ri Abiola.
Lasiko ti ikọ ijọba Amẹrika yii n ṣe ipade pẹlu Abiola gan an o bẹrẹ si ni ṣe aisan
Awọn ẹṣọ ologun at'awọn ikọ ijọba Amẹrika to n ṣe ipade lọwọ pẹlu rẹ lo gbe e digba digba lọ si ile iwosan.
Ṣugbọn nile iwosan naa ni o ti dagbere faye.
O ya mi lẹnu nigba ti wọn sọ fun mi pe Abiola ti ku.
Wọn ṣalaye fun mi pe nibi ti o ti n ṣe ipade lọwọ pẹlu awọn ikọ ijọba Amẹrika ni ailera rẹ ti bẹrẹ ti o fi gbẹmi mi."
Mo bẹrẹ si ni ronu bi mo ṣe maa sọ fun ẹbi Abiola pe o ti dagbere faye ati bi mo ṣe maa sọ fun gbogbo aye.
Bi a se tufọ fun mọlẹbi MKO Abiola ree:
Abdulsalam ni "Baba Gana Kingibe gbiyanju gan an, oun naa ni mo pe wí pe ki o mu ẹbi Abiola wa sọdọ mi.
Bayii ni a ṣe sọ nipa iku Abiola fun awọn ẹbi rẹ ti wọn si bẹrẹ si ni sọkun.
Emi gan an fun ra mi ni mo di ọwọ ọkan lara awọn obinrin to wa ninu ẹbi Abiola to wa sí Abuja mu lati tu u ninu ki Susan Rice Amẹrika to gba a lọwọ mi lati rẹ ẹ lẹkun.
Idi niyii ti mo fi maa n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun idari igbesẹ mi nigba naa tori ti n ko ba gba k'awọn ikọ ijọba Amẹrika lọ yọju si Abiola ni, bawo ni mo ṣe fẹ sọ faye pe Abiola ku?
Ta lo fẹ gba mi gbọ pe awa kọ ni a pa Abiola lasiko ti wọn sọ pe awọn fẹ ri i?"
Ẹbi MKO Abiola tako ọrọ Abdulsalami Abubakar lori iku rẹ:
Ẹbi oloogbe MKO Abiola ti tako ọrọ ti ajagunfẹyinti Abdulsalami sọ pe Abiola ṣe aisan lo fi ku.
Jamiu Abiola, ọkan lara awọn ọmọ oloogbe MKO Abiola ni Abdulsalami dena itọju ara to peye mọ Abiola lo fi ku.
"Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ bi ọdun mẹrinlelogun sẹyin.
Agbalagba ni Abdulsalami, mo maa n ro pe agbalagba kii parọ ni, ṣugbọn ọrọ ti Abdulsalami sọ ya mi lẹnu.
Abdulsalami ni oun loun fun ẹbi Abiola lanfaani lati le ri.
Ẹ bi i leere pe kilode to fi pe oṣu kan ki ẹbi Abiola to le yọjú si i?
Eeyan le jẹbi ẹsun ipaniyan lọna meji.
Akọkọ, ti o ba pa eeyan bi ijọba ologun Naijiria nigba naa ti ran Sergent Rogers lati yinbọn pa mọmọ mi, Kudirat Abiola.
Tabi ki o payan diẹ diẹ gẹgẹ bi ti Abiola lasiko ijọba Abdulsalami.
Mi o le sọ pe wọn fun baba mi ni nkan jẹ lo fi ku tori esi ayẹwo oku rẹ ko fidi rẹ mulẹ bẹẹ.



















