Alaba Bakare: Ìyàwó rẹ̀ fi òògùn orun sínú oúnjẹ fun, kó lè sùn fọnfọn láti fi ẹ̀rọ ìlọṣọ jo lójú oorun

Alaba ati Motunrayo Bakare

Oríṣun àwòrán, Taiwo Bakare

Adura to yẹ ki tọkọ-taya maa se ni pe Ọba Oke di awọn mu titi di ọjọ alẹ, to ba si dun ni aarọ, ko ma kan fun wọn lọsan ati ni alẹ

Ileesẹ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti nawọ́ gán obìnrin kan, Motunrayo Oluwatoyin Mulero-Bakare fún ẹ̀sùn pé ó pa ọkọ rẹ̀, Alaba Olusegun Oladapo Bakare.

Alaba Olusegun Oladapo Bakare tó ni ilé ìtura Bama Hotels and Suites tó wà ní agbègbè Abule-Egba ní ìpínlẹ̀ Èkó, ní ìyàwó rẹ̀ rán lọ sí ọ̀run láti ojú orun lálẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kìíní ọdún 2022.

Ìròyìn ní lẹ́yìn tí Motunrayo ati ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn tí ìrìn àjò dé láti Dubai ní ìròyìn kàn án lára pé ọkọ rẹ̀ ti fún obìnrin kan lóyún.

Ọkan lara awọn ile itura to jẹ ti Alaba

Ọna wo ni iyawo gba, fi pa ọkọ rẹ?

Gẹgẹ bi iwadii se lọ, ní alẹ́ ọjọ́ yìí ni wọ́n ṣe àríyànjiyàn lórí pé ọkọ fún obìnrin kan lóyún.

Iyawo naa jẹwọ pe oun fi òògùn orun sínú oúnjẹ fọ́kọ oun eyi ti yoo mu ko sun fọnfọn.

Lẹ́yìn tí ọkọ ti sùn fọnfọn tan ní Motunrayo mú ẹrọ ilọṣọ eyiun áyọ́nù gbigbóná, to si fi jó ọkọ rẹ̀ lábẹ́ àti lójú láti ojú orun.

Igbe oro, irora nla ati egbo gidi si ni Alaba bá a lọ sí ọ̀run lati ipasẹ iwa ika ti aya rẹ hu naa.

Ọdún kẹjọ rè é tí àwọn méjéèjì tí fẹ ara wọn, tí wọ́n sì ti bí ọmọ mẹ́ta funra wọn.

Ki ni ileesẹ ọlọpaa sọ nipa isẹlẹ naa:

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, Adekunle Ajisebutu ní wọ́n ti gbé òkú arákùnrin náà lọ sí yàrá ìgbóòkúsí ní ilé ìwòsàn Yaba Mainland fún àyẹ̀wò.

Motunrayo àti àwọn mẹ́ta mìíràn ní wọ́n ti nawọ́ gán lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bákan náà ni Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, Abiodun Alabi ti pàṣẹ pé kí wọ́n tarí ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka CID, Yaba fún ìwádìí tó péye.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ