Fathia Balogun: Ilúmọọka oṣere tiata, Fathia Balogun ṣetan lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọna ara.

Faithia Balogun Williams

Oríṣun àwòrán, faithiawilliams/Instagram

Ẹni ọdun ba ba laye, o yẹ ko se ọpẹ paapaa ọjọ ibi nitori eyi la maa fi n dupẹ fun Oluwa pe o da mi wa si lari ri ọdun tuntun.

Boya eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata, Faithia Balogun, to fi seto ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ fun ọdun ta wa yii ni ọna ara.

Fathia, to pe akori ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni ‘Faithia Unusual 2022’ ni ayẹy ọjọ ibi naa yoo waye lọjọ ketadinlogbọn oṣu keji ọdun 2022.

Bakan naa lo ti fi ekunrẹrẹ bi eto naa yoo ṣe lọ sori oju opo Instagram Bimbo Thomas, ọkan lara awọn akẹẹgbẹ rẹ lobinrin lagbo ere tiata.

Ikede bi owo asọ ẹbi naa yoo si se lọ ni Bimbo Thomas kede eyi to ni yoo jẹ ki awọn eeyan rere to nifẹ mọ nipa ayẹyẹ naa le mọ bo se yẹ

Àkọlé fídíò, Fathia Balogun: Kò sí ẹni tó bá mi lò pọ̀, kó tó fún mi ní isẹ́

Wo iye owo ti wọn n ta isọri asọ ẹbi kọọkan fawọn obinrin fun ọjọ ibi Fathia Balogun:

Ninu ohun ti o wa loju opo Bimbo Thomas, oriṣiiriṣii aṣọ ẹbí lo wa fawọn alejo ti yoo wa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa.

Isọri aṣọ ẹbí Platinum fawọn obinrin lo wọn julọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (₦150k) ni aṣọ naa pẹlu gele.

Isọri platinum fawọn ọkunrin, ẹgbẹrun lọna ọgọfa (₦120,000) ni aṣọ naa tii ṣe agbada ati fila.

Ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (₦60,000) ni aṣọ awọn obinrin pẹlu gele.

Bakan naa ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ni aṣọ awọn ọkunrin bakan naa.

Ikede nipa ọjọ ibi Fathia Balogun ti Bimbo Thomas gbe jade

Oríṣun àwòrán, iambimbothomas/Instagram

O wa fi apo asuwọn owo ile ifowopamọ sibẹ fun awọn eeyan to nifẹ lati ra asọ ẹbi naa pe ki wọn san owo si.

Bakan naa lo sọ fun wọn pe ki wọn fi risiti, eyiun ẹri pe wọn ti san owo naa sọwọ si oun gẹgẹ bi idaniloju pe lootọ ni wọn ti sanwo asọ ẹbi naa.

Ko tan sibẹ o, Ọlọjọ ibi tun kọ sibi ikede naa gadagba pe funra awọn eeyan to ba ra asọ ọjọ ibi oun ni wọn yoo san owo ọkọ fun ẹni ti yoo gbe asọ naa wa fun wọn nile.

Koda gan, lọjọ ibi funra r ti gbe ikede nipa ọjọ ibi naa soju opo Instagram rẹ.

Ohun t'awọn eeyan n sọ lori ayelujara:

Nigba ti awọn eeyan kan n foju sọna fun ọjọ ibi ọhún, niṣe l'awọn mii n beere wi pe nibo l'awọn ilumọọka oṣere tiata ti n rowo ti wọn n na lati fi ra asọ ẹbi gbogbo igba.

Koda kan ninu wọn ni plu bi wọn se n ra asọ ẹbi lọsọọsẹ yii, se wọn yoo ni ajẹsẹku bi?

Bi ọjọ ibi ọhun ti n kan ilẹkun gbọngbọn, awọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ si ni sọ nipa ayẹyẹ ọjọ ibi naa ti yoo waye nile itura kan niluu Eko.

Ikede nipa ọjọ ibi Fathia Balogun to gbe jade jade

Oríṣun àwòrán, faithiawilliams/Instagram

Ta ni oṣerebinrin Faithia Balogun?

Ọdun 1971 ni wọn bi Faithia Balogun niluu Eko bo tilẹ jẹ pe ọmọbibi ipinlẹ Delta l'awọn obi rẹ.

Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Maryland ni Faithia lọ niluu Eko.

O tun tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Maryland Comprehensive Secondary School.

Faithia lọ si ile ẹkọ gbogbonṣe Kwara Poly ki o to tẹsiwaju ni fasiti Olabisi Onabanjo nibi to ti gboye ninu ẹkọ ere ori itage.

Faithia jẹ oṣere, olootu ati adari ere.

O si ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ lẹnu iṣẹ ere ori itage ati igba to ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage.

Faithia ṣe igbeyawo pẹlu akẹgbẹ rẹ, Saheed Balogun.

Eledumare si fi ọmọbinrin kan ati ọmọkùnrin kan t'awọn lọrẹ.

Àkọlé fídíò, Yollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá