Saheed Balogun: Aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó mi, mi ò kí ń sá a níta gbangba

Oríṣun àwòrán, Saheed Balogun
"Awọn to sa aṣọ ikọkọ wọn sita lọjọsi wọn pada mu Garri rẹ".
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Saheed Balogun ni kii ṣe gbogbo ibeere ni ẹni ti wọn fi ọrọ wa lẹnuwo naa n fẹdahun.
Mo ti ko gbogbo owo ileewe lọ fi ṣe ere ori itage ri ti o jẹ pe ao ri owo mu bọ, awọn obi mi pada wa fi owo mii gba mi silẹ ni agọ ọlọpaa.
O ni nigba ti oun bẹrẹ ere Tiata leyi to ti le logoji ọdun sẹyin, oun ṣi wa nileewe koda awọn tun ma n lọ ja awọn iṣẹ mii mọ ara wọn ki owo le wa lọwọ ọmọkunrin.
Ọpọlọpọ iroyin lo ti wa nilẹ koda to ti wa lọkan awọn eeyan ti wọn fẹ lati mọ ẹkunrẹrẹ rẹ lati ẹnu ọlọrọ gangan, nipa ọrọ ifẹ laarin gbajugbaja oṣere Saheed Balogun ati iyawo rẹ tẹlẹ, Fathia Balogun.
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
- 'Títí ọdún mẹ́wàá gbáko! A o ni kó Àlùbósà lọ sílẹ̀ Ibo, kí la rí gbà nígbà tí ojà Sasha jóná?'
- Àjọ NECO kéde ọ̀gá àgbà fìdíhẹẹ́ tuntun lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ọ̀gá àgbà àná jáde láyé
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Ìjọba àpapọ̀ dá iléeṣẹ́ Twitter dúró lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀!
BBC Yoruba wa ni anfani lati gbalejo ọkan ninu wọn, Saheed Balogun, ọrọ nipa ara rẹ ni ibeere ti a kọkọ beere ti idahun rẹ si jẹ iwuri fun awọn ololufẹ rẹ to n wo o nile.
Ibeere nipa oun ati Fathia Balogun ṣi papa jade naa.
Iṣẹ ere sise Saheed Balogun:
bi Saheed Balogun ṣe tayọ awọn akẹgbẹ rẹ kọọkan to fi n ba awọn oṣere elede Gẹẹsi kopa ti yoo tun sọ ede Hausa ninu awọn ere mii, o ṣalaye pe "wọn bi mi si ilẹ Enugu, mo tun wa gbọ ede Hausa, amọ ni ti sisọ ede Gẹẹsi ninu ere, Ọlọrun kan yan mi fẹ ni tori aimoye awọn ti mi o tilẹ le duro lẹgbẹ wọn ninu ede Gẹẹsi sisọ.
Sibẹ mo si n ṣe daadaa ju wọn lọ tori naa, Ọlọrun kan wo sunsun ṣe mi laanu ni".
Saheed Balogun wa gba imọran pe ko dara ki eeyan maa jowu ẹnikankan ti Ọlọrun ba ti ni oun lo kan, "ohun to n ṣe ti tiẹ fi da a, iwọ naa ṣe e ki tiẹ fi da a".

Oríṣun àwòrán, Saheed Balogun
Awon osere miran ti a ko ri mọ nkọ?
Ni ti awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ bẹrẹ ti wọn jọ jẹ ogbontarigi ti awọn eeyan o ri mọ, Saheed ni ẹlomii ti lọ ilu Oyinbo, omii o si laye mọ.
O tun ni omii ti n ṣe iṣẹ mii pe oun si maa n kan si wọn ti oun si maa n fun wọn ni apọnle ju ẹni to ṣẹṣẹ de lọ ki wọn le kọ ẹkọ lara rẹ.
Lara awọn ti wọn ṣi jọ wa to darukọ ni Taiwo Hassan, Yinka Quadri.
O kọ lati darukọ awọn ti ko ṣe daadaa mọ tori o ni o le ko ironu ba ẹlomii tori o maa n bainu elere jẹ ko maa kọja lọ ki wọn maa gbọ pe ṣe ko ṣere mọ".
Ni kete ti atọkun mẹnu ba ọrọ Fathia Balogun to jẹ iyawo rẹ tẹlẹ, Saheed Balogun ni oun kan pọn BBC le ni oun ṣe dahun lati wa fun ifọrọwanilẹnuwo wọn amọ ni ti ọrọ yii ki wọn jami lori rẹ.
"Awọn ibeere kan wa ti eeyan lẹtọ lati ma dahun, eleyii aṣọ kọrọ ni mi o ki n sa a si gbangba. Gbogbo nkan kọ ni idakẹjẹ maa n bajẹ, gbogbo nkan si kọ lo maa n tun ṣe, mi o ni sọ ju Bayẹ́n lọ".
"Ọrọ ile ni o, ọrọ igba ẹni kan n ja ni o, mi o fẹ sọrọ nipa rẹ, aṣọ kọrọ ni mi o ki n sa iru rẹ sita tori jẹjẹ mi ni mo n lọ, ki Ọlọrun maa kẹ gbogbo wa". O ni keeyan ṣe bi ẹni ti ko gbọ ni iṣẹ awọn gba".
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Aàrẹ Muhammadu Buhari gba àmì ẹ̀yẹ Adarí tó dára jùlọ
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Bíi ti UK, USA, Germany, France lẹ ó lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù yín yàlàyòlò ní orílẹ̀èdè Yorùbá Nation - Igboho
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
Ọjọ ti ọrọ ba to sọ, maa sọ ọ".
Saheed ni awọn to sa tiwọn sita lọjọsi wọn mu Garri kẹyin ni. "Lootọ funra wa la yan iṣẹ taa n ṣe, aṣọ unfun ni wa to n rin ninu okunkun, aṣọ funfun ko si rọra ko ma baa kọlu elepo".
Saheed Balogun ni bi ẹlomii gan ba tẹ pẹpẹ ọ̀rọ̀ aye rẹ sita wọn a bi i pe ṣe ko niṣẹ ni, eyi si ni iyakun ayelujara ti ṣakoba fun".
Bi ibeere ṣe yi si awọn iṣẹ mii ti Saheed Balogun n ṣe niyẹn to si ṣalaye pe oun ti ni ileeṣẹ fiimu tirẹ to ti n kọ awọn ọdọ to ṣẹṣẹ n dagba.
Sayeed ni oun o ni igbagbọ ninu oni, oun gbagbọ ninu ọla toripe awọn agba oṣere kan naa lo gba oun laye ti gbogbo eeyan ṣe n pe inagijẹ oun, "Walata".
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- A tí ń gbé ìgbésẹ́ láti kó àwọn tó ja bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbà ní Ondo- Komisonna Bolaji Salami
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
Lori ọrọ Baba Ijesha:
Lori ọrọ pe Saheed Balogun wa lara awọn to n gba waju lati ri i pe akẹgbẹ wọn Olanrewaju Omiyinka ri itusilẹ,
Saheed kọ lati fesi ati lori awọn akẹgbẹ wọn to n ja lori ọrọ yii, o sọ lakotan pe "ohun to n jo wa lọwọ ni ka maa lo itakun ayelujara wa fun ju ki a maa ja lori rẹ lọ".
O ni awọn mii o yo ni wọn ṣe n ṣe nkan ti wọn n ṣe kii ṣe pe ki eeyan ma sọ ẹdun kan rẹ, ko ọ ko si kuro nibẹ.

















