Akure school bus hijacked: Mí kò dá àwọn agbébọn náà mọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò bojú- Omolayo Ojo
Wọn gbe ibọn sori mi pe ki n tẹle wọn ni- Omolayo Ojo to jẹ oluranlọwọ akékọọ ninu bọọsi.
Adari ile ẹkọ Chimola Schools ni wọn ti da gbogbo ọmọ pada ati pe ko si ẹni to sọnu mọ nile iwe naa.
Omolayo ti wọn gbebọn si lori naa ba BBC sọrọ lori bi gbogbo ẹ ṣe ṣẹlẹ.
Bakan na ni kọmiṣọnna Bolaji Salami to n tukọ agbofinro ipinlẹ Ondo naa ba BBC Yoruba sọrọ lori ibi ti igbesẹ wiwa bọọsi ati awọn oniṣẹ ibi naa ri de duro.
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND

A ti rí dírẹ́bà àti olùrànlọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú bọ́ọ̀sì- Adarí ilé ẹ̀kọ́ Chimola Schools, Akure
Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí nílé ẹ̀kọ́ wa, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé a rí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́- Bolatito Akindemowa
Arabinrin Bolatito Akindemowa to jẹ oludari ile ẹkọ Chimola schools ni Oba Ile Estate ni ilu Akure nibi ti awọn agbebọn ti sọṣẹ ni aarọ yii ti sọrọ sii lori iṣẹlẹ naa.
O salaye pe lasiko ti direba bọọsi to n ṣa awon ọmọ kaakiri ile wọn n lọ ni nkan bii aago mẹfa abọ owuro oni lo ṣẹlẹ.
Bi a ṣe n sọrọ yii, wọn ti ri direba to wa ọkọ naa ati Omolayo Ojo to jẹ oluranlọwọ awọn akẹkọọ ninu bọọsi naa pada.
Omolayọ Ojo salaye fun BBC Yoruba pe, awọn agbebọn naa gbe oun lọ sinu igbo ni.
- Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
O ni: Wọn ja oun sinu igbo naa, wọn si wa ọkọ bọọsi awọn akẹkọọ naa lọ.
Omolayo ni oun rin pada wa si oju titi ti oun si ri awọn alaanu fun pun lowo ọkọ wa si ile ẹkọ pada.
Adari ile ẹkọ naa ni wọn ti fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ati pe bọọsi nikan lo ku ti won n wa bayii.
O ni ko si akẹkọọ kanakan to sọnu.
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
Àwọn ajínigbé ṣọṣẹ́ ní Akure wọ́n kọlu bọ́ọ̀sì iléẹ̀kọ́ kan lọ
Awọn agbebọn kan ti kọlu ọkọ bọọsi ileewe kan lagbegbe Ọba ile Estate ni ilu Akurẹ.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn agbebọn naa ji eeyan kan gbe ninu awọn oṣiṣẹ to wa pẹlu awọn akẹkọọ naa.

Oríṣun àwòrán, other
Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni nnkan bi agogo meje ku iṣẹju diẹ lowurọ Ọjọbọ.
Iroyin fiyeni pe awọn ajinigbe naa ti wọn to mẹjọ niye wa lori alupupu ọkada nigba ti wọn yi bọọsi naa po ti wọn si wọ dẹrẹba ọkọ naa bs silẹ.
Awọn ajinigbe naa wa bọọsi naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ Lagos LSD 853 FJ lọ pẹlu skan lara awọn oṣiṣẹ naa.














