Harzard Allowance: Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera

Harzard Allowance: Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó ààbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera

Oríṣun àwòrán, Ngige

Ìjọba àpapọ̀ ní Nàìjíríà tí fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ètò ìlèra ní àfikún owó ìdá 350% sí 600% gẹ́gẹ́ bí owó àjẹ́mónú ewu lẹ́nu iṣẹ́.

Lọ́bẹ́ àfíkún owó náà, àwọn òṣìṣẹ́ kéékèké yóò má gba ìdá àádọ́ta lé ní ọ̀ọ̀dúrún, nígbà tí àwọn àgbààgbà lẹ́nu iṣẹ́ yóò má gba ìdá ẹgbẹ̀ta gẹ́gẹ́ bí àfikún tíwọn.

Mínísítà fún ètò ìgbanisíṣẹ́ àti ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ Chris Ngige, kéde ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Isegun lẹ́yìn ìpàdé láàrín ìjọba apapọ̀ àti asójú àwọn oṣísẹ́ tó fí mọ́ àwọn ẹgbẹ́ àwọn oṣiṣẹ́ ilera.

Ètò ìpàdé náà tó wáyé gbọ̀gán gbogbonìṣe nínú ilé ìjọba l'Abuja.

Ngige ti tún fẹnu kò pé kí wan sún àsìkò ìfẹ̀yìntì àwọn dókítà, àti àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera mííràn láti ọdún ọgọ́ta ọdún sí ọdún márùnlélọ́gọ́ta àti ọdún àádọ́rín fáwọ́n dókítà àgbà.

Ìpàdé òun dálé ọ̀rọ̀ owó àjẹmónú ewu lẹ́nu iṣẹ́ àti ọjọ́ orí ìfẹ̀yìnti àwọn òṣìṣẹ́ ètò iléra.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Mínísítà sọ pé ìhà tí ìjọba apapọ̀ ní pé mínísítà kékere lórí ètò ìsúna ọmọ ọba Clem Agba tí tako iye owó tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ dókìtà (NMA) àti ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ilera (JOHESU) mú wá.

" Ìjọba pèsè nǹkan tí ó le sé ṣe láti san, pàápàá jùlọ nítorí bí ètò ọ̀rọ̀ ajé ṣe rí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ gbòògì ti ìjọba ń ṣe ló dálé owó yíyá, tí ibi ti ìjọba tí n rówó pàápàá kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe dáada mọ́.

" Nítorí náà wọ́n yóò lọ jábọ̀ fún àwọn ènìyàn wọ́n lórí nǹkan tí ìjọba lágbara láti ṣe."

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Ngige fìdí èyí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan ti ìgbákeji olùdarí ètò ìròyìn Charles Akpan fọ́wọ́ sí.

Bákan náà ni àtẹjáde náà fi kun pé kí àwọn adéhùn wọ́n wọ̀nyìí wà bẹ́ẹ̀ títí tí àwọn asojú ẹgbẹ́ yóò fí lọ jábọ̀ fún àwọn ènìyàn kí wọn si padà fún ọ̀rọ̀ sísọ láàrín ọ̀ṣẹ̀ méjì fún ìdúnadúrà míiràn.

Ngige ni bílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gbọ̀n ní ìjọba àpapọ̀ ná láàrín oṣù mẹ́tà lórí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19.

Harzard Allowance: Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó ààbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera

Oríṣun àwòrán, Health workers

"Sùgbọ́n a ti sún kúrò láti sísan ẹgbẹ̀rún márùn naírà lósù títi di àsìkò tí ọ̀rọ̀ Covikd-19 bẹ́ sílẹ̀ èyí sì mú kí ìjọba náà bílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gbọ́n láàrín oṣù mẹ́ta.

"Ní tẹ̀mi, mo gba pé ìjọba ti ṣe dáadaa fún àwọn òṣìṣẹ́ yìí láti sún iye tí àwọn òṣìsẹ́ ilérà kékèké sí ìdá ààdọ́ta lé lọ́ọ̀dúnrún àti ìdá ẹgbẹta fún àwọn àgbà òṣìṣẹ́.