Christopher Deja: Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja

Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí Christopher Deja

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Ìròyìn sọ pé àwọn agbébọ̀n ti pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá (AIG) tó tún jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ fún gómìnà Samuel Ortom ti ìpínlẹ̀ Benue ló ètò ààbò.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, ọ̀gá ọlọ́pàá náà Christopher Deja ni wọ́n yìn ní ìbọ̀n ní àyà títí tí ó fi gbé ẹ̀mí mì ní ìlú Jos.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Jos fi idí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé, iṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ ajẹ, iṣẹ́jú díẹ̀ sí àsìkò tó wọ̀lú Jos ni wọ́n paá.

Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Plateau Edward Egbuka sàlàyé pé ìwádìí tí wọn ṣe fi han pé, ọgá ọlọ́pàá náà kúrò ni Markudi ni wọ́n lépa wá sí Jos ti wọ́n sì paa.

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ni agbegbe Anguldi ni ìjọba ìbílẹ̀ Jos South Bukuru ni dédé aago mẹjọ ààbò alẹ́ ọkọ́ Ajé.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣàlàyé àwọn ọ̀dànran kan tó níṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn ti mú báyìí tí wọ́n sì wà ni àtìmọ́lé, bákan náà ni ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn tó kù.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí