Sex For Grades: UNILAG gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Boniface Igbeneghu àti Samuel Omoniyi

Oríṣun àwòrán, @jo_alabi
Fasiti ijọba apapọ to wa niluu Eko, UNILAG, ti jawe lọ gbele ẹ fun awọn olukọ meji, Ọjọgbọn Boniface Igbeneghu ati Ọjọgbọn Samuel Omoniyi.
UNILAG gbe igbesẹ naa lẹyin iwadii ti wọn ṣe lẹyin fiimu ti ileeṣẹ iroyin BBC gbe jade, iyẹn sex for grades, eyii to tu aṣiri bi awọn memeji ṣe gbiyanju lati ni ibalopọ pẹlu awọn akẹkọọ lọna ti ko ba ofin mu.
Ninu atẹjade kan ni fasiti ọhun ti kede pe awọn ti da awọn afurasi mejeji naa duro lẹnu iṣẹ.
Atẹjade ọhun ni "Awọn alaṣẹ fasiti yii ti pinnu lati gba iṣẹ lọwọ ọjọgbọn Boniface Igbeneghu to jẹ olukọ ni ẹka imọ ede ilẹ Yuroopu, ati Ọjọgbọn Samuel Omoniyi Oladipo to wa ni ẹka imọ eto ọrọ aje."
"A gbe igbesẹ yii lẹyin ti a ṣe agbeyẹwo iwadii ileeṣẹ iroyin BBC lori ẹsun ibalopọ laarin olukọ si akẹkọọ finifini, nitori naa, ti pinnu lati da awọn afurasi naa duro lẹnu iṣẹ, bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2021."

Oríṣun àwòrán, UNILAG
Gẹgẹ bi UNILAG ṣe sọ ninu atẹjade naa, ipinnu wọn lati da awọn eeyan naa duro lẹnu iṣẹ wa ni ibamu pẹlu abala kejidinlogun iwe ofin to gbe fasiti ọhun kalẹ lọdun 1978.
- Bíi ti UK, USA, Germany, France lẹ ó lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù yín yàlàyòlò ní orílẹ̀èdè Yorùbá Nation - Igboho
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
Lẹyin naa ni wọn rọ awọn adari fasiti ọhun lati ṣe agbeyẹwo ofin to rọ mọ iwa ibalopọ lọna aitọ nile ẹkọ naa.
Ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2019 ni ẹka to n ṣe iwadii ijinlẹ nileeṣẹ BBC gbe fiimu "Sex for grades" jade lati tu aṣiiri awọn olukọ fasiti ni Najiria ati Ghana to n ba awọn akẹkọọ lopọ lọna aitọ ki wọn le fun wọn ni maaki.
Fiimu ọhun fa ori ayelujara ya, o si tun fun ọpọ awọn akẹkọrinrin ni igboya lati sọrọ sita lori awọn ohun ti oju wọn n ri lọwọ awọn olukọ ni fasiti.
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ohun tí wọ́n ní kí òkóbó Buhari bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àbò ni kó bọ̀, dípò dídúnmọ̀huru mọ́ aráàlú- PDP
- Wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí obìnrin tó bá fi ojú rí Orò
- Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ibi kátàkárà fún yín, ẹ̀yin àgbà tẹ ń gbárùkù ti ọ̀dọ́ lẹ́yìn láti máa da ìlú rú ẹ sọ́ra - Ẹgbẹ́ YWG
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin















