Aláàfin: Olorì Damilola ní kí wọ́n má pa òun, bí wọn ṣe pa bàbá òun

Oríṣun àwòrán, Damilola/Instagram
Kàkà kí ewé agbọn dẹ nìdí ọ̀rọ̀ bí ọkàn lára olórí Aláàfin Ọ̀yọ́, Ayaba Damilola ṣe kúrò ní ààfin Oyo, ko ko ko lo n le si.
Ṣe ni iná ọ̀rọ̀ náà tún rú sóde lórí ayélujára lọ́jọ́ Aje nígbà tí àbúrò bàbá olorì Damilola, tii ṣe ẹni tó kú ní bàbá fún, fi fọ́nrán ohùn kan síta.
Ninu fọ́nrán ohùn bàbà náà, tí wọ́n pé ni Master G ( Baba Damola) ló ti n sọ pé, àwọn ni ẹbi Damilola to kúrò ní ààfin láìpẹ́ yìí.
Baba naa ló sàlàyé pé ẹbí Moshood ni òun àti pé gbogbo igbésẹ̀ tí Damilola gbé lori Ayejara irọ́ pátápátá ni.
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- 'Lórí irọ! Kò sí ààtò fún òfin Sharia àti ẹtọ àwa ẹlẹsìn Islam nínúu Oduduwa Republic, a ò gbà'
- Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ibi kátàkárà fún yín, ẹ̀yin àgbà tẹ ń gbárùkù ti ọ̀dọ́ lẹ́yìn láti máa da ìlú rú ẹ sọ́ra - Ẹgbẹ́ YWG
- Àwon ẹlẹ́ja ṣe ìfẹ̀hónúhàn nílùú Akure nítorí ọ̀kan nínú wọn tí ilé wó pa
- Ọdún Oro bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Ikorodu
- Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ni Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni máa gbógun tàwọn ọ̀daràn àti ajínigbé nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí obìnri tó bá fi ojú rí Orò
Ó ni àwọn mọ̀náfìkí èèyàn ló tí ọmọ náà kúrò níbi ògo rẹ̀ tí yóò tí ṣe orííre, àwọn náà sì ni wọ́n tìí kó máá sọ ìsọkúsọ nípa Aláàfín, Ọba Adeyemi keji àti pe bàbá kò le kúrò láàfin, bákan náà sì ni kò fi ìyà jẹẹ́ gẹ́gẹ́ bi Damilola ṣe sọ.
Baba G ọhun tún fikun pé Aláafin lo sọ Damilola di èèyàn, ó sì ń ran ẹbi àwọn lọ́wọ́ ni pẹ̀lú bí ó ṣe fẹ́ẹ, baba lo n ran àbúrò Damilola lọ sí ilé ìwé tí ọ̀pọ̀ àbúrò rẹ mííràn sì wà nínú ààfìn títí dí àsìkò yìí.
Ó tún wá rọ àwọn ènìyàn láti bẹ Aláàfin nítóri kò fi ìyàjẹ́ Damilola, " Titi di àsìkò yìí, Aláàfin ṣì ń fi owó ránṣẹ́ sí Damilola lósòòsù."
Damilola fi epe ránṣẹ́ láti fèsì sí ọ̀rọ̀ Baba G
Olorì Damilola Adeyemi tí wa ké gbèjarè sí gbogbo ẹni tó bá ṣetan láti gba pé kò sí nǹkan tí òun yóò tún padà lọ mú ní ilé ilé Alááfin Oyo nítorí pé ibi tí a bá ti dágbére pé ó dàárọ̀ a kìí tún sọ pé ẹ káalẹ́ níbẹ̀.
Damilola to fọnrere lójú òpó instagramu rẹ̀ láti fèsì sí ọ̀rọ̀ fọ́ran ohùn tí Baba G fisita.
Damilola ní alátẹnujẹ ni ẹni tọ n sọrọ̀ nínú fọ́ran náà, àti pe wọ́n fẹ́ pà òun bi wọn ṣe pa bàbá òun ni.
Damilola nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú òpó Instagram ló tí kéde pé láí, òun kò le padà sí ààfin nítorí òun lóun mọ ibi ti bàtà tí n ta òun lẹ́sẹ̀ nígbà ti òun wà ni àafin Ọba Lamidi Adeyemi.

Oríṣun àwòrán, Damilola/instagram

Oríṣun àwòrán, Damilola/instagram
Olorì Damilola fi kun pé, gbogbo ọ̀rọ̀ ti baba náà tó pè ni Master G sọ kò ni òòtọ́ kan nínú, bí kò ṣe irọ́ pọ́nbélé.
Ó ní owó tí wọn dájọ fún òun lórí ayélujára ní òun fi gba ilé àti sọ́ọ̀bù fún ìyà òun, kìí ṣe Aláàfin lo fi owó ránṣẹ́ sì òun.
Olorì tó ti kúrò láàfin náà fi kun pé, alátẹnujẹ ni bàbá náà, àti pé òun fúra òun ni òun ń san owó ilé ìwé ọmọ òun.

Oríṣun àwòrán, Damilola/Instagram
Damilola ni ti Master G bá ni ẹ̀rí gbogbo nǹkan tí ó sọ yìí pé Kabiesi lo gba ilé fún ìyá òun tàbí òun fí owó ránṣẹ́, kí wọ́n gbé síta.
Epe ńlá sì lo fi ránṣẹ́ sí bàbà náà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun èyí tí a kò lè máa kọ lójú òpó yìí.
Olori Badrat àti Aanu gbé lẹ́yìn olórí Olorì Damilola
Àwọn olorì méjì tí wọn ti sá kúrò ní Ààfin Oyo ṣaaju olórí Damilola, eyiun olorì Badrat Ajoke àti Olorì Aanuoluwapo, naa ti gbe lẹ́yìn ohun tí Olorì Damilola sọ nípa Master G.
Nígbà ti wọn ń fèsì labẹ fọ́nrán ohùn tí ẹni tó pé ara rẹ ní Baba Damilola fisita, àwọn olorì Badrat àti Aanu ni bákan náà ni wọn ṣe lásìkò tí àwọn kúrò ní ààfin Oyo.
Badra ni bàbá òun tilẹ̀ ni wọn lo láti máa bẹ òun láti padà sí ààfin, tí Damilola náà sì ni bo se ri nígbà tòun náà nìyẹn.
Awọn olorì méjèèjì ní ààfin máa ń fún àwọn alatẹnujẹ kan lowo lati maa bẹ àwọn lórí ayélujára pé kí àwọn padà sí ààfin.
Awọn olorì mejeeji náà, tó gbé lẹ́yìn olórí Damilola fún ìgbésẹ̀ akin to gbé láti kúrò ní ààfin, tún ń rọ láti máṣe yí ìpinnu ọkàn rẹ padà, kò tún máa lọ rẹrin nínú iya, tí wọn pè ní 'Suffering and Smiling'

Oríṣun àwòrán, Queenaanu













