Akure Fishsellers protest: Àwon olórí wa ń fi ayé ni wá lára - Ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja ìlú Akure

Àwọn tó n ta ẹja ní ìlú Àkúrẹ́ tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Oǹdó ni wọ́n ṣe ìfẹ̀hónú hàn lónìí nítọrí bí ọ̀kan nínú wọn, ti wọn n pè ni Iya Gbenga ṣe pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí ọwọ́ líle àwọn adarí wọn.
Ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀hún ni wọ́n sọ pé ó ríkú he lákokò tí ilé tó sá sí dàwó lée lórí lẹ́yìn tí àwọn adarí ẹgbẹ́ kò fún un láyè láti ra ọjà torípé kò san ẹgbẹ̀rún kan ti ó kù kí owó ẹgbẹ́ pé.
Àwọn olùfẹ̀hónúhàn naa lábẹ́ àsíá ẹgbẹ olùta ẹja lórílẹ̀ èdè Nigeria, ẹ̀ka ti ìlú Akure, ni wọn bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de wọn láti Ọjà-Ọba títí dé ọọfisi gómìnà l'Akure, ti wọn si n pe àwọn adarí wọn ní agbàlọ́wọ́ọméèri-baálẹ̀-jòntolo.
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin
- Ọ̀gá àgbà NECO papòdà- Kà nípa bí Ọjọ́gbọ́n Obioma ṣe kú
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
- Nǹkan kò burú tó báyìí ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí mo kọrin pé kí Ọlọ́run bá wa tún Nàijíríà ṣe- Funmi Aragbaye
Wọ́n ní àwọn adarí ọ̀hún ló n kó ìnira bá wọn eyii to yọri si iku ọkna lara wọn.
Arábìrin Blessing Johnson ati Foluke Ajayi tí wọ́n sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tó kù sọ pe kí ìjọba tú àwọn adarí náà ká lẹ́yẹ ò sọkà.

Olùrànlọ́wọ́ àgbà fún gómìnà Oluwarotimi Akeredolu lórí ètò àbò, Alhaji Jimoh Dojumo, rọ àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà kí wọ́n ṣe sùúrù àti pé ìjọba yóò túṣu ọ̀rọ̀ ọ̀hún dé ìsàlẹ̀ kòkò.
Gbogbo akitiyan láti bá àwọn adarí ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja naa sọ̀rọ̀ ló já sí pàbó níbí kò ṣe sí ẹni táa ri bá ní gbólóhùn nínú u wọn.

Bakan naa ni a gbiyanju lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ́ Ondo, Ọ̀gbẹ́ni Tee Leo Ikoro náà sọrọ, ṣugbọn ipe ko wọle sori aago rẹ.
- Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ibi kátàkárà fún yín, ẹ̀yin àgbà tẹ ń gbárùkù ti ọ̀dọ́ lẹ́yìn láti máa da ìlú rú ẹ sọ́ra - Ẹgbẹ́ YWG
- Ìdí tí a fi mú àwọn olùfẹ̀hónúhàn pé wọ́n tẹ òfin ètò ààbò lójú.
- Àwọn ọ̀dọ́ lé kábíyèsí jáde láàfin l'Ondo
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè
Ẹ̀wẹ̀, àwọn méjì tí orí kó yọ nínú ilé tó dàwó ọ̀ún sọ pe àdììtú iṣẹ̀ Olódùmarè ni bí àwọn kò ṣe pàdánù ẹ̀mí i wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà, Christiana Olamilekan ṣàlàyé fún ilé iṣẹ́ BBC News Yoruba lóri ibùsùn pé kíákíá tí wọ́n gbe ohun lọ sí ilé ìwòsàn lo dá ẹ̀mí òun sí.














