St Claire's Offa spirit vs students case: Ẹ̀mí àìrí lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ẹ̀kọ́ St Claire's ní Offa

Ẹ̀mí àìrí lé àwọn akọẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ẹ̀kọ́ St Claire's Offa

Oríṣun àwòrán, St Claire's

Àwọn alásẹ́ ilé ẹ̀kọ́ St Claire's Girl Grammer School Offa ti gbé ilé ìwé náà tì ní tóri àwọn ohùn àjòjì tí wan ni wan gbọ́ ní ilé ìwé náà.

Ìròyìn sọ pé àwọn alásẹ ilé ẹ̀kọ́ tún rọ àwọn òbí àti àlágbàtọ́ wọn láti wa mú àwọn ọmọ wọn lọ sílẹ̀.

Ìwádìí fi han pe ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì kan ṣẹ̀ tó si kó ìbẹ̀rùn bójo sí ọ̀kàn àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ní ilé ẹ̀ka náà.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú

Ìṣẹ̀lẹ̀ aburu náà wáye ni ọjọ́ Eti, ọjọ́ kejìdnlọ́gbọ̀n, oṣù karun un, ọdún 2021 lẹ̀yiǹ tí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ni pariwo tí wọ́n sì fẹ̀sùn kan pé àwọn ń gbọ́ òhùn àjòjì látí inú ẹ̀mí.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ìbẹ̀rù bojo mú yìí sá jáde kúrò nínú kílààsì àti yàrà wọn.

Lásìkò tó n fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC Yorùbá, agbẹnusọ àjọ àbò àrà-ẹni ni àbò ìlú (NSCDC) Babawale Afolabi sàlàyè pé, sáájú àsìkò yìí ni wọ́n ti ri ìràn si ilé ìwé náà ti wọ́n si ti gba ilé ẹ̀kọ́ náà nímọ̀ràn láti gba ààwẹ̀ àti àdúrà ọlọ́jọ́ kan.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, àwọn il';e ẹ̀kọ́ náà ṣe bẹ́ẹ̀, tó si fí kún pé, wọ́n ṣe èyí tí wọ́n sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó mu kí ọ̀rọ̀ náà mọ níwọ̀nbá bi ọ ṣe rí.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

O ní bí a sẹ n sọ̀rọ̀ yìí wọ́n ti tí ilé Ẹkọ́ náà pa sùgbọ́n kò sí ẹni tó mọ́ ìgbẹ́sẹ̀ tó kàn tí iléẹ̀kọ́ náà yóò gbé.

Afolabi tún fí kún un pé, ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà fi tó NSCDC létí pé kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ rèé tí ìrú rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà, ó tí wáye ni ọdún 1978 lásìkò tí òun pẹ̀lú jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé náà.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Ọ̀kan nínú àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tó bá àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ Utman Mariam náà tún fi kún pe òun rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ oníruuru ti wọ́n sì ń pè òun láti wá darapọ̀ mọ́ àwọn.

Ìdí sì rèé tí òun fi pariwo ti òun kò sì mọ pé òun pariwo tí òun sì subu láìmọ̀.