Greenfield University: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tí wọ́n jí gbé ní Kaduna ti gba òmìnira

Oríṣun àwòrán, Greefield
Mẹrinla ninu awọn eeyan ti awọn agbebọn ji gbe ni Fasiti Greenfield to wa ni Kaduna ti gba ominira.
Kọmiṣọna eto abo ipinlẹ ọhun, Samuel Aruwan lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.
Aruwan sọ pe akẹkọọ mọkanla ati oṣiṣẹ fasiti mẹta ni wọn gba itusilẹ lọwọ ajinigbe ọhun.
- Ariwo ẹkún sọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí òkú akẹ́kọ̀ọ́ 215 nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yìí
- Bí Ààrẹ Buhari bá parí sáà rẹ̀ tán ni ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria yóò mọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe - Ìjọba àpapọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Ẹnu yóò ya àwọn alátakò lórí ǹkan tí mo ti gbé ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo
Awọn agbebọn naa tu awọn eeyan naa silẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2021 loju ọna marosẹ Abuja si Kaduna.
Meji lara awọn awọn obi awọn ọmọ naa sọ fun awọn akọroyin pe ọgọsan (180) miliọnu naira ati alupupu mẹwaa ni awọn ajinigbe naa gba ki wọn to tu awọn ọmọ wọn silẹ.
Ọkan lara wọn ni "Ọgọsan an miliọnu naira ni awọn ajijigbe naa gba lọwọ awa obi ki wọn to tu awọn ọmọ wa silẹ."
"A ko ri iranlọwọ kankan gba lọdọ ijọba lati tu awọn ọmọ wa silẹ, bẹẹ naa ni a ko ri aṣoju ijọba tabi ọlọpaa kankan lati to lọwọ si itusilẹ wọn."
Bi ẹ ko ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii ni awọn ajijigbe naa ji awọn aẹkọọ ọhun gbe lẹyin ti wọn kọlu ile ẹkọ wọn.
Ni ọjọ kẹtalelogun, awọn eeyan ilu ri oku mẹta ninu awọn akẹkọọ naa labule Kwanan Bature, eyii ti ko jina sile ẹkọ ọhun.
Ọjọ mẹta lẹyin ti wọn ri oku awọn mẹta naa ni awọn agbebọn naa tu pa meji ninu awọn eeyan naa ti wọn ji gbe.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn akẹkọọ naa ti kọkọ gba itusilẹ ṣaaju lẹyin ti awọn obi rẹ san owo itusilẹ fun awọn ajinigbe naa.














