Bobrisky: Ọjọ́ ìbí mi ń bọ̀ lọ́nà, ìdí mi sì gbọdọ̀ dúró re, ní mo ṣe fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ náà

Idris Okuneye Olanrewaju

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/Instagram

Gbajugbaja ọkunrin to maa n mura bia bo, Idris Okunneye, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky ti n kọminu lori isẹ abẹ to fẹ se lati mu ki idi rẹ tobi, ko si duro re nilẹ.

Ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa lọsan ọjọ Ẹti ni Bobrisky ti kede bẹẹ fun araye nipa isẹ abẹ to fẹ ṣe naa amọ o ni aya oun n ja.

Isẹ abẹ naa ti wọn n pe ni Brazilian butt lift, ni wọn ti maa bu ọra kuro ni awọn ẹya ara kan, bii itan, ikun, isalẹ ẹyin ati gegeru.

Awọn ọra yii ni wọn yoo si ko lọ sinu idi lati jẹ ko tobi si, ti irisi rẹ yoo si tun yatọ lai jẹ pe wọn ri ounkohun sinu rẹ.

Ninu fidio naa ni Bobrisky ti n sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe aya n ja, ẹru si n ba oun nipa isẹ naa to ku ọjọ mẹta pere.

Idris Okuneye Olanrewaju

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram

"Ẹru n ba mi pupọ nipa isẹ abẹ to ku dẹdẹ ki n se naa nitori irora ti maa jẹ fun ọsẹ melo kan, irora yii le to bẹẹ gẹẹ, ti ko si se fi ẹnu sọ.

Maa ni irora nibi ọmu ati ni gbogbo ara kaakiri amọ mo ti setan lati tẹsiwaju pẹlu isẹ abẹ naa. Maa se e nitori mo ti san gbogbo owo to yẹ fun isẹ abẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mo gbọdọ se ni, maa wọ inu yara isẹ abẹ lọ, ki n si jade pẹlu ara to rẹwa, ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹjọ ni ọjọ ibi mi, irisi mi gbọdọ le koko ni."

Bobrisky tẹ siwaju pe, lati ọdun diẹ sẹyin ni oun ti n ro lati se isẹ abẹ naa, ti oun si se asaro pupọ lori rẹ, ki oun to pinnu pe oun yoo se isẹ abẹ yii.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

O ni oun ni owo to towo lati sisẹ abẹ naa, amọ ni kete ti wọn ba ti sisẹ abẹ si igegeru oun, ko le pada si bo se wa tẹlẹ mọ laelae.

O ni idi ree ti oun se n ronu lẹẹmeji nipa isẹ abẹ ọhun amọ lọwọ lọwọ bayii, ko si iyemeji mọ, oun ti pinnu lati se isẹ abẹ naa lọjọ mẹrin oni.