Bobrisky: Ìpinu mi fọ́dún 2021 ni lati yí padà si obìnrin patapata

Idris Olarewaju Okunneye, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ si Bobrisky ti fi ọ̀rọ̀ léde fún gbogbo àwọn olólùfẹ̀ nipa isẹ to yan laayo.
Gẹ́gẹ́ bi o ṣe kọ sójú òpó instagram rẹ̀ láìpẹ́ yìí, o ni pé òun ti ni ìpinu tuntun fun ọdún 2021.
Bobrisky sàlàyé sójú òpó rẹ̀ pé, òun ti lo ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àkọ́kọ́ òun gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin sùgbọ́n ti òun kò ri ayọ àti ìdúnu kankan nibẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
- Ajínigbé jí èèyàn méjì gbé l‘Ekiti, Amotekun gba ọ̀kan sílẹ̀
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ibadan, àjọ IBEDC ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwadìí
- Allwell Ademola sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi ń ṣe ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún
- Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó
- Òhun tó yẹ̀ kí o mọ̀ nípa "Bone Straight Hair"
Ó ní òun tálákà ju èkúté sọ́ọ̀sì lọ, òun kò rí ǹkan kan tọ́ka si bó tilẹ̀ jẹ́ pé, òun kẹ́kọ́ọ̀ gboyè ìsírò owó (Accounting) ni fásitì ìpínlẹ̀ Eko síbẹ̀, òun kan n fi ẹsẹ̀ gbálẹ̀ títì kiri ni.
Ọkunrin náà wá kéde pé ni báyìí òun ti ṣetan láti gbé ìgbésẹ̀ tó kan láti di obìnrin pátápáta.
"Kí n tó gbé ìgbésẹ̀ yìí, lọ́jọ́ kan mo ròó pé kíni mo fẹ́ fi ayé mi ṣe? Tí mo ba darapọ̀ mọ́ àwọn adigunjalè, wọ́n a kan pa mi dànu lọ́jọ́ kan ni àti pé mí ò ni ẹ̀mí ká jalè tàbí kí a lu ènìyàn ni jìbìtì.
Lásìkò tí mò n dàgbà, mó ni àwọn àmúyẹ obìnrin lára, ìgbàyìí ni mo pinu láti máa múra bi obìnrin, mo si ri pé, mo bẹ̀rẹ̀ si ni ri owó.
"Èyí ló wá mú mi wọ inú rẹ lọ, mo bẹ̀rẹ̀ si ni lo òògun, mo sì n tójú ara mí, bí gbogbo ǹkan ṣe n gún régé nìyẹn, ti àwọn ọkùnrin ń pè mí, ti mo bẹ̀rẹ̀ dí ni ri iṣẹ́ gba níbi gbogbo"
Fún ìdí èyí, Bobrisky ni òun dára gẹ́gẹ́ bi obìnrin ju okùnrin lọ, òun sì bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn obìnrin.
Ó wa rọ àwọn ènìyàn láti mase da òun lẹ́bi .
Ẹ̀wẹ̀, sáájú nínú síníma kan ti àkọlé rẹ̀ jẹ́ (Skin) ló ti sọ ìtàn ìgbési aye rẹ̀ pé, ǹkan ẹyọ kan ti òun kabamọ̀ ni pé òun bóra.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Bobrisky ni ọ̀rọ̀ ara bíbó kìí ṣe ǹkan tó dẹrun rára, bi ó ṣe n lo ìpara ọwọ́, ni wàá maa lo ti ẹsẹ̀, ó ni ni ọ̀pọ̀ ìgbà ọmọ ènìyàn máa n kánjú.
"Emi gẹ́gẹ́ bi Bobrisky mo kánju ju àsìkò mi lọ ni mo ṣe sáre di ǹkan ti mo dà lónìí, gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ nínú (SKIN)

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

















