2021 Prophecies: Ayodele ní ọwọ́ pálábá Abubakar Shekau yóò ségi lọ́dún tuntun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Primate Babatunde Elijah Ayodele
Oludasilẹ ijọ INRI, Primate Elijah Ayodele ti gbe awọn asọtẹlẹ to le ni igba sita fun ọdun 2021.
Wolii naa, to maa n sọ asọtẹlẹ lọdọọdun nipa awọn isẹlẹ ti yoo waye ninu ọdun tuntun tun salaye pe awọn agbegbọn yoo tubọ kọlu ilu Abuja lọdun 2021.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Ìjọba kéde ọjọ́ tuntun fún ṣíṣí afárá Third Mainland Bridge
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
Bakan naa lo tun ni aawọ to maa n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran yoo tubọ pọ si ninu ọdun 2021 ati siwaju si, jakejado Naijiria.
Ko tan sibẹ, Wolii Ayodele ni laipẹ laijinna ni ọwọ palaba asaaju ikọ Boko Haram, Abubakar Shekau yoo segi, ti ina yoo si dilẹ lẹyin asunsunjẹ rẹ.
Nigba to n sọrọ lori epo rọbi, ojisẹ Ọlọrun naa sọ asọtẹlẹ pe awọn ileepo ifọpo rọbi to jẹ ti ijọba yoo tubọ dojude, ti wọn yoo si di akurẹtẹ amọ ileepo aladani ti Dangote kọ yoo gbinnaya.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Primate Babatunde Elijah Ayodele
Bakan naa ni Ayodele sasọtẹlẹ pe o seese ki aarẹ to wa lori aleefa ati ọkan lara awọn aarẹ to ti jẹ tẹlẹ jade laye, ti omiran yoo si fi asọ penpe roko ọba.
O tẹsiwaju pe awọn gende agbebọn yoo kọlu awọn sọọsi pupọ ninu ọdun 2021, ti wọn yoo si tun maa ji awọn asaaju ijọ gbe lọ pẹlu.
Bakan naa lo ni ọpọ awọn oloselu ni yoo dero ọrun lairotẹlẹ nitori ikọlu oselu lọdun 2021.
"Ikọlu nla yoo waye lati ọdọ awọn Darandaran si awọn agbẹ ni ẹkun ariwa ati ila oorun Naijiria, ti Ọlọrun si fi han mi pe ọpọ awọn darandaran naa ni wsn n lo fun awọn idi kan, ti asiri rẹ ko ni pẹ tu.
Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀

Saaju la ti sọ fun yin pe, oludasilẹ ijọ INRI Evangelial, Wolii Elijah Ayodele ti kede pe, ẹkun ariwa orilẹede Naijiria si ni ipo aarẹ yoo duro si lọdun 2023.
Wolii Ayodele, ẹni to n sọ asọtẹlẹ nipa awọn isẹlẹ ti yoo waye ninu ọdun tuntun 2021 wa sekilọ fun gbogbo awọn eeyan to n foju sọna pe ipo aarẹ yoo wa si guusu Naijiria lati gbagbe ero naa.
Ojisẹ Ọlọrun naa ni oludije fun ipo aarẹ mii lati ẹkun ariwa Naijiria ni Buhari yoo fa akoso Naijiria le lọwọ lẹyin ibo gbogbo gboo ọdun 2023.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bàyíì ni mo ṣe kílọ̀ fún Donald Trump, àmọ́ kò gbọ́rọ̀ - Primate Ayodele
- Ajínigbé jí èèyàn méjì gbé l‘Ekiti, Amotekun gba ọ̀kan sílẹ̀
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ibadan, àjọ IBEDC ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwadìí
- Allwell Ademola sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi ń ṣe ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún
- Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó
- Òhun tó yẹ̀ kí o mọ̀ nípa "Bone Straight Hair"
"Ẹkun ariwa Naijiria ko ni fi oju rere wo ẹya miran to ba fẹ gba akoso lọwọ ijọba Buhari, nitori naa, ẹlomiran lati apa oke ọya ni Buhari yoo fa akoso orilẹede yii le lọwọ."
Wolii Ayodele fikun pe igbesẹ naa le fa rogbodiyan lọdun 2023, eyi ti yoo buru pupọ ju awọn iriri laasigbo ti Naijiria ti foju wina rẹ sẹyin lọ.
O wa sekilọ pe o seese ko jẹ pe ibo ọdun 2023 naa ni yoo fopin si orilẹede ti wọn n pe ni Naijiria , eyiun tawọn alasẹ ba fi kuna lati se atunto orilẹede yii.
"Yoo dara ki Naijiria se amulo ijọba apapọ tootọ tabi ko pin si yẹlẹyẹlẹ niotir ọrọ lee bẹyin yọ lẹyin ibo ọdun 2023.":
Bakan naa ni wolii naa wa n rọ asaaju ẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu lati jami lori afojusun rẹ lati dije fun aarẹ orilẹede yii.
Wolii Ayodele ni gbogbo erongba Tinubu, Bukola Saraki, Aminu Tambuwal, Kayode Fayemi ati Amaechi lati dije fun ipo aarẹ Naijiria ni yoo ja si pabo ni 2023.
O fikun pe agbara kan wa ti ko ni jẹ ki erongba Tinubu lati di aarẹ Naijiria jọ bi o tilẹ jẹ pe oke tente lo wa, wọn yoo kan erongba rẹ labuku, ti yoo si ja wa silẹ.
Ojisẹ Ọlọrun naa tun rọ Tinubu lẹẹkan si lati gbagbe erongba rẹ naa, ko ma si sopo daba lati dije fun ipo aarẹ rara nitori ala ti ko le sẹ lo rawọ le.
Ajínigbé jí èèyàn méjì gbé l'Ekiti, Amotekun gba ọ̀kan sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Awọn gende agbegbọn ti wọn furasi bii darandaran ti ji eeyan meji gbe loju ọna Isan-Iludun nipinlẹ Ekiti lọjọ ọdun keresimesi.
Deede aago mẹfa irọlẹ ni awọn agbegbọn naa da ibọn bo ọkọ ayọkẹlẹ Lexus ti wọn wa ninu rẹ nigba ti wọn de ibi ti oju ọna ko ti dara.
Amọ Ọba Oke ko ọkan lara wọn yọ nigba ti awọn ọmọ ikọ Amotekun tete gba ọkan silẹ ninu wọn amọ ti awọn ajinigbe naa wọ ekeji wọ inu igbo ni tipatipa.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ Abamẹta nipa isẹlẹ naa, oludari ikọ Amotekun nipinlẹ Ekiti, Ajagunfẹyinti Joe Komolafẹ ni pẹlu ibọn ni awọn agbegbọn fi da ọkọ awọn eeyan naa duro.
Komolafẹ wa rọ awọn araalu lati mase foya nitori ikọ rẹ atawọn agbofinro n sisẹ papọ lati pese aabo to peye lasiko ọdun, ti wọn yoo si tun doola ẹmi ẹni ti wọn jigbe naa.

















