Ilorin Killing: Ọmọ kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ dèrò ọrun torí ááwọ̀ báńgà ní Mọ́ṣáláṣí

Abdulkadir ati Kehinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nurudeen Musa

Awọn ara adugbo Ita Nmo nilu Ilorin ti ke gbajare s'awọn agbofinro lati ṣawari arakunrin kan to gun eeyan lọbẹ pa nitori Banga.

Ohun tá gbọ ni pe arakunrin to ko agbako iku ojiji naa, Abdulkadir Segi sọ fún ọkunrin kan, Kehinde Oloka pe ko ma yin banga sinu mọsalasi lasiko ti won n kirun janmọ.

Kaka ki Kehinde gbọ arọwa yii, se ni wọn lo sare lọ sí ilé, tó sì lọ mu ọbẹ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ka to wí ka to fọ, o ti gun Abdulkadir lọbẹ, nigba ti won yoo si fi gbé Abdulkadir dé ilé iwosan, ẹpa ko boro mọ, ẹlẹmi ti gba a.

Awọn ara adugbo to ba ileesẹ iroyin Punch sọrọ lori isẹlẹ yii sọ pe, Kehinde na papa bora ni kete to huwa laabi rẹ naa tan, t'awọn eeyan agbo-ile rẹ, tó fi mọ awọn obi rẹ naa si sálọ.

Ẹnikan mu ọbẹ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abdulkadir nikan lawọn obi rẹ bi gẹgẹ bí a ti ṣe gbọ, ti wọn ti sin ni ilana musulumi.

Ọrọ yii ti de etigbọ awọn ọlọpaa to wa ni Adewole, ti a si gbọ pe alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Kehinde Okasanmi náà tí fidi ọrọ yii mu'lẹ.

Awọn ọlọpaa lawọn ti bẹrẹ iwadii lati wa afurasi yii kan nibi kibi to ba sa pamọ si.

Ṣé lóòtọ́ ni èèyàn kan kú níbi wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ l'Osogbo lọ́jọ́ ọdún Kérésìmesì?

igboro agbegbe Sabo ni ilu Osogbo lasiko wahala naa

Oríṣun àwòrán, Toba adedeji

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, wahala bẹ silẹ lagbegbe Sabo nilu Osogbo nibi tawọn janduku ti ṣọṣẹ lalẹ Ọjọbọ, tii ṣe aisun ọdun Keresimesi ati owurọ ọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ ọdun Keresimesi gangan.

Amọṣa ohun to n ṣe awọn eeyan ni haa-hin bayii ni pe boya lootọ lẹmi ba iṣẹlẹ naa lọ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn iroyin abẹle n fidi rẹ mulẹ pe eeyan kan ku ninu iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko tii lee sọ boya ẹmi ba iṣẹlẹ naa rin nitori pe iwadi ṣi n lọ lọwọ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?

Awọn eeyan n da rogbodiyan kan silẹ

Oríṣun àwòrán, Quartz

Awọn afunrasi janduku ya bo agbegbe Sabo ni ilu Osogbo lọjọ keresimesi ti wsn si da ibọn bolẹ nibẹ ti wọn si ṣe ọpọlọpọ awọn oniṣowo to n ba karakata wọn lọ nibẹ leṣe.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn eeyan agbegbe naa sọ, awọn janduku naa ya wọ agbegbe ọhun ni aṣalẹ Ọjọbọ tii ṣe ọjọ aisun ọdun Keresimesi pẹlu awawi pe awọn fẹ ṣe eto isin idagbere "candle night" fun ọkan lara wọn to jade laye.

Amọṣa, kaka ki wọn fi mọ lori ohun ti wọn ni awọn wa ṣe, wahala ni wọn ni wọn fi da silẹ ti wọn si bẹrẹ si ni koju ija sawọn olugbe agbegbe naa atawọn ontaja to wa nibẹ.

Aarọ ọjọ Ẹti, iyẹn ọjọ ọdun Keresimesi gan an lawọn janduku naa tun pada wa si agbegbe naa.

Gẹgẹ bi awọn to wa nibẹ ṣe sọ, wọn yinbọn fun oniṣowo kan nibẹ ti awọn miran si tun farapa

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Amọṣa ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye fun BBC News Yoruba pe awọn ti da alaafia pada si agbagbe naa ati pe nibayii awọn ko tii lee sọ ni pato ohun gan to bẹrẹ wahala naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, arabinrin Yẹmisi Ọpalọla ṣalaye pe iwadii ti n lọ lọwọ ati pe oun ko tii le sọ boya ẹmi kankan ba iṣẹlẹ naa lọ

Bi awọn iroyin abẹle ṣe n sọ, nnkan ṣi le diẹ lagbegbe naa bayii ati pe awsn Hausa to jẹ olugbe agbe naa pẹlu ti di ihamọra okuta, ọbẹ, ada ati ọkọ lati daabo bo ara wọn bi awsn janduku naa ba tun yọju.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'