Tunde Bakare: Àwọn èèyàn kò gbọ́ ìwàáṣù mi délẹ̀, kí wọn tó bú mi lórí ọ̀rọ̀ Tinubu

Oríṣun àwòrán, @T_Bakare/@AsiwajuTinubu
Olusọagutan Tunde Bakare, ti i se asaaju ijọ Citadel Global, ti yọ suti ete sawọn eeyan to n foju laifi wo oriyin to gbe fun ipa ti Bola Tinubu ko si idagbasoke orilẹede yii.
Bẹẹ ba gbagbe, fidio kan lo lu sori ayelujara laipẹ yii, ninu eyi ti Bakare ti yonbo asaaju ẹgbẹ APC naa ninu iwaasu to se lori pẹpẹ ijọ rẹ.
Gbajugbaja oniwaasu naa si lo fi Tinubu we Jephtar ninu bibeli, pẹlu afikun pe gbajumọ oloselu naa ti ja ọpọ ogun fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Ìjọba kéde ọjọ́ tuntun fún ṣíṣí afárá Third Mainland Bridge
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
Bakan naa lo ni o ti gba ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ yoku nilẹ Yoruba silẹ lọwọ ifiyajẹni ẹgbẹ oselu PDP laarin ọdun 1999 si 2007.
Iwaasu yii lo mu awuyewuye dani, ti ọpọ si n kọminu pe ki lo de ti Tunde Bakare ti ti laali Tinubu tẹlẹ, se wa yipada maa kọrin re ki i.

Oríṣun àwòrán, @T_Bakare
Nigba to n fun awọn alariwisi rẹ lesi ọrọ wọn, Bakare wa se apejuwe awọn eeyan to n bu ẹnu atẹ lu naa gẹẹ bii 'Agbokujo'.
O ni kii se pe oun gba owo lọwọ Tinubu, ki oun to kọrin rere kii, bẹẹ ni ko si ẹni to lowo lọwọ to bẹẹ lati sanwo isẹ fun oun.
O tun kesi awọn eeyan to n yọ suti ete si pe o ti gba owo ẹyin, lati fi ẹri to daju lelẹ, ti wọn ba ni lọwọ.
Ninu iwaasu miran to se lọjọ Aiku ana, eyi ti Bakare pe akori rẹ ni 'Ko si ẹni to mọ bii Ọlọrun', wa n beere pe ki lo de tawọn eeyan fi n tako oun lai gbọ ẹkunrẹrẹ iwaasu naa delẹ tan.

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu
Bakare ni ọwọ Ọlọrun ni idajọ wa, ko si yẹ ki awọn eeyan maa fi iwanwara se idajọ ọmọnikeji nitori iwa ti wọn ti hu sẹyin.
O fikun pe lootọ ni oun yonbo Tinubu nipa awọn aseyọri to se nidi oselu amọ eyi ko tumọ pe oun fara mọ igbe aye rẹ
Ojisẹ Ọlọrun naa ni nigba ti ọpọ eniyan n sun, Tinubu n sisẹ kara lati fi awọn eeyan rẹ sibi to lagbara.
O ni yoo nira fun ẹnikẹni lati bori oludije ti Tinubu ba ti lẹyin nipinlẹ Eko nitori akoko ko tii to fun wọn.
Bí kìí bá ṣe Buhari ni ààrẹ ni, ológun ì bá ti dìtẹ̀ gba ìjọba - Kukah

Oríṣun àwòrán, Sokoto catholic Diocese
Wayi o, Bisọọbu ijọ aguda ti Sokoto Ẹniọwọ, Matthew Kukah ni aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ọjọ iwaju Naijiria rubọ nitori ifẹ ati ipinu rẹ lati mu ki iha Arewa Naijiria maa jẹgaba lori ẹya to ku.
Kukah sọ eyi ninu atẹjade iwe ikini rẹ fun ọdun keresimesi to pe akọle rẹ ni A Nation in Search of Vindication.' O ni Naijiria wa ninu okunkun birimu labẹ akoso aarẹ Buhari, ati pe o ṣe pataki ki aarẹ ṣalaye nkan to wa ni idi itajésilẹ ojoojumọ nitori eto abo to mẹhẹ.
O ṣapejuwe orilede Naijiria bi eyi ti ara ilu rẹ n rinrin ajo ọkọ oju omi ṣugbọn ti ko si awakọ, iwe irina ati ebute ibi ti yoo ti sọkalẹ.
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Odunlade Adekọla, Lateef Adedimeji, , Mercy Aigbe àtàwọn òṣèré míì tó fi àsìkò Kérésì ya àwọn olólùfẹ́ wọn lẹ́nu
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Àwọn Tíṣà Oyo kó owó tó wà fún àkóso iléèwé jẹ, ni wọ́n fi ń fọwọ́ kọ ìdánwò pẹ̀lú ṣọ́ọ̀kì - Seyi Makinde
Kukah ni " Aarẹ Buhari nilo lati ṣalaye fun ọmọ Naijiria ibi ti o ń dari ọkọ wọn lọ gan nitori pe o jọ pe inu okunkun birimu ni. "Itajẹ silẹ ojoojumọ ti pọju o si kọja afẹnusọ, ṣe bi awọn oniṣẹ ibi yii yoo ṣe di ara ilu lọwọ ati ẹsẹ ree abi o ti di nkan ti a o maa ba gbe titi lai?"
"Aarẹ Buhari mọọmọ fi iran awọn ọmọ orilede yii to dibo fun rubọ ni, ó jọ bi ẹni pe, o ni ileri kan to gbọdọ muṣẹ fun awọn Arewa nitori naa o gbọdọ sọ ẹya toku di "boo ba o pa a" boo ba o bu u lẹsẹ. Imọ tara ẹni nikan ni aarẹ ni ṣe lai fi ti ara ilu ṣe."

Oríṣun àwòrán, Kukah
" Gbogbo ọmọ Naijiria ti ko ba ni parọ tan ara rẹ mọ pe ẹnikéni ti kii ṣe musulumi lati iha Arewa ko dan ida kan nkan ti aarẹ Muhammadu n dáwo lọọwọlọwọ bayii ti yoo si mujẹ bẹẹ. Awọn ọmọ ologun yoo ti ditẹ gba ijọba tipẹ tabi ki orilede yii ti béré ogun".
O ni nitori iwa aibikita aarẹ ajalu lori arelu ni aburu to n de ba Naijiria, orilede yii ti wa ninu wahala ati isoro to n ranju mọ ara ilu kọọkan.

Oríṣun àwòrán, Kukah
Ọpọ ala ati iran ara ilu lo si ti sọnu pẹlu, wọ́n ti ji ọrọ gbogbo ilu gbe, ti iwa ajẹbanu si ti ni éka loriṣiriṣi, awọn mitan ti gba émi ara wọn pẹlu.
Ẹwẹ, o rọ gbogbo ara ilu lati ma sọ ireti nu loju gbogbo isoro yii, inira, ibanuje ati ainireti to kun orilede Naijiria

















