Christmans celebrations: Alaafin Oyo gba àdúrà ọdún fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, pẹ̀lú ìmọ̀ràn lórí ààrùn COVID-19

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, facebook/Alaafin Oba Adeyemi III

Bi awọn eekan gbogbo ṣe n dawọ idunu pẹlu oniruuru ara ati ọrọ lọjọ Keresimesi, kabiyesi Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Ọlayiwọla kẹta pẹlu ti sọrọ.

Koko ohun mẹta si ni Baba sọ nipa Keresimesi lọdun yii.

Akọkọ, ninu atẹjade to fi sita laafin rẹ lọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ ọdun keresimesi lagbaye, "lorukọ awọn olori, atawọn ọmọọba laafin", Kabiyesi Alaafin rọ awọn ọmọ Naijiria, paapaajulọ awọn Kristẹni lati maa tẹlẹ ẹkọ to kalẹ sawọn iwe mimọ gbogbo ninu idawọle wọn lojojumọ.

O ni o ṣe pataki lati "tẹsiwaju pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun" lati mọ pe a o bori ajakalẹ aarun to n da aye laamu bayii.

Ẹkeji, Alaafin gba adura fun mutumuwa pe "ìkoko ọbẹ" wọn o ni gbẹ, bẹẹni aka wọn ko ni ṣofo ati pe awọn ọmọ ilẹyii yoo ṣe rere ninu alaafia tii ṣe baalẹ ọrọ.

Ẹlẹkẹẹta ti iku Baba Yeye mẹnuba ni fun awọn ọmọ Naijiria lati maṣe gbagbe pe ajakalẹ aarun COVID-19 ṣi wa ni sakani wa.

Nitorinaa ki koowa o tẹle awọn ilana gbogbo to wa fun didena itankalẹ aarun naa.