Nollywood actors death 2020: Wo àwọn gbajúgbajà òṣèré fíìmù Yoruba àti olórin tí kò rí ọdún tuntun 2021

Oríṣun àwòrán, ...
- Author, Yetunde Olugbenga
- Role, Senior Broadcast Journalist
Ohun toju ri lọdun 2020 to n kogba wọle lọ yii ti kuro ni keremi koda ti wọn ba n bi gbogbo eeyan lagbaye nipa iriri, ko si ẹni ti ori rẹ dọta ti ko ni lee sọ nkankan.
Ẹwẹ, isọri isọri ni awọn nkan to ṣẹlẹ, bi ko ṣe rọgbọ fawọn kan lo n dun yafunyafun fawọn mii.
Bi ọdun 2020 ṣe san awọn mii si owo, ọmọ ati aiku baalẹ ọrọ, bẹẹ lo gba owo iṣẹ, ọna atijẹ koda o tun gba awọn ẹbi awọn mii.
- Ṣé òótọ́ ni àwọn ará Amẹ́ríkà máa ń hán an lọ́wọ́ kan tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó ti kú àmọ́ tí iṣẹ́ wọn ń fọhùn síbẹ̀
- Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó
- Nínú kó o fi omi fọ ìdi tàbí lo tííṣù fi fá a, Èwo ló rọrùn?
Lara awọn to ṣọfọ ti wọn kẹdun awọn eeyan wọn to dagbere faye ni idile awọn oṣere ati olorin Yoruba kan to fi mọ agbo oṣere Tiata lapapọ.
Oṣere àti olórin mọkànlá tí ko rékọjá sí ọdún 2021
Pa Kasumu (Kayode Odumosu)

Oríṣun àwòrán, Twitter
O ti to ọjọ diẹ ti iroyin pe aisan n ba gbajugbaja agba oṣere, Kayode Odumosu ti ọpọ mọ si Pa Kasunmu finra ti wa lode.
Koda ko si afibo nibẹ tori oun funrarẹ sọrọ jade pe adura kikan kikan loun nilo latọdọ awọn eeyan kii ṣe owo amọ ti awọn akẹgbẹ rẹ to fi mọ awọn ọdọ ninu awọn oṣere gan dide iranwọ fun un.
Foluke Daramola to jẹ ọkan lara awọn ọdọ ipele eyi to pọwọle awọn agbaagba ni "eyan daada ni wọn yatọ si pe wọn jẹ oṣere tiata.Iku wọn jẹ eleyi to fi ọwọ kan wa lẹmi''.
Awọn dokita ni o ni aisan rọpa rọsẹ, amọ iroyin sọ pe ailera rẹ tun buru sii lẹyin to pada de lati orilẹede India to ti lọ fun itọju.
Ni ile iwosan aladani kan ni agbegbe Lantoro, Abeokuta ni ipinlẹ Ogun ni oloogbe yii dakẹ si.
Osuntoun (Musiliat Arikeusola)

Oríṣun àwòrán, OTHER
Ko si ẹni to ba n wo awọn ere ibilẹ Yoruba to kun fun aṣa, iṣe ati igbagbọ ẹya Yoruba ti ko ni mọ mama, Ọṣuntoun paapaa julọ nitori awọn ipa awọn "ẹlẹmi agba" to ko ninu awọn ere oloogbe Yẹkini Ajilẹyẹ.
Lara awọn ere ti oloogbe Osuntoun ti kopa ni Koto Orun, Aye Akamara, Koto Aye, ti gbogbo rẹ jẹ latọwọ oloogbe Ajilẹyẹ.
Oloogbe Ọṣuntoun funrarẹ naa gbe awọn ere kan jade bii 'Omi Ipin,' 'Imi Esin' ati 'Ogun Omo Iya le', to jẹ ere ti o ṣe gbẹyin, gẹgẹ bi ọgbẹni Adedokun ṣe sọ.
Ile rẹ lagbegbe Ijẹtu nilu Osogbo ni Mama dakẹ si.
Toromagbe nínú fíìmù ''Arelu''

Oríṣun àwòrán, Facebook
Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi lo kọpa ninu ere agbelewo ti wọn ṣe ni ọdun 1986, ti wọn si pe akọle rẹ ni ''Arelu''.
Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ni o kopa gẹgẹ bi ''Toromagbe'' ninu fiimu naa, to si jẹ ọkọ fun ''Ọwọ otori'' ti wọn gbe ninu aginju ninu fiimu kan naa.
Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi pe ara rẹ ni araye-rọrun nitori iji gbe e lọ fun ọjọ mẹrinla lasiko ti wọn n ṣe fiimu ''Arelu'', ti o ni oun si le sọ nipa igbeaye eniyan nipa wiwo ọwọ rẹ.
Ogun Majek

Oríṣun àwòrán, Others
Ilumọọka ni osere tiata Gbolagade Akinpelu, ti ọpọ eeyan mọ si Ogun Majek.
Ọrẹ timọtimọ ni Ogun Majek ati Musiliu Dasofunjo ti wọn tun jọ jẹ oṣere tiata, ti ọpọ eeyan mọ si Esu laalu.
Dasofunjo ni wọn gbe Majek digbadigba lọ si ileewosan UCH ni Ibadan, nigba ti aisan rẹ fẹ bọwọ sori amọ ẹpa ko boro mọ.
O fikun wi pe, kii se pe agba lo de si ọrẹ oun nitori ọjọ ori rẹ ko tii to nnkan, amọ asiko ti to, ni Majek fi di ero ọrun.
Aisan kidinrin ati aisan itọ suga ni Majek ti n ba finra fun ọpọlọpọ ọdun ko to jade laye.
Majek Fashek

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja olorin Raggae ni Majekodunmi Fasheke, ọmọ Yoruba si ni amọ ti wan mọ ọ gẹgẹ bii gbajumọ lagbaye.
Orilede Amẹrika ni eto isinku rẹ ti waye nibi tawọn mọlẹbi rẹ nikan ti kopa nibẹ. Alamojuto ẹgbẹ akọrin rẹ Uzoma Omenka sọ eyi pe ki awọn eeyan ma binu toripe Covid-19 ko jẹ kawọn le wa sin in si Naijiria.
Prisoner of conscience, Send down the rain, Little little patience, One Love, No woman no Life ati ọpọlọpọ ni awan orin to kọ nigba aye rẹ.
Ni ọjọ Aje, ọjọ kini, oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni Majek Fashek jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.
Ọjọgbọn Ayo Akinwale

Oríṣun àwòrán, Etsu Muazu Idris/Facebook
Wọn bi gbajugbaja oṣere fiimu ati olukọni ere ori itage, Ọjọgbọn Ayo Akinwale ni ilu Ibadan, ọmọ bibi ilu Ibadan si ni pẹlu.
"Ẹni ti Ọlọrun da ti ko ṣee fara we ni Ọjọgbọn Ayo Akinwale. O mu gbogbo akẹkọọ bi ọmọ rẹ, oloju aanu si ni". Oludari ẹka imọ ẹkọ ere idaraya ni fasiti Ilorin, Abdulrasheed Adeoye sọ fun BBC Yoruba.
Gbogbo oye to yẹ keeyan gba ninu imọ iṣẹ Tiata lo gba nigba aye rẹ- oye Diploma, Degree, Masters, PhD ni ẹka Tiata fasiti ilu Ibadan.
Agbaọjẹ ni ti awan agbaagba orilẹede Naijiria gan mọ to bẹẹ ti aarẹ Buhari daro rẹ nigba to ku.
Lara awọn ere to ti kopa ni Afonja, Sango, Ladepo Omo Adanwo, Iranse Aje, Agbara Obinrin.
Ayo Akinwale jade laye lọjọ kẹtala oṣu kẹsan ọdun 2020 ni ile iwosan fasiti Ilorin.
Jimoh Aliyu

Oríṣun àwòrán, NTA ado-ekiti/city people magazine
Jimoh Aliu ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa lati mu iyatọ ba iṣẹ tiata lori mohunworan koda o tun ti jẹ ọmọ ologun ri nigba aye rẹ.
Ko to ku, Aliu n ṣiṣẹ lori fiimu maarun, ti ireti wa pe awọn agbaagba oṣere Nollywood yoo kopa ninu rẹ. Ṣugbọn, iku mu u lọ lasiko to n ya ọkan ninu rẹ to pe akọle rẹ ni "Olowo Ite".
Oun ati gbajugbaja oṣerebinrin, Folake Aremu 'Oriṣabunmi', ti fi igba kan jẹ tọkọ-taya, kii wọn o to tuka lẹyin ogun ọdun.
Yatọ si Oriṣabunmi, O ni iyawo meji miran - Queen Bola ati Folashade.
Jimoh Aliyu ti ọpọ mọ si Aworo jade laye lẹni ọgọrin ọdun ni ọjọ kọkandilogun oṣu kẹsan ọdun 2020.
Gbenga Ajumoko

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gbajugbaja ni Gbenga Ajumoko naa laarin awọn agba oṣere fiimu Yoruba.
Oṣere ati onkọwe ni. Iroyin jade nigba kan pe o dubulẹ aisan nileewosan kan fun nkan bii oṣu mẹfa ni Sagamu Remo.
Iroyin ni o kọkọ n da ara rẹ tọju ni ki aisan naa to burẹkẹ sii ti wọn wa gbe e lọ si ile iwosan aladani kan ni ilu Ibadan nibi to dakẹ si.
Diẹ lara awọn iṣẹ ere to ti kopa ko to ku ni Enikeji (2017), Agbere (2017), Yeye Efun, Wound (2019), Ako Okuta (2018).
Alhaji Yekeen Omobolanle (Baba Lẹgba)

Oríṣun àwòrán, Others
Wọn ṣàpèjúwe Baba Lẹgba gẹgẹ bi baba awọn oṣere nigba aye rẹ to ko awọn eniyan mora.
Ẹni to jẹ adari ẹgbẹ awọn oṣere Yoruba ni ipinlẹ Ogun, Owolabi Ajasa ni "bi o tilẹ jẹ pe oloogbe naa kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣere TAMPAN nigba aye rẹ, to jẹ wi pe ọmọ ẹgbẹ ANTP ni, sibẹ o sunmọ gbogbo awọn oṣere".
Aisan to rọmọ ọjọ ogbo lo ṣe Baba legba to fi papoda, amọ, ede aiyede to ṣẹlẹ laarin ẹgbẹ TAMPAN ati ANTP, lo mu ki ọpọ ma ri i mọ pupọ lori itage.
Baba Lẹgba lo maa n sere awada pẹlu baba Sala laye ọjọsi, ki agba to de.
Agba ọjẹ osere tiata naa jade laye nile rẹ to wa nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.
Toyosi Arigbabuwo

Oríṣun àwòrán, Toyọsi Arigbabuwo
Ọkan lara awọn ọrẹ timọtimọ Toyọsi Arigbabuwo ti wọn jọ n sisẹ tiata, Alhaji Musiliu Dasọfunjo salaye pe Arigbabuwo jẹ akikanju eeyan pupọ pupọ.
Isẹ aransọ ni Toyọsi kọkọ kọ nigba aye rẹ ko to ya si idi isẹ tiata, to si n fi ẹsa ẹkun iyawo kewi, eyi ti awọn eeyan mọ si, ko to wa da ẹgbẹ tiata tiẹ silẹ taa mọ Toyọsi Arigbabuwo Theather Group.
Lẹyin eyi, o bẹrẹ si ni se ere fun ileesẹ mohunmaworan ijọba apapọ lasiko to wa ni WNTV ko to wa di NTA bayii.
Inu oṣu kini nibẹrẹ ọdun 2020 ni o dagbere faye.
Laditi (Femi Oyewunmi)

Oríṣun àwòrán, Facebook/Prince Kehinde Oyewunmi
Ọmọba Oyewunmi ni a gbọ pe o ti n ṣaisan fun ọjọ pipẹ, koda ọrẹ rẹ,Ọgbẹni Sayo Alagbe fidi rẹ mulẹ pe o ṣiṣẹ abẹ lori ẹyin rẹ.
Oloogbe Oyewunmi kopa ninu awọn ere tiata bii Aye Toto, Koto Ọrun, Ija Eleye atawọn ere tiata.
O jade jaye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta lọjọ kejilelogun oṣu karun un ọdun 2020.




























