Majek Fashek: Mọlẹbí nìkan ló péjú síbi ìsìnkú gbajúgbajà olórin reggae náà ní Amẹ́ríkà

Majek Fashek

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Majek Fashek gbajugbaja olorin reggae ọmọ Naijiria ti wọ kaa ilẹ lọ.

Alamojuto ẹgbẹ akọrin rẹ Uzoma Omenka ni eto isinku rẹ waye lorileede Amẹrika nibi tawọn mọlẹbi nikan ti kopa nibẹ.

Uzoma ni ki awọn ọmọ Naijiria paapa julọ awọn ololufẹ rẹ ma ṣe binu nitori pe Covid-19 lo ṣokunfa bi wọn ko ti ṣe le sin ni Naijiria.

Loju opo Instagram rẹ, o fi aworan kan sibẹ ni iranti Majek Fashek

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Bi a ko ba gbagbe ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa Randy Fashek ti ṣaaju kede pe isinku ranpẹ lawọn yoo ṣe nitori Covid-19.

Uzoma wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to gbaruku ti mọlẹbi ti o si ni nigba ti gbogbo nkan yoo ba fi lọlẹ awọn yoo ṣeto iranti isinku rẹ lọdun to n bọ

Majek Fashek

Oríṣun àwòrán, Instagram/official_Majek Fashek

Ìdí rèé tí a ṣe fẹ́ sin Majek Fashek sílẹ̀ Amerika- Randy Fashek

Idile gbajugbaja akọrin Raggae ni, Majek Fashek to ti di oloogbe bayii ti sọ pe orilẹede Amerika ni yoo ti wọ kaa ilẹ lọ.

Ni ọjọ Aje, ọjọ kini, oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni Majek Fashek jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.

Gẹgẹ bii alakoso iṣẹ rẹ ṣe sọ, Majek Fashek fọwọ rọri ku ni ni ilu New York lorilẹ-ede Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Agbẹnusọ fun ẹbi oloogbe to tun jẹ ọmọkunrin rẹ, Randy Fashek lo kede pe ilẹ Amẹrika ni awọn yoo sin Fashek si.

Ninu fidio kan lori ayelujara ni Randy ti ṣalaye ọrọ yii.

Skip YouTube post
Allow Google YouTube content?

This article contains content provided by Google YouTube. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Google YouTube cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of YouTube post

O ṣalaye pe ẹbi Majek Fashek wo awọn nnkan to rọ mọ eto aabo lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ lati sin in silu oyinbo.

Randy tun fikun ọrọ rẹ pe ajakalẹ aarun coronavirus naa jẹ ọkan gboogi lara idi ti ẹbi fi pinnu lati sin ogbontarigi olorin to lọ si ilẹ Amerika.

O sọ pe o nira fawọn ẹbi Majek Fashek lati ṣe ipinnu yii, ṣugbọn awọn bi lati ṣe bẹẹ nitori ohun ti o n ṣẹlẹ lọwọ lagbaaye bayii.

Ọmọkunrin Majek Fashek tun fidi rẹ mulẹ pe idile Majek Fashek nikan ni yoo ṣe eto isinku fun un.

Majek Fashek

Oríṣun àwòrán, Instagram/official_MajekFashek

Bakan naa lo sọ pe awọn ẹbi ko tii mu ọjọ isinku fun Majek.

Randy tọrọ garafara lọwọ awọn ololufẹ Majek Fashek ti wọn fẹ ki gbajugbaja olorin to lọ wọ kaa ilẹ lọ niluu abinibi rẹ ni Naijiria.

O ṣalaye pe awọn ẹbi yoo maa kede ọjọ ti eto isinku naa yoo waye laipẹ.

Ohun mẹ́fà tí àgbáyé kò mọ̀ nípa Majek Fashek tó d'olóògbé nìyí

Ni ọjọ Aje, ọjọ kini, oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni gbajugbaja akọrin Raggae ni, Majek Fashek jade laye lẹyin to lo ọdun mẹtadinlọgọta lorilẹ-ede aye.

Gẹgẹ bii alakoso iṣẹ rẹ ṣe sọ, Majek Fashek fọwọ rọri ku ni ni ilu New York lorilẹ-ede Amẹrika.

Lootọ gbajugbaja ni Majek Fashek kaakiri agbaye ṣugbọn awọn ohun mẹfa wọnyii ni awọn eeyan ko mọ nipa rẹ.

Ohun mẹfa ti ọpọlọpọ eniyan ko mọ nipa Majek Fashek

  • Majẹkodunmi Fasheke to tumọ si pe ifa kii ṣe eke, ni orukọ abisọ oloogbe onkọrin, Majek Fashek.
  • Lati kekere ni awọn obi rẹ ti kọ ara wọn silẹ gẹgẹ bii lọkọ-laya, ṣugbọn Fashek ko kuro ni ilu Benin city pẹlu iya rẹ.
  • Lati kekere ni Majek Fashek ti ni ifẹ si orin kikọ; ifẹ to ni fun orin kiks naa lo mu ki o darapọ mọ ijọ aladura ti iya rẹ n lọ gẹgẹ bi akọrin.
  • Nibẹ lo si ti kọ bi a ṣe n fun fere ati gita ti o si tun n ko orin jọ pẹlu fun ẹgbẹ akọrin ijọ naa.
  • Orin to kọkọ pokiki Majek Fashek ni awo orin rẹ to fun ni akọle 'Prisoner of conscience' orin kan to si tan bi itanṣan oorun ninu awo naa ni orin "Send down the rain" eleyi to di orin ti tagba-tọmọde n kọ nigba naa; ọdun 1988 lo si gbe e jade.
  • Awọn gbajugbaja ileeṣẹ agborinjade bii Tabansi records, CBS Nigeria, Interscope records ni Majek Fashek ba ṣiṣẹ nigba ti orin rẹ n gberu.
  • Yatọ si iṣẹ orin raggae, Majek Fashek tun dan agbara wo lagbo sinima nigba to ko pa ninu fiimu agbelewo Mark of the beast to jade lọdun 2000 ati eto apanilẹrin kan ni ọdun 2016.

Majek Fashek: Àlàyé rèé lórí ikú tó pa gbajúgbajà olórin reggae Majek Fashek lẹ́ni ọdún 57

Erin wo, ajanaku sun bi oke. Ongbontarigi olorin raggae ni, Majẹkodunmi Fasheke ti ọpọ mọ si 'Majek Fashek' ti re iwalẹ asa nibi ere tii so'kan.

Aṣoju oloogbe Majek Fashek, Omenka Uzoma to ba BBC sọrọ ṣalaye pe ilumọọka olorin fọwọ rọri ku lọjọ kinni oṣu kẹfa niluu New York lorilẹede Amẹrika.

Ọgbẹni Uzoma ṣalaye pe ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Majek Fashek ki o to dagbere faye.

Ni ilu Benin city ni wọn bi Majek Fashek si. Ọmọ Ilesha ni baba rẹ ti iya rẹ si wa lati Edo.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ogbontagi olorin raggae to di ilumọọka lẹyin to kọ orin tii akọle rẹ ''Send down the rain'' ṣiṣẹ pẹlu awọn gbajugbaja olorin bii Jimmy Cliff, Tracy Chapman and Snoop Dogg nigba aye rẹ.

Ninu fidio ti aṣoju fi lede loju opo Instagram rẹ, Uzoma ni asiko ree lati ṣe ayẹyẹ awọn aṣeyọri Majek Fashek ati gbogbo nnkan to ṣe fun Naijiria ati ilẹ Afirika lapapọ.

Majek Fashek

Oríṣun àwòrán, others

Uzoma ni ko ba dara ki ijọba ranti ohun ipa ribiribi ti Majek Fashek pẹlu orin rẹ ki ijọba ṣi maa ṣe ayẹyẹ ni orukọ rẹ lọjọ keje oṣu kẹta to jẹ ọjọ ibi rẹ.

Itan igbe aye Majek Fashek

Ni ọdun 1988, ni okiki Majek Fashek kọkọ jade to bẹrẹ si ni lo Majek Fashek gẹgẹ bii orukọ apejẹ rẹ ti awo orin rẹ ti o pe akọle rẹ ni 'Prisoner of conscience' jade to si di wọọ ki ilu mọ nigba ti ọkan lara awọn

orin inu awo naa, Send down the rain di gbajugbaja to fun ni ami ẹyẹ ti ko din ni mẹfa lọdun 1989 nikan.

Majek Fashek fẹ Rita to si bi ọmọ mẹrin fun un ki wọn to kọ ara wọn silẹ .

Lawọn asiko kan ni igba aye rẹ, irinajo rẹ ṣe bi ẹni wọ diẹ nigba ti iroyin jade pe o n lo ogun oloro.

Amọ ṣa, yatọ si eyi, awọn aisan miran wa to n baa finra eyi to ran an lọ si ileewosan lọpọ igba.