Lateef Adedimeji and Adebimpe Oyebade: Ohun tí BBC mọ̀ nìyí nípa àjọṣepọ̀ òṣèré tíátà méjéèjì

Oríṣun àwòrán, Instagram/@adefits
Laipẹ yii ni iroyin jade pe, gbajugbaja oṣerebinrin, Adebimpe Oyebade ti loyun, ti ọpọ eeyan si n sọ pe akẹẹgbẹ rẹ, Lateef Adedimeji ni ọkọ rẹ to loyun fun.
Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori eto kan ta se fun l‘Ọjọru, Adebimpe sọ pe iṣu Ọlọrun ti ko ṣe e fi ọwọ bo ni ọrọ oyun nini, ati ọrọ ọkọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni awọn ololufẹ oun yoo mọ boya lootọ ni oun loyun tabi bẹẹkọ, nigba ti oṣu mẹsan ba pe.
Bo tilẹ jẹ pe o ṣe alaye yii, ọpọ to wo ifọrọwanilẹnuwo naa lo tẹnumọ pe oju rẹ jọ oju oloyun.
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Àìsàn Muyiwa kò lè la ẹ̀mí lọ - Agbẹnusọ Òṣèré, Muyiwa Ademola
- Ìrẹsì ọ̀fadà, ikọ́kọre, àti àwọn oúnjẹ míì tóo lè fí gbádùn ẹ̀mí rẹ lásìkò Kérésì
- Nínú kó o fi omi fọ ìdi tàbí lo tííṣù fi fá a, Èwo ló rọrùn?
- Ṣé òótọ́ ni àwọn ará Amẹ́ríkà máa ń hán an lọ́wọ́ kan tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?
- Báyìí ni Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ṣe wọ ṣọ́ọ̀ṣì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bá bàbá rẹ̀ ṣe ìdúpẹ́ ìwúyè
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Adedimeji ní àdìtú layé, Toyin Abraham sọ pé kò sẹ́ni tó lè táyé lọ́rùn
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn
- Ìrìnàjò Toyin Abraham, láti orí gbèsè jíjẹ, ó di onílé, onimọto àti aya lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ
Adebimpe ni ọrẹ timọtimọ ni oun ati Lateef, ti ko si si ọrọ ifẹ laarin wọn.
Nigba ti a beere lọwọ rẹ boya o le fẹ Adedimeji lọjọ iwaju, to ba dẹnu ifẹ kọ ọ, Adebimpe ni ọwọ Ọlọrun ni ohun gbogbo wa.
"Awa eeyan kan ma n gbiyanju ni, ti Ọlọrun ba sọ pe oun lọkọ mi, ma a sọ pe bẹẹni."

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimejilateef
Oṣu diẹ sẹyin ni awọn aworan kan to jọ pe oun ati Lateef ṣe igbeyawo jade sori ayelujara.
Awuyewuye tẹle nigba naa, ti ko si si eyikeyi laarin awọn mejeeji to sọ boya lootọ ni wọn ṣe igbeyawo tabi rara.
Arẹwa oṣere naa, to kẹkọọ gboye akọkọ ninu ede Gẹẹsi sọ pe, sababi ni bi oun se di osere tiata.
O ni iṣẹ arinrin oge (model) ni oun fi bẹrẹ. To si jẹ pe ere kan ti wọn ti nilo ọmọbinrin ti ko sanra, to si jẹ alawọ dudu lo pilẹ ere ṣiṣe fun oun.
"Awọ ara mi to dudu ati Ọlọrun lo sọ mi di nkan ti mo di lonii. Awọ ara kọ lo ṣe pataki julọ fun eeyan lati ṣe oriire laye, bi eeyan ṣe mọ iṣẹ rẹ daju si lo ṣe koko."

Oríṣun àwòrán, Instagram/mo_bimpe
Oṣere naa, to tun n ta aṣọ ati eroja aṣaraloge sọ pe, iṣẹ igbohunsafẹfẹ ni oun i ba tun ṣe, ka ni oun ko di oṣere.
O fikun pe oun ko fi igba kankan kabamọ pe oun ya sinu iṣẹ sinima ṣiṣe.

Oríṣun àwòrán, Instagram/@mo_bimpe
Lori iroyin to wọpọ pe awọn oṣerebinrin ma n ni ibalopọ pẹlu awọn alaṣẹ ati oludari ere, ki wọn o to o goke, Adebimpe sọ pe, iṣẹ ọwọ onikaluku lo n polongo rẹ, kii ṣe dandan ni lati ni ibalopọ pẹlu ẹnikẹni.



















