Americans sexists: Ṣé òótọ́ ni àwọn ará Amẹ́ríkà máa ń hán an lọ́wọ́ kan tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?

Ọkunrin ati obinrin alawọfunfun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdun 2020, ikọ BBC ni ilu Amẹrika ṣe agbeyẹwo ki lo n mu Amẹrika jẹ Amẹrika gangan atawọn ibeere to yi i ka.

Lori eto "What's Up America ti BBC, abala kẹta rẹ da lori ibaselopọ takọ-tabo.

Iwadii eto naa fihan pe afihan oju opo Netflix kan "Emily in Paris fihan pe ọrọ ibalopọ maa n wọ awọn ara Amẹrika lórí púpọ̀ ti wọ́n si maa n ṣe e daadaa.

"Ọmọge ni wa a si mọ ere títage ṣe daadaa sibẹ sibẹ, a o ran ẹnikẹni tori kii ṣe pe a ni eredi pataki kankan fun un".

"A tun maa n gba lọwọ kan bi o ba gbe ara rẹ wa ti eeyan kan ju ọrọ ibalopọ si wa".

Lara awọn to n gbe l'Amrika ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo ni lai fi ọkan we ọkan, "ootọ ni pe bi a ba gbe awọn ara Amẹrika yẹwo, awa ko fibẹẹ kọbiara si nkan ti aarẹ wa ba n ṣe nita igbeyawo rẹ o".

Eyi ni pe wọn o ka a bi ẹṣẹ si i lọrun.

Bẹẹni, orilẹede Amẹrika ni awọn patako atọna to n polowo awọn oju opo fun ibaraẹniṣepọ eyi to lee faaye gba iwa nọbi.

"Ẹ da aṣọbo ère alaṣẹwo yii tori mi o le bojuwo o"

Aworan ere

Atọkun eto ni oun fi ọrọ wa ẹnikan lẹnu wo to sọ fun oun pe ara oun ko balẹ mọ nitori pe o ri ere obinrin kan to wa ni ihoho ni aarin gbugbun ilu.

Obirin naa pariwo pe ki wọn da nkan bo ere to ṣi ọmu silẹ tori oun ko le ṣiju wo o.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Ṣe lootọ ni ara awọn Amẹrika kii balẹ to ba ti di ọrọ ibalopọ?

Ifarawe Condom

Arabinrin A: Lootọ nkan to n jẹ pe ara eeyan ko balẹ wa lootọ ni ti awọn Amẹrika, maa kan tẹsiwaju lati sọ pe "bẹẹni".

Ọgbẹni A: Fun igba akọkọ ti mo maa ba awn obi mi sọrọ nipa ibalopọ, o fẹrẹẹ to igba ti mo ti fẹẹ pari ile iwe girama, wọn si ra pali rọba idaabobo nla kan fun mi, wọn si gbagbe ọrọ naa sibẹ. O si jẹ asiko ti alainitiju.

Eso

"O dabii koo fi kọndọọmu sori ọgẹdẹ ni"

Yatọ si iha ti awọn obi kọ si i, imọ ẹkọ nipa ibalopọ lawọn ileewe ijọba jẹ ọ̀rọ̀ ti ijọba ibilẹ atawọn ọlọdani fọwọ si.

Fun ọpọlọpọ wọn, ọ̀na ti a gba ṣalaye to si ye wọ́n ni pe o dabii wiwọ rọba idaabobo fun ọgẹdẹ jijẹ ni.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

"Duro de ẹyin igbeyawo rẹ koo to ni ibalopọ"

Boya wọn foju nkan buruku wo o tabi bẹẹ kọ, igbadun lawọn eeyan maa n ka a si amọ awọn mii ko lọwọ si eyi.

Awọn igun ẹlẹsin Kristẹni ti ko fẹ iru awọn ayipada kan koro oju si gbogbo eyi. Igbagbọ wọn ko faaye gba ibalopọ nita igbeyawo ẹni to si ni ijiya.

Ẹya ẹlẹsin Kristẹni Puritan

Ẹwẹ, awọn ọdọ gbagbọ pe lati inu aṣa awọn olorin takasufee ni iwa fifẹran ibalopọ atawọn ohun to rọ mọ ọ ti wa.

"Mo ranti ifẹnukonu ara ọtọ ti Britney ati Madonna, ati Janet Jackson to n ṣi ọmu sita.

Ki wa ni koko ninu ọrọ to wa nilẹ yii, awọn ọdọ Amẹrika ni boya ninu aṣa orin afẹ, yoo le di alafo gbogbo ọrọ to n suyọ nipa ibalopọ ati ipa rẹ lara awọn eeyan Amẹrika.

"Bi a ṣe n wo awọn fiimu "High School Movies" tawọn oṣere inu rẹ si n ni ibalopọ, o jẹ ki awa naa ro pe a le maa ṣe e nileewe nigba ti a n ri i".

Wọn bo tilẹ jẹ pe ọpọ lodi si i, o n ṣafihan pe eeyan ti dantọ o si ti tojuu bọ ni.