Nollywood Yoruba: Allwell Ademola ní ara ọ̀nà àti máa dá aráàlú lárayá ló mú kí òun máa ṣe ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún

Allwell Ademola

Oríṣun àwòrán, Instagram/allwellademola

Ni ohun to faa ti oun fi maa n ṣe ọjọ ibi karundinlogoji lọdọọdun ko ju wi pe oun fẹ maa mu inu awọn eeyan dun.

O ni oun kan fi n da awọn eeyan lara ya ni ati pe oun kii ṣe ọmọ ọdun ọdun marundinlogoji rara.

O ni ko rọrun ni ibẹrẹ fun oun lati bẹrẹ ere tiata; gẹgẹ bi o ṣe sọ, ere ọlọsọọsẹ ni oun fi bẹrẹ ni ileeṣẹ mohunmaworan apapọ ilẹẹwa NTA nigba naa.

O fi kun un pe ọdun ti baba oun yọnu si ere tiata ti oun n ṣe lo jade laye.

Gbajugbaja oṣere tiata naa ṣalaye pe pe Allwell Ademọla ni orukọ oun nitootọ nitori pe idamu kekere kọ ni oun fun iya oun ninu oyun, gẹgẹ bi awọn eeyan sọ sọ.

Allwell Ademola atawọn oṣere meji miran

Oríṣun àwòrán, Instagram/allwellademola

O ni itan sọ fun oun pe bi oun ṣe da iya oun laamu ninu oyun lo mu ki iya oun pariwo All is Well, iyẹn ni pe "O dara".

O ni sisanra oun fun oun ni ọpọlọpọ ipenija nigba ti oun bẹrẹ iṣẹ tiata. O ni ọpọlọpọ ni wọn maa n san fun oun pe ipa mama loun lee ko ninu ere sinima nitori pe oun sanra. O wa rọ awọn obinrin lati maṣe jẹ ki awọn eeyan o fi sisanra wọn bu irẹwẹsi sinu ọkan wọn.

Bakan naa lo ṣalaye lori igbeyawo rẹ ti awsn eeyan kan n sọrọ le lori pe ọrẹ ọkọ ounloun fẹ.

Allwell Ademola ati Ọdunlade Adekọla

Oríṣun àwòrán, instagram/Allwell

Allwell Ademọla ṣalaye pe ọrẹ oun ni ọkunrin naa lati ipilẹ. Nigba ti oun ati ọkọ ti oun fẹ fẹ pade lo mu ko mọ ọrẹ oun naa ti awọn mejeeji si di ọrẹ.

Amọṣa o ni ọkọ oun ku nigba to ku diẹ ki wọn gbeyawo, bakan naa si ni afẹsọna ọrẹ ọkọ oun naa to tun jẹ ọrẹ oun fi silẹ lẹyin ọdun mẹjọ.

Eyi lo mu ko kọnu ifẹ si oun lẹyin igba diẹ pe " a ko kuku mọ nnkan ti Ọlọrun ọba fi ṣe." Bi o tilẹ jẹ pe o ni oun kọkọ faake kọri lori ọrọ naa, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ imọran oun gba fun un.

Amọṣa, o ni nitori awọn nnkan kan to ṣẹlẹ ajọṣepọ naa ko ju oṣu mẹjọ ti wọn fi tuka.

Lara awọn ibeere to tun tan imọlẹ si ni ajọṣepọ to wa laarin oun ati Sunkanmi. Allwell Ademọla ni lootọ ajọṣepọ wa laarin oun ati Sunkanmi ṣugbọn ajọṣepọ ẹgbọn si aburo, ẹni to gbe eeyan dide ti ko si ni fẹ ki teeyan o bajẹ ni.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'