Anthony Joshua: Mí ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá ni ìwọ́de #EndSars níṣe pẹ̀lú

Oríṣun àwòrán, Anthonyjoshua/instagram
Gbajugbaja abẹsẹ ku bi ojo Anthony Joshua ti tunu pé, lasiko ti iwọde #EndSars gbona janjan ninu oṣu kẹwaa ko ju ọrọ "Virus" ti wọn pè ni "Severe Acute respiratory Syndrome ti age ku rẹ n jẹ́ "SARS" ni oun ro pe o jẹ.
ninu ifọ̀rọ̀wánilẹnuwò ti Anthony Joshua ṣe pẹlu ilé iṣẹ iroyin Punch lo ti salaye pe gbogbo asiko ohun ni Naijiria oun ko ti ni nkan kan ṣe pẹlu ọrọ SARS bákan náà ni oun ko gbọ ẹka ọlọpaa SARS ri.
Joshua ti oun naa darapọ mọ awọn ilumọọka ọmọ Naijiria to n fẹhonuhan lori iwa ika àwọn ẹka ọlọpaa SARS lasiko to wa si Naijiria.
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kóo mọ̀ nípá ọmọ ọdún mẹ́wàá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀
- Bí kìí bá ṣe Buhari ni ààrẹ ni, ológun ì bá ti dìtẹ̀ gba ìjọba - Kukah
- Ṣé òótọ́ ni àwọn ará Amẹ́ríkà máa ń hán an lọ́wọ́ kan tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?
Abẹsẹkubiojo naa ni igba ti ẹbi oun kan pe akiyesi oun si ifẹhonuhan naa lo mu oun ka itan Naijiria ati ọrọ SARS daada.
"Mi o mọ nkankan nipa ọrọ SARS ni gbogbo asiko ti mo ti lo ni Naijiria, nitori naa nigba ti ifẹhonuhan naa bẹrẹ, mo ro pe ọrọ ajakalẹ aarun SARS ni, lọjọ kan lẹyin ti mo ṣe igbaradi tan , ara ile mi kan pe iyẹn ki awọn soja to lọ yinbọn ni Lekki, bi wakati marun si igba ti wọn yinbọ ni Lekki lo salaye nkan to n ṣẹlẹ gan fun mi, O ni awon eniyan Naijiria fẹran mi, wọn si fẹ mọ iha ti mo kọ si ọrọ naa.
"Mo ni mi o fi bẹẹ mọ nkan to n ṣẹlẹ nipa rẹ, ṣugbọn to ba jẹ pé ki n jẹ pe ki n kan sọrọ ni, maa sọ, mo rọ wọn pe ki wọn fun ijọba laye ki wọn wa ojuutu si ọrọ naa ati awọn ọdọ ati ijọba ki wọn gba fun ara wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
" Ko ju wakati diẹ sigba naa lọ ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki ṣẹlẹ. Mo wa wo pe , ọrọ naa kọja bi mo ṣe ro, igba yii ni mo wa lọ ka awọn nkan to ti sẹlẹ ati idi ti awọn eniyan fi jade lati fẹhonuhan."
Asiko ti mo n ṣe iwadii nipa ọrọ #ENDSARS yii ni mo tun fi la ara mi lọyẹ lori awọn nkan miran to n ṣẹlẹ ni Naijiria.












