Anthony Joshua: Lẹ́yìn ìjà rẹ̀ pẹ̀lú Luiz, Anthony Joshua bẹ Ọba ìlú rẹ̀, Àkárìgbò wò

Anthony Joshua pẹlu Akarigbo ilẹ Rẹmọ

Oríṣun àwòrán, CockFM Radio

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọmọ ale ni fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ.

Gbajugbaja akanṣẹ lagbaye, Anthony Joshua bẹ ile wo lọjọru. Taara ta ilu rẹ ni Ṣagamu lo mori le, nibẹ lo si ti ṣe baba kẹẹ pẹ sawọn ọbalaye ati oriade gbogbo to wa nilu naa.

Eyi ni igba akọkọ ti Anthony Joshua yoo maa yọju si orilẹede Naijiria lẹyin to gba igbanu ẹyẹ agbaye rẹ, WBA, WBO, IBF ati IBO pada lọwọ Andy Ruiz.

Ọmọ orilẹede Mexico naa si lo gba ami ẹyẹ ọhun dani fun bi oṣu diẹ, nibi ija wọn to waye ni gbagede Diriyah Arena lorilẹede Saudi Arabia.

Anthony Joshua pẹlu Akarigbo ilẹ Rẹmọ

Oríṣun àwòrán, CockFM Radio

Ọkẹ aimoye awọn ololufẹ rẹ ni wọn rọgba yii ka lasiko to fi lọ ki Alafin Ẹlẹpẹ ati Akarigbo ti ilẹ Rẹmọ ni aafin wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lẹyin to foribalẹ fawọn ọba alade naa tan, ni Anthony Joshua wa ya fọto pẹlu awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa foju gaanni rẹ.

Anthony Joshua pẹlu Akarigbo ilẹ Rẹmọ

Oríṣun àwòrán, CockFM Radio

Ariwo 'ibi ni ile rẹ kii ṣe ilẹ Gẹẹsi' ni ọpọlọpọ awọn eeyan to tu sita wa wo agba ọjẹ akanṣẹ naa n pa, bi gbogbo wọn ṣe n da giiri lati baa ya fọto, ti wọn si tun wọ tọọ lẹyin lati aafin Elepe lọ si aafin Kabiyesi Akarigbo ti ilu Rẹmọ.