Oluwo tí sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye láàrin rẹ̀ àti Agbowu tìlùu Ogbaagbaa
Oluwo ilu Iwo Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ba BBC Yoruba nipa ohun to ṣẹlẹ laarin rẹ ati Agbowu ilu Ogbaagba.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to waye pẹlu Oluwo, Oba Alade naa ṣalaye pe ko si eleyi ti oun ko bọwọ fun laarin awọn ọba to wa labẹ ohun ṣugbọn iwa arifin awọn kan ti fẹ pọju.
Oluwo ni kii ṣe pe o wu ohun lati ma tahun si awọn ọba wọnyii ṣugbọn nigba ti wọn ba ti n tẹ ẹtọ awọn ara ilu mọlẹ nipa tita ilẹ lọna ti ko tọ, ohun ko ni le dakẹ.
- Mò ń ṣe Gbosa! fún BBC Yorùbá fún ayẹyẹ ọdún méjí - Mike Ifabunmi láti Brazil
- Coronavirus: Ó dá mi lójú pé ìwá ìbàjẹ́ ló fa àrùn yìí - Ọ̀gá àgbá EFCC
- Ibà Lassa wọ ìpínlẹ̀ Èkó!
- Gbogbo ẹ̀yin ọ̀ba abẹ́ mi, tí ẹ̀ ń ta ilẹ̀ ìlú, ẹ kò ní fara re lọ - Oluwo
- Ìgbà mẹ́rin tí ọ̀rọ̀ Oluwo dá awuyewuye sílẹ̀
- Ìjọba Ọṣun ti dásí ìjà láàrin Oluwo àti Agbowu
- Anthony Joshua gba nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN, àwọn ọmọ Nàìjíríà kan kérora lórí ètò náà
''Ti awọn eeyan ba wa fẹjọ wọn sun mi, mo maa n sọ fun wọn pe ade mi lo wa lori wọn, ẹ ma ba wọn ja. Mo fi aye gba wọn gaan ṣugbọn laarin bii ọdun mẹrin bayii, arifin wọn ti pọju''
Oba Abdulrasheed nigba ti a beere nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn da apa si ọba Agbowu lara sọ pe ''Iro balawu ni wọn pa mọ mi''
Kii ṣe oni ni wọn ṣẹṣẹ n na ọpa si mi loju. Bẹẹ, eewọ ni ki wọn na ọpa si ọba. Nigba ti wọn fẹ ki ọpa bọ mi loju, ṣe ki n maa wo wọn niran ni?'.
Oluwo tẹsiwaju pe pupọ ninu awọn ọba to n doju ija kọ oun lo ti ta ilẹ awọn baba wọn tan ti wọn wa n wa awọn ilẹ ara ilu ti wọn a ta kun.
O pari ọrọ rẹ pe oun jẹ Oba to ni ifẹ ara ilu lọkan nitorinaa, oun ko ni gba ki ẹni kankan wa maa tẹ ẹtọ ara ilu mọlẹ.
- Ṣé Liverpool ṣì leè tẹ̀síwájú ní ìdíje Champions league?
- Oyè Ibadan kò sí fún títà - Otun Olubadan, Lekan Balogun
- Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta l'ẹ̀wọ̀n akọrin ẹ̀mi gbẹ̀mí ará rẹ̀ látìmọ́lé
- Yàtọ̀ sí eku gọ́tà tàbí èku inú ilé, kò sí eku téèyàn ò lè jẹ - Òǹtajà Eléwé ọmọ
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti bẹ̀rẹ̀ òfin tí yóò máa mú àwọn olùkọ́ fásitì tó ń bèrè fún ìbálòpọ̀













