Champions league: Lẹ́yìn tó fìdírẹmi ní Spain, Ṣé Liverpool ṣì leè yí ojú ayò padà ní Anfield?

Ifẹsẹwọnsẹ Athletico Madrid ati Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ni ipele komẹsẹ o yọ to kan ni idije Champions league ọdun yii ti bẹrẹ.

Lara eyi to waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ni itaporogan laarin ẹgbẹ agbabọọlu Athletico Madrid ati Liverpool.

Goolu ti Saul Niguez, agbabọọẹu Ath;etico Madrid gba wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrin ni o la awọn ikọ mejeeji laarin ni papa iṣire Wanda Metropolitano

Bi o tilẹ jẹ wi pe Athletico Madrid bori ifẹsẹwọnsẹ naa, sibẹ ọrọ ọhun ko tii tan nitori pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii yoo tun fojurinju ni ọsẹ mẹta si asiko yii ni papa iṣire Anfield to jẹ ibuba Liverpool.

Ibeere to wa n gba ẹnu ọpọ bayii ni pe, ṣe yoo ṣeeṣe fun Liverpool lati yi oju ayo pada?

Lootọ, oniruuru ọrọ ni awọn ololufẹ Liverpool ti nsọ lati fi igbagbọ wọn han pe ikọ naa yoo yii pada yoo si bori Athletico lati tẹsiwaju.

Bi a ba ni ka wo o daradara, ikọ agbabọọlu Liverpool kii ṣe ajeji si irufẹ igbesẹ bẹẹ.

Eyi si ni awọn igba ti Liverpool ti yi oju ayo pada fun awọn alatako wọn lẹyin ti wọn ti kọkọ n m'oke.

Ifẹsẹwọnsẹ Athletico Madrid ati Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Liverpool 3 AC Milan 3 (Liverpool won 3-2 on penalties, Champions League final, Istanbul, May 2005)

Ni ọdun 2005, Liverpool na Milan pẹlu ami ayo gbe e silẹ ko o gba a si goli, pẹnariti lati gba ife ẹyẹ Champions league ni ọdun naa lọhun.

Eyi waye lẹyin ti Milan ti kọkọ gba goolu mẹta wọ ile Liverpool ki Liverpool to wa ta kiji da mẹtẹẹta pada.

Liverpool 4 Barcelona 0 (Liverpool won 4-3 aggregate, Champions League semi-final, Anfield 2019)

Bi ti ọdun 2005 ba jina, eyi to waye ni ọdun to kọja, 2019 tun le nilẹ.

Barcelona ti na Liverpool pẹlu ami ayo mẹta si odo ni ifẹssẹwọnsẹ akọkọ to waye ni papa iṣire Camp Nou ni Spain ni ipele to kangun si aṣekagba idije Champions league kan naa. Nigba ti Barcelona yoo fi yọju si papa iṣire Anfield fun apa keji goolu mẹrin si odo ni wọn ba lọ eleyi to gbe Liverpool wọ ipele aṣekagba idije naa eyi ti wọn wa bori lẹyin-o-rẹyin.