Ilé-ẹjọ̀ kòtẹ́milọ́rùn kọ onídùró El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Nasir El-Rufai/Facebook
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Kaduna ti sọ pe ohun ko le fontẹ lu ẹbẹ gbigba beeli gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Nasir El-Rufai.
Gẹgẹ bi ojulowo iwe ẹri idajọ ti igbimọ ẹlẹni mẹta gbe kalẹ l'Ọjọbọ to kọja, ile-ẹjọ naa sọ pe El-Rufai ko ni awijara kankan lori idi ti ohun yoo ṣe gbe igbesẹ lati tako idajọ ile-ẹjọ giga to ti kọkọ way.
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe ile-ẹjọ giga ni anfaani lati gbe idajọ kalẹ, ti ohun naa si ni anfaani lati gbe aṣẹ tiẹ naa kalẹ, ṣugbọn ninu ẹjọ ti El-Rufai gbe wa, ko si ẹri kankan ti wọn le fi tako idajọ to ti kọkọ waye.
Olori igbimọ onidajọ naa. Onidajọ Onyekachi Aja Otisi, sọ pe idajọ to da ile-ẹjọ lọwọ kọ lati gba beeli El-Rufai lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 fẹsẹ mulẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ajọ ICPC ni wọn fẹsun kan El-Rufai to ṣe gomina ipinlẹ Kaduna laaarin ọdun 2015 si 2023 lori awọn iwa ibajẹ to jẹyọ lasiko iṣakoso rẹ.
Latigba ti ajọ ICPC ti fẹsun kan El-Rufai ni gomina tẹlẹ naa ti sọ pe oun ko lẹbọ lẹru, to si ti bẹrẹ sii tako bi wọn ṣe fi si ahamọ.
Ṣugbọn ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kaduna ti da ẹjọ ti El-Rufai pe nu, lori igbiyanju lati gba beeli rẹ, ṣugbọn ti ile-ẹjọ sọ pe ki igbẹjọ bẹrẹ lai fi akoko ṣofo.
Nigba ti igbesẹ ile-ẹjọ naa ko tẹ El-Rufai lọrun, lo jẹ ko gba ile-ẹjọ kotẹmilọrun lọ.
Kí ni ilé-ẹjọ́ sọ?
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun naa sọ pe aṣẹ ti ile-ẹjọ giga gbe kalẹ tẹle ilana ati aṣẹ to ni, nipa kikọ lati gba beeli gomina tẹlẹ ọhun, ati pe awọn ẹri aridaju lo fa igbesẹ ile-ẹjọ.
"Ko si ẹri kankan to tako bi ile-ẹjọ ṣe kọ lati gba beeli, A fidi idajọ ile-ẹjọ giga to gbe kalẹ lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 mulẹ," Otisi sọ bẹẹ.
Bakan naa ni ile-ẹjọ kotẹmilọrun naa tun sọ pe awọn ọrọ ti El-Rufai lori awọn ẹrọ amohunmaworan tapa si ofin ati eto idajọ.
Awọn agbejọrọ sọ fun ile-ẹjọ pe El-Rufai sọ awọn ọrọ ti ko tọ nita gbangba nipa fifi idi ilana eto oṣelu rẹ mulẹ lodi si awọn to n fẹsun ọdaran kan an.
Bakan naa ni wọn lo tun sọ lori amohunmaworan Arise lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 wi pe oun n tọpinpin ero ibanisọrọ oludamọran pataki sọrọ eto aabo ni Naijiria.
Ninu idajọ naa, El-Rufai loun gba wi pe oun ṣe oniruuru ifọrọwerọ leyi to fidi rẹ mulẹ pe oniruuru ẹsun to nii ṣe pẹlu ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ṣugbọn ṣa, ile-ẹjọ kotẹmilọrun naa fidi rẹ mulẹ pe oun ko le maa wa ẹri kaakiri, bi ko ṣe pe o digba ti ile-ẹjọ ba da El-Rufai, ki wọn too mọ pe lotitọ ni ko jẹbi.





























