Mike Ifabunmi, àwọn òṣèré Yorùbá kí BBC Yorùbá kú ayẹyẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Àkọlé fídíò, Mike Ifabunmi kí BBC Yorùbá kú ayẹyẹ ọdún méjì
Ọpọlọpọ awọn eeyan jankan jankan lo ti n fi ikini ku ayẹyẹ ọdun meji ranṣẹ si ileeṣẹ BBC Yoruba tẹ o si maa ri gbogbo rẹ loju opo wa bi oni ba ṣe n lọ.
Ka to wi ka to fọ ka to ṣẹju pẹrẹ, ọdun meji ti pe. Ọmọ kekere ana ti wa wa dagba.
Akanṣe eto pataki ti a ṣe fun ayẹyẹ ọdun meji BBC Yoruba loju opo Facebook wa niyii nisalẹ.
Kẹrẹkẹrẹ nigba ti igbohunsafẹfẹ ileeṣẹ BBC Yoruba ati kiko iroyin sori ẹrọ ayelujara bẹrẹ lọjọ naa lọhun, wẹrẹ wẹrẹ la n wọle si ọkan awọn eeyan.
Eyi ko tii dawọ duro bayii o koda, iroyin wẹrẹwẹrẹ ti di eyi ti wọn n rọ lu witiwiti lati ka bayii to bẹẹ ti okiki BBC Yoruba ti kan tayọ orilẹede Naijiria to si ti de gbgobo agbaye.
Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun
BBC Yoruba taa ṣe ifilọlẹ rẹ ni dede ọjọ oni lọdun meji sẹyin, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji ọdun 2018 ni ifilọlẹ pataki nla naa waye ni ipinlẹ Eko, Naijiria.
Àkọlé fídíò, Ọ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé
Àkọlé fídíò, Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba
Àkọlé fídíò, 2019 Elections: Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjíròrò Eko yóò bẹ̀rẹ̀
Àkọlé fídíò, Iriwisi àwọn ará ìlú ṣe ọtọtọ lórí èsì ìdìbò Osun
Ọrọ to kan araalu
Lara awọn iroyin manigbagbẹ ti a ti sẹ ni yii nipa eto idibo gbogboogbo to waye lorilẹede Naijiria ni ọdun 2019, eto oṣelu ni Naijiria, asa, iroyin kayeefi to fi mọ iroyin awọn oṣere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria.